Seriki Fulani: Àtijẹ, àtimu nira, mó fẹ́ owó gbà má bínú àti ìdájọ́ òdodo

Seriki Fulani ipinlẹ Oyo, Alhaji Saliu Abdulkadir ti sọ pe oun fẹ lati foju ri Oloye Sunday Igboho yala ninu ẹwọn to wa lorilẹede Benin Republic tabi ni Naijiria.
Abdulkadir kede ọ̀rọ̀ yii lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori awọn ipenija to n koju rẹ lẹyin to pe ọdun kan ti wọn le kuro nilu Igangan to tẹdo si tẹlẹ.
Seriki Fulani Igangan ni ohun ti oun fẹ beere lọwọ Igboho naa ni pe ki lo ri ti o fi ṣe ikọlu si ibugbe oun niluu Igangan.
- Ta bá gba Seriki Fulani padà sí Igangan, a fi ọwọ́ ara wa, pa ara wa ni - Aráàlú
- Gbèǹdéke ku àsìkò díẹ̀, Seriki Fulani fohùn ránṣẹ́ sí Sunday Igboho
- Báyìí ni àwa àti Sunday Igboho ṣe rìnrìn àjò láti Ibadan lọ sí Igangan"
- Igboho vs Fulani: Báyìí ni nǹkan ṣé ń lọ nílé Sunday Igboho lónìí
- Á fojú Sunday Igboho balé ẹjọ́, á sì gba ₦500m owó ìtanràn fún Seriki - Ẹgbẹ́ Fulani
- Wo nkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Iskilu Wakili, afurasí Balógun Fulani tí OPC mú ní Ayetẹ ìpínlẹ̀ Ọyọ
- Afurasí olóṣèlú tí ọlọ́pàá mú lórí ikú ọmọ mi, ló jẹ́ alátakò rẹ̀ nínú PDP - Baba Aborode
Alhaji Abdulkadir fẹsun kan Igboho pe oun lo ṣiwaju awọn to ṣe ikọlu sile oun níbi tí wọn ti dana sun ibi ti oun n gbe ati ile mẹta mii ti oun kọ si igboro ilu Igangan.
Seriki Fulani sọ fun BBC Yoruba pe Igboho at'awọn ọmọlẹyìn rẹ sekupa eeyan mẹfa nile oun, to fi mọ aburo oun.
Bakan naa lo sọ pe wọn tun dana sun awọn ọkọ oun ati t'awọn ọmọ oun naa.
Seriki Fulani ni Ọlọrun lo da awọn naa ati pe eeyan ni awọn naa jẹ.
Inu inira ni mo wa lẹyin ti mo kuro ni Igangan, aye le pupọ:
Awọn iwe iroyin kan ti kọkọ gbe iroyin kan pe Seriki Fulani sọ pe oun o fẹ ki wọn tu Igboho silẹ ni ahamọ to wa ni Benin Republic.
Alhaji Abdulkadir ni awọn to ran Igboho wa si Igangan lo le sọ bo ya ki wọn tu Igboho silẹ lahamọ tabi ki o sí wa níbẹ.
Seriki Fulani sọ fun BBC Yoruba pe inu inira ni oun ati idile oun wa lati igba ti wọn ti le oun kuro ni Igangan wa si ilu Ilorin.
"Nkan ti inu mi n dun si ni pe ko si enikan to ni ẹri to daju lati sọ pe oun n gbabọde fawọn Fulani ajinigbe.
Ẹ fun wa ni owo gba ma binu lati di dukia wa to sofo ati idajọ ododo - Seriki Fulani
Seriki Fulani wa n beere lọwọ ijọba Gomina Seyi Makinde tipinlẹ Oyo lati fun oun, at'awọn Fulani mii ti wọn le kuro ni Igangan, ni owo gba ma binu.
O ni nnkan le koko fun oun atawọn eeyan miran lẹyin isẹlẹ naa, ti wọn le awọn kuro ni Igangan, ti awọn ko ri dukia kankan mu kuro nibẹ.
"Lẹyin ọdun kan ti ikọlu yii waye tan, a ko tii ri nkan kan gba lọwọ ijọba.
Gbogbo ohun ti mo ṣiṣẹ ko jọ ni wọn parun patapata lọjọ kan, awọn maalu mi ti mo padanu le ni igba nilu Igangan.
Asiko ibo lo n bọ yii, awọn oloṣelu kii da ni ile mi, ibudo idibo meji lo wa ni ile mi nikan niluu Igangan.
Idajọ ododo ni mo fẹ ko waye lori bi wọn ṣe le wa kuro niluu Igangan.
Ati emi ati gbogbo awọn Fulani mii ti wọn le kuro ni Igangan ni mo n gbẹnu sọ fun un," Seriki Fulani lo sọ bẹẹ.
Mo fẹ pada si Igangan, ti wọn ba fẹ ka pada sibẹ:
Nigba to n sọrọ nipa bi igbe aye rẹ se ladun, to si larinrin nigba to wa nilu Igangan, Seriki Fulani ni yoo wu ohun lati pada silu naa.
Seriki ni " bi wọn ba fẹ ka pada si Igangan, awa naa setan lati pada sibẹ nitori awa kọ ni a ja tabi le ara wa.
Ko si ohun to buru ti wọn ba gba wa laaye lati pada silu Igangan."
Ki lo sẹlẹ si Seriki Fulani ni ọdun kan sẹyin nilu Igangan?
O le ni ọdun kan sẹyin ti isẹlẹ eto aabo ti ko fi ara rọ ti n waye nilu Igangan ati agbegbe Oke Ogun lapapọ.
Ọpọ isẹlẹ ipaniyan laibikita, ijinigbe, ifiyajẹni ati ifipabanilopọ lo n waye lagbegbe naa, tawọn ọmọ onilu si di ẹbi awọn isẹlẹ naa ru awọn afurasi darandaran Fulani, eyi ti Seriki Fulani jẹ asaaju wọn.
Koda, ọpọ eeyan agbegbe naa lo ti ko kuro nile wọn nitori ikọlu ojoojumọ ọhun, ti apa awọn agbofinro ko si ka awọn afurasi ọdaran naa.
Koda, wn tun fi ẹsun kan awọn ọlọpaa agbegbe naa pe se ni wọn n segbe sẹyin awọn eeyan to n huwa ọdaran ọhun, ti wọn si n tu wọn silẹ ni ahamọ.
Idi ree ti ajijagbara ọmọ Yoruba kan, Sunday Igboho fi pasẹ fun Seriki Fulani pe ko kuro ni agbegbe naa, to si fun ni gbedeke ọjọ meje lati pa asẹ naa mọ.
Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ kejilelogun osu Kinni ọdun 2021 ni gbekede ọjọ meje ti Sunday Igboho fun Seriki Fulani pe, eyi to fi pasẹ fun lati kuro Igangan.
Ọjọ yii kannna si ni Igboho ati awọn ọmọ lẹyin rẹ lọ silu naa fun iwọde, lẹyin to si kuro nibẹ ni awọn eeyan kan fi ina bọ̀ ile atawọn dukia Seriki Fulani.






















