Money rituals: Babaláwo kan ní kò sí ètùtù òògùn owó nínú Ifa, àwúre ló wà

Babalawo Olukunle Idowu ti ṣalaye lẹkunrẹrẹ fun BBC Yoruba pe ko si ohun to jọ oogun owo ninu Ifa.
Eyi tako igbagbọ ọpọ eeyan pe awọn babalawo lo n ṣe oogun ọrọ fawọn ọdọmọde ti wọn n wa owo ojiji lasiko yii.
Lẹnu ọjọ mẹta yii, iroyin fifi awọn eeyan ṣe oogun ti wa wọ pọ lawujọ.
- Àbúrò mi dágbéré pé òun fẹ́ dé ibì kan, ìròyìn ikú rẹ̀ ni mo gbọ́
- Ọwọ ọlọ́pàá tẹ ọmọ ọdún 15 mẹ́ta lásìkò tí wọ́n fẹ́ fi èèyàn ṣe òògùn owó
- Kìnìún méjì ṣekùpa olùṣọ́gbà ẹranko, wọ́n sì sálọ
- Ẹ foríjìnmí, ẹlẹ́ran ara ni mí- Gbajúgbajà adẹ́rìnpòṣónú, Bae_U
- Alukoro JAMB wọ́ Ahmed Isah Brekete lọ síwájú Adájọ, ₦6bn lo n bèèrè lówó gbà má bínú
O si buru debi wi pe awọn ọdọ langba ti ko tii pe ogun ọdun ni wọn n saaba ba nidi awọn to n ṣe oogun owo.
Alaye babalawo ree lori oogun owo:
Babaawo Idowu ni ọrọ naa dabi owe tawọn Yoruba maa n pa wi pe amukun, ẹru rẹ wọ, o ni oke lẹ n wo ẹ o wo isalẹ.
''Ikanju lo n mu ki awọn ọmọ kekeke maa ṣoogun owo, gbogbo nkan lo ti di ikanju lode oni.
Ninu ikanju ni a n bimọ si, ninu ikanju ni a n bi ọmọ si laye ode oni.
Ikanju ni a fi n loyun ọmọ, ikanju ni a fi n wa sile aye, ikanju yii naa ni wọn fi n fi aye silẹ.
Nitori awọn eeyan o dagba di ogbo mọ, ẹni to ba fi ikanju waye yoo kanju lọ.
Amọ, ko si ohun to n jẹ oogun owo ninu Ifa o nitori ki a gbo, ki a tọ ni Orunmila dimu.
Orunmila n ṣe tiwa lode ọrun, ẹni to ba ti ṣe ti Orunmila lode aye, ki ni kanju ku tori Orunmila ko kanju ri.
Ikanju lo bi gbogbo ohun to n ṣẹlẹ yii lati inu ile bọ si ode to fi de ọdọ ijọba.
O yẹ ki a ba awọn alaṣẹ sọrọ lori gbogbo awọn to n kowo sinu kanga nla, awọn mii n kan posi fun owo, gbogbo ẹ lawọn ọmọ yii n gbọ.
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ekiti sàfihàn àwọn òníjàgídíjàgán méjìdínlọ́gọ́rùn ún lónìí ní Ado Ekiti
- Àwọn Olóyè ti wọ́gilé ẹjọ́ tí wọ́n pé tẹ́lẹ̀ lórí bí a ṣe ń jẹ ọba Olúbàdàn
- Ọwọ́ aráàlú ní ètò ìdájọ́ òdodo Nàìjíríà wà, kìí ṣé ọdọ àwọn onímọ̀ ètò ìdájọ́- Osinbajo
- Àjọ SERAP gbé Ààrẹ Buhari lọ sílé ẹjọ́ nítorì kò wádìí N3B tó pòórá níléèṣẹ̀ ètò ẹ̀náwó
Awọn ọmọ yii naa fẹ la loojọ, awure ni n bẹ lọdọ babalawo ko si oogun owo.
Awure ti n sọ yii gan an, ti ọmọde ba wa labẹ obi rẹ, ko ni le ṣe tori ẹru.
Ti oogun owo ba wa ni, n ko ni maa gbe ile atijọ to ma wa mọ, n ko ba ti ko lọ ile ara mi.
Inu ile atijọ ni mo n gbe, ti oogun owo ba wa ni, n ko ba ti wo ile naa palẹ ki n fi kọ ile alaja mẹta.
Ẹmi gigun ati aṣiri bibo lawọn baba wa maa n tọrọ, awa o le iyẹn mọ.
Owo gbigbona ni, ẹni to ba wa, oun naa maa ku iku gbigbona ni.
Kinni onimọ nipa ihuwa si ọmọde sọ?
Onimọ nipa ihuwasi ẹda, Akinola Akinropo ni awọn ọmọde to n ṣe oogun owo yii nikan kọ jẹbi ọrọ yii.
O ni ''nkan ti Obi ba n ṣe, awọn ọmọ naa maa gbagbọ pe awọn naa le ṣe iru rẹ.
Fun apẹrẹ, fifi ẹgba lu ọmọ to ba ṣẹ kii ṣe ibawii, ibinu lasan ni iru awọn Obi bẹẹ kan n fihan.
Gbogbo ọmọ lo gbe ogo wọn waye, ṣugbọn o ku sọwọ Obi lati tọ ọmọ sọna.

Oríṣun àwòrán, @Akinola Akinropo facebook
Kii ṣe gbogbo obi kọ lo mọ pe kii ṣe gbogbo ile ẹkọ ni ọmọ le lọ, kii ṣe gbogbo adugbo ni ọmọ ti le dagba.
Aṣiṣe ti ọpọ awọn obi maa n ṣe ni pe wọn kii tọ ọmọ fun ọjọ iwaju.
Iru awọn ọmọ to n dunkoko mọ awọn ọmọde ẹgbẹ wọn nile ẹkọ ti awọn alaṣẹ ile ẹkọ lo n pada n fi awọn eeyan ṣe oogun owo kaakiri.
Ko yẹ ki ile ẹkọ maa le awọn akẹkọọ to ya apanle ọmọ kuro nile ẹkọ.
- Gbogbo ẹ̀yin ọ̀ba abẹ́ mi, tí ẹ̀ ń ta ilẹ̀ ìlú, ẹ kò ní fara re lọ - Oluwo
- Ẹ jẹ́ ká dá ìbọn kọjá, tó bá jẹ́ pé Oluwo kò fìyà jẹ́ mí - Agbowu
- Ìjọba Ọṣun ti dásí ìjà láàrin Oluwo àti Agbowu
- Àwọn ọlọ́pàá méjì ṣe kòńgẹ́ ọlọ́jọ́ wọn níbi tí wọ́n ti ń ṣe àyẹ̀wò ọkọ̀
- Èèwọ̀! Ọmọ Yahoo fẹ́ pa ìyá rẹ̀ ṣ'owó l'Eko
- Àjọ ìṣọ̀kan ilẹ̀ Àdúláwọ̀ fòfin de Burkina Faso lórí ìdìtẹ̀gbàjọba
- U.S. yóò máa fún àwọn ọmo Nàìjíríà kan ní físà ìwé ìrìnnà láì ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò
Nitori ti wọn ba le wọn kuro, igboro naa ni wọn yoo pada si ti wọn yoo si da idakuda.
Ijọba gan an ni ẹbi tiẹ nipa aiṣeto ẹkọ to mọyan lori fun awọn akẹkọọ.





















