JAMB PRO vs Ahmed Isah: Àwọn ọ̀rọ̀ kabiti tí wọn ní Ahmed Isah Brekete sọ sí alukoro JAMB rèé tó fí pè é lẹjọ́ bílíọ̀nù mẹ́fà Náírà

Oríṣun àwòrán, Others
Alukoro ajo to n mojuto idanwo igbaniwole ile eko giga fun awon akekoo ni Naijiria ti gbe akoroyin Ahmad Isah lo sile ejo.
Alukoro ajọ to n seto idanwo igbaniwọle si fasiti ni Naijiria, Joint Admissions and Matriculation Board, Onimọ Fabian Benjamin ti wọ gbajugbaja sọrọsọrọ nii Ahmed Isa lọ sile ẹjọ.
O ni Ahmed Isah gbe iroyin ibanilorukọ jẹ jade nipa oun tori naa afi ko san owo gba ma binu biliọnu mẹfa naira.
- 'A kò le gba ẹlẹ́wọ̀n kankan wọlé mọ́, kò sí òunjẹ tá a fẹ́ fún wọn'
- Ọkọ mi tẹ́lẹ̀ àti Adekaz kò fi ìgbà kankan jẹ́ ọ̀rẹ́, kìí sẹ ọ̀rẹ́ ọkọ mi ni mo fẹ́ - Mercy Aigbe
- Alukoro JAMB wọ́ Ahmed Isah Brekete lọ síwájú Adájọ, ₦6bn lo n bèèrè lówó gbà má bínú
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ekiti sàfihàn àwọn òníjàgídíjàgán méjìdínlọ́gọ́rùn ún lónìí ní Ado Ekiti
- Àwọn Olóyè ti wọ́gilé ẹjọ́ tí wọ́n pé tẹ́lẹ̀ lórí bí a ṣe ń jẹ ọba Olúbàdàn
Ahmed Isah ati ileesẹ iroyin Human Rights Radio to jẹ oludasilẹ rẹ ni Benjamin papọ pe lẹjọ ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aiku.
Ogbeni Benjamin Fabian so pe iwa ibaniloruko je ni agbohunsafefe Ahmad Isah hu si oun lasiko to n seto kan lori afefe re iyen Human Right Radio nilu Abuja.
Ninu ọrọ rẹ Benjamin sọ pe oun pe ẹjọ naa ninu iwe ipẹjọ CV/3211/2021 ti agbẹjọro rẹ Chris Alashi gbe lọ siwaju adajọ A.O Ebong tile ẹjọ giga to fi Gwagwalada se ibujoko nilu Abuja.
- Osun la fẹ́ kí ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke ti wáyé, kìí ṣe Abuja - Mọ̀lẹ́bí yarí
- Deji Akure tó lu aya rẹ̀ lójú títì, tí wọn rọ̀ lóyé, ti jáde láyé
- Èèyàn méjì dèrò ọ̀run nínú ìkọlù ọlọ́pàá àtàwọn afurasí akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn Kwara Poly
- Òkú kú ní ẹ̀ẹ̀kejì nígbà tí òkú 400 jóná ráúráú ní mọ́ṣúárì, ẹbí bú sẹ́kún lẹ́ẹ̀kejì
- Àwọn ọmọbìnrin oníwọ́kuwọ́ ló mú kí ń yẹ̀bá nídìí iṣẹ́ tíátà
- Bí ayẹyẹ ìsìnkú Alao Akala yóò ṣe lọ rèé
- Àwùjọ àgbáyé, ẹ ṣèrànwọ́ fún Burkina Faso kó le borí ìṣòro - Olórí ìjọba ológun
Kini Benjamin n beere fun lori esun naa?
'Ọmọwe Benjamin n beere fun owo gba mabinu biliọnu mẹfa Naira lori ọrọ ibanilorukọjẹ ti ileesẹ Human Rights gbe safẹfẹ eleyi ti Ahmed Isa si jẹ atọkun rẹ''.
Bawo ni ọrọ naa ti se sẹlẹ gan an?
Ahmed Isah jẹ sọrọsọrọ ilumọọka ti a si maa fi eto rẹ Berekekete Family se agbeyẹwo awọn isẹlẹ lawujo lọna ati ba araalu ja fun ẹtọ wọn.
Ninu ọrọ ti Ọmọwe Benjamin fi sita o ni lọjọ Kẹrindinlogun, osu Kẹrin, ọdun 2021 Ahmed Isa pe oun lori ago laarin ago meje abọ si mẹwaa aarọ lori eto rẹ.
''Lasiko to pe mi sori eyo yi, nise lo sọ awọn ọrọ to tabuku to si tun ba mi lorukọ jẹ gẹgẹ bi alukoro ajọ JAMB ati ọmọwe''
''Ni pato o sọ pe mo fọna ẹburu gba iwe oye mi gẹgẹ bi Ọmọwe ati pealagana ni mi, mi o kaju osunwọn, bẹẹ si ni mi o jẹ eeyan ti ọwọ rẹ mọ''
Ko tan sibẹ ninu ẹsun ti Benjamin fi kan Ahmed Isah
Benjamin ni pe Ahmad Isah so pe: iwa igberaga toun n hu ati iwa buruku ọwọ oun, ajogunba ni wọn jẹ.
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ekiti sàfihàn àwọn òníjàgídíjàgán méjìdínlọ́gọ́rùn ún lónìí ní Ado Ekiti
- Àwọn Olóyè ti wọ́gilé ẹjọ́ tí wọ́n pé tẹ́lẹ̀ lórí bí a ṣe ń jẹ ọba Olúbàdàn
- Ọwọ́ aráàlú ní ètò ìdájọ́ òdodo Nàìjíríà wà, kìí ṣé ọdọ àwọn onímọ̀ ètò ìdájọ́- Osinbajo
- 'A kò le gba ẹlẹ́wọ̀n kankan wọlé mọ́, kò sí òunjẹ tá a fẹ́ fún wọn'
- Wo ǹkan mẹ́jọ tí o kò ma nípa Abiidemi Rufai, amúgbálẹ́gbẹ̀ Gómìnà Dapo Abiodun tí wọ́n mú ní America
- Àkúntúnkú, ìgbà mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ rè é tí Shekau kú, tí wọ́n ní kò kú mọ
- Ahmed Isah, Ordinary President, ṣàlàyé ìdí tó fí dá ìgbájú-ìgbámú bó obìnrin lórí afẹfẹ
- Ọwọ́ tẹ àwọn afurasí afipábánilòpọ̀ 206 l'Eko
Benjamin tẹsiwaju pe Ahmed Isa ni ko si ọna abayọ si iwa igberaga rẹ ati pe awọn obi rẹ naa ni iru iwa yi lọwọ.
Ta ni Ahmed Isa sọrọ sọrọ Brekete Family?
Orukọ tawọn eeyan mọ si tunmọ si aarẹ lasan lede Yoruba.
Ordinary President lorukọ tawọn eeyan maa n pe Ahmed Isa to si ti n se isẹ sọrọ́sọrọ lori eto Brekete Family ti pẹ.
Lori eto rẹ, awọn mẹ́kunu ati awọn to ba ro pe wọn dun awọn lẹtọ wọn lo maa n gbe ọrọ wọn sita.
Lọpọ igba a maa safihan kudiẹkudiẹ awọn alasẹ tabi osisẹ ijọba ti eleyi yi si mu ki ọpọ eeyan nifẹ si.

















