Police-cultists clash: Èèyàn méjì dèrò ọ̀run nínú ìkọlù ọlọ́pàá àtàwọn afurasí akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn Kwara Poly

Oríṣun àwòrán, Kwara State Polytechnic
Eeyan meji lo jẹ Ọlọrun nipe nigba tawọn akẹkọọ ile ẹkọ gbogbonṣe Kwara Poly kọlu awọn ọlọpaa niluu Ilorin lọjọ Abamẹta.
Iroyin sọ pe aṣita ibọn lo pa akẹkọọ kan ati ẹnikan to wa ladugbo ti iṣẹlẹ ọhun ti waye ni Elekoyangan.
A gbọ wi pe awọn sọja ni wọn pada lọ pẹtu si aawọ naa ki alaafia to jọba nibẹ.
- Ọlọ́pàá Ogun mú ọ̀dọ́ mẹ́ta tí kò tó ọdún 20 níbi tí wọ́n ti n fi ọ̀rẹ́bìnrin ọ̀rẹ́ wọn ṣe òògùn owó
- Ọwọ ọlọ́pàá tẹ ọmọ ọdún 15 mẹ́ta lásìkò tí wọ́n fẹ́ fi èèyàn ṣe òògùn owó
- Musulumi àti Kristẹni lo ṣe àdúrà níbi ètò ìsìnkú Timothy Adegoke lónìí
- Òkú kú ní ẹ̀ẹ̀kejì nígbà tí òkú 400 jóná ráúráú ní mọ́ṣúárì, ẹbí bú sẹ́kún lẹ́ẹ̀kejì
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ pásítọ̀ tó ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ìyá àti ọmọ méjì
- Dókítà àti Nọ́ọ̀sì di atọrọjẹ torí àjẹsílẹ̀ owọ oṣù mẹ́jọ
Ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye ohun to ṣẹlẹ
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ṣalaye ninu atẹjade to fi sita pe rogbodiyan bẹ silẹ lẹyin tawọn ẹlẹgbẹ okunkun kọju ija sawọn ọlọpaa to wa lati Abuja fẹ mu awọn afurasi akẹkọọ ẹlẹgbẹ okunkun kan lagbegbe Elekoyangan.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, CSP Ajayi Okesanmi ni ọpọ ninu awọn ẹlẹgbẹ okunkun naa lo sapamọ lagbegbe Lajolo to wa lẹgbẹ ile ẹkọ naa.
Agbegbe yii ni a gbọ pe awọn ẹlẹgbẹ okunkun ti ṣe ikọlu si akẹkọọ kan ti orukọ rẹ n jẹ Idris Aderemi.

Oríṣun àwòrán, Kwara State Police
Okesanmi ni ''eyi gan an lo jẹ ki awọn ọlọpaa STS yabo agbegbe naa lai mọ pe awọn ẹlẹgbẹ okunkun naa gẹgun de wọn.
Ṣadeedee ni wọn bẹrẹ si ni yinbọn mọ bọọsi awọn ọlọpaa nibi ti ọlọpaa kan, Adebayo Abdulahi ti ṣeṣe lori.''
Ọwọ awọn ọlọpaa pada tẹ awọn ẹlẹgbẹ okunkun meji, Ahmed and ati Musibau 'm' ti inagijẹ rẹ jẹ Shaban.
Wọn ka ibọn pẹlu oriṣiiriṣii ọta ibọn ati iwe lilo ibọn mọ wọn lọwọ.
Awọn akẹkọọ yari
Lẹyin iṣẹlẹ yii ni awọn akẹkọọ pejọ biba ti wọn si di ọna iwaju ile ẹkọ naa.
Awọn akẹkọọ bẹrẹ si ni ṣe ifẹhonuhan, wọn sun taya mọto loju titi eleyii to da sun kẹrẹ fakẹrẹ ọkọ silẹ.
Awọn ọlọpaa naa lo pada ri i pe alaafia jọba nibẹ.
Ẹwẹ, awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa ti sun idanwo to yẹ ko bẹrẹ lọjọ Abamẹta siwaju nitori iṣẹlẹ to ṣẹlẹ.
- Ìtàn ayé ọ̀gágun Paul-Henri Sandaogo Damiba tó léwájú ológun gbàjọba Burkina Faso?
- Ìjọba Eko gbẹ́sẹ̀lé NURTW ní Lagos Island, ọlọ́pàá mú àwọn méjì míì lórí ìjà ìgboro Idumota
- Lanre Gentry, ọkọ Mercy Aigbe tẹ́lẹ̀ sọ̀rọ̀ sókè lórí ìgbéyàwó aya rẹ̀ àná
- Àlàyé rèé lórí ìròyìn tó ní Buhari ti kú, Jubril Sudan ló ń darí Nàíjíríà
- Mo fẹ́ fojú rí Sunday Igboho ní àhámọ́ tó wà, kò sì ní bọ́ níbẹ̀ - Seriki Fulani
- Gbajúmọ̀ akọrin ẹ̀mí ṣe panságà, ó kọ̀wé ẹ̀bẹ̀ sí aya rẹ̀
















