Sammie Okposo: Torí mo bá obìnrin kan ní àjọṣepọ̀ l‘Amẹ́ríkà, mó ń wá ojú Ọlọ́run

Oríṣun àwòrán, Sammie Okposo Instagram
Se ni ori ayelujara n gbona fẹlifẹli nipa bi gbajugbaja ojisẹ Ọlọrun ati akọrin ẹmi kan se jẹwọ iwa agbere to hu lasiko to rinrinajo lọ silẹ okeere.
Akọrin ẹmi naa, Sammie Okposo lo tọrọ aforijin naa ninu iwe kan to kọ sawọn ọ̀rẹ́ ati ololufẹ rẹ eyi to ti lu ori ayelujara pa.
Se ni ẹnu si n ya ọpọ eeyan nipa igbesẹ ẹni ẹmi naa, paapaa lori iwe to kọ sita nipa isẹlẹ naa.
- Aráàlú fẹsẹ̀ fẹ bí jàndùkú ṣe dáná sun ọba wọ́n àti èèyàn mẹ́ta míì l‘Ogun
- Mercy Aigbe kéde orúkọ tuntun lẹ̀yìn ìgbéyàwó rẹ̀ pẹ̀lú Adekaz
- "Mo padanu isẹ mi tori n ko gba abẹrẹ àjẹsára Covid-19"
- Èèyàn mẹ́jọ kú, ọ̀pọ̀ farapa lásìkò ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ láàrin Cameroon àti Comoros
- Ìwádìí rèé lórí fídíò tó ṣàfihàn bí agbébọn ṣe tú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sí ìhòhò
- Mo fẹ́ fojú rí Sunday Igboho ní àhámọ́ tó wà, kò sì ní bọ́ níbẹ̀ - Seriki Fulani
- Ìjọba Kano gbẹ́sẹ̀lé ìwé àṣẹ gbogbo ilé ẹ̀kọ́ aládàni lẹ́yìn ikú ọmọdébìnrin Hanifa Abubakar
Oniruuru eeyan lo ti wa n sọ ero rẹ nipa isẹlẹ naa lori ayelujara, ti iroyin kan tiẹ ni obinrin ara Amẹrika naa ti loyun fun bi o tilẹ jẹ pe a ko le fidi eyi mulẹ.
Iwa wo ni Sammie Okposo hu, to mu ọgbẹ ọkan ba iyawo rẹ?
Okposo salaye pe ni opin ọdun to kọja 2021, ni oun tẹkọ leti rinrin ajo lọ silẹ Amẹrika, ti oun si yan obinrin kan ni ọrẹ.
O ni lootọ ni oun mọ pe igbesẹ naa ko tọna, ti ko si ba ifẹ Ọlọrun mu gẹgẹ bi akọrin ẹmi ati pe oun ti se igbeyawo.
Koda, oju n ti oun, ti oun si kabamọ iwa pansaga ti oun hu yii ati irora nla ti igbesẹ naa ti mu ba iyawo oun, Ozioma, idile oun ati oun gan alara.
Igbesẹ wo ni ojisẹ Ọlọrun yii gbe lẹyin isẹlẹ yii?
Ninu lẹta iforijin naa ni Sammie Okposo ti wa kede pe nibayi ti oun ti n wa ọna lati rin ni alaafia pẹlu Ọlọrun, oun si n tọrọ aforijin siwaju.
Okposo ni "Mo ti da ara mi duro na kuro ninu gbogbo awọn isẹ to jẹ mọ ti iransẹ Ọlọrun titi ti maa fi ni idapada tootọ.
Eyi ni igbesẹ to tọna niwaju Ọlọrun, mo si jẹ Ọlọrun ati awọn eeyan ni gbese yii."
Okposo bẹ iyawo rẹ fun ijakulẹ to mu ba igbẹkẹle to ni ninu rẹ:
Akọrin ẹmi naa wa sọ fun Ozioma aya rẹ pe oun kabamọ pupọ pe oun ko ojuti ba, ti oun si da igbagbọ ati igbẹkẹle to ni ninu oun.
"Idarijin rẹ se pataki fun mi lori iwa ijakulẹ ti mo hu, mo si gbadura pe titi gbogbo ọjọ aye mi ni maa fi maa wa ọna lati tun gbe igbagbọ ati igbẹkẹle naa ro."

Oríṣun àwòrán, Screen shot
Mo tọrọ aforijin lọwọ awọn ọmọ ijọ mi - Sammie Okposo
Sammie Okposo wa tun tọrọ aforijin ninu lẹta naa, lọwọ awọn baba ati iya rẹ ninu igbagbọ, to fi mọ awọn ojisẹ ihinrere fun iwa aimọra to hu naa.
O ni oun kabamọ pupọ nipa ihuwasi oun naa pẹlu afikun pe ti kii ba se igbagbọ wọn pe Ọlọrun lo pe oun si isẹ iransẹ, oun ko ba ti si mọ.
O tun wa rawọ ẹbẹ si awọn ọmọ ijọ rẹ atawọn eeyan to n tẹle oun lẹyin lai mọ oun ni ojukoroju pe oun n tọrọ aforijin pe oun ja wọn kulẹ.
Bakan naa lo ni oun kabamọ nipa irora ọkan ti oun ti le mu ba wọn amọ ki wọn tubọ maa gbadura fun oun ni.
Ta ni Sammie Okposo?
Ọgbọnjọ osu Karun ọdun 1971 ni wọn bi Sammie Okposo tii se gbajugbaja akọrin ẹmi ati aluduuru.
Ọdun 2004 lo kọkọ gbe awo orin sita amọ o ti dara pọ mọ ọpọ olorin ẹmi miran lati se awo orin to gbajumọ sita.
Akọrin ẹmi naa ti sere kaakiri awọn orilẹede lagbaye to fi mọ Yuroopu, Amẹrika ati Gẹẹsi.
Awo orin ti Okposo gbe jade gbẹyin lọdun 2018 lo pe akọle rẹ ni The Statement, to si ti gba ami ẹyẹ jakejado agbaye.




















