2023 elections: David Oyedepo ní ààrẹ Nàìjíríà lè jáde láti inú ìjọ Winners

Oríṣun àwòrán, David Oyedepo
Oludasilẹ ijọ Living Faith ti ọpọ mọ si Winners Chapel, Biṣọọbu David Oyedepo ti o ṣeeṣe ki Ọlọrun yan aarẹ Naijiria to kan lati inu ijọ naa.
Oyedepo ni o le jẹ ki pe ijọ Winners ni aarẹ obinrin akọkọ ni Naijiria yoo ti jade.
Biṣọọbu sọrọ yii lasiko to n waasu lọwọ ninu ijọsin ọjọ Aiku ni gbọngan ṣọọṣi naa to wa ni Ota, ipinlẹ Ogun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ṣé lóòtọ́ ni Mercy Aigbe ti sẹ ìgbéyàwó pẹ̀lú Adekaz, àbọ̀ ìwádìí wa rèé
- Wo nkan tí yóò ṣẹ̀lẹ̀ ní àgọ́ ara rẹ tí o kò bá ní ìbálòpọ̀ fún ìgbà pípẹ́
- Adájọ́ àgbà ìpínlẹ̀ Ogun pàṣẹ pé kí wọn tú ẹlẹ́wọ̀n 20 sílẹ
- 'Mo máa ń ṣa ìdọ̀tí kúrò lójú omi láti dóòlà ẹ̀mí ìjàpá ni'
- Wọ́n ṣàwárí òkú ọmọ ọdún mẹ́ta ní Jigawa
- Àwọn Àgùnbánirọ̀ ni kò jẹ́ kí ìkúrẹtẹ̀ bá ẹ̀ka ìlera àti ẹ̀kọ́ - DG NYSC
Oyedepo wa rọ gbogbo awọn ọmọ mi ìjọ rẹ ti wọn ba fẹ dupo oṣelu lati beere fun itọni lori erongba wọn.
"O ṣe pataki fun mi lati sọ fawọn ọmọ ijọ wa to jẹ oloṣelu bayii tori asiko ibo mii tun ti sun mọ etile.
Ko ba san yin bi ẹ itọni lọdọ wolii ki ẹ baa ko ara yin si wahala.
Ko si ọfiisi oloselu kan ti ẹnikẹni le wa ti mo maa nilo ni iranlọwọ lati ọdọ rẹ."
N ko nilo iranlọwọ oloselu kankan - Oyedepo
Nigba to n sọrọ nipa iranlọwọ ti oloselu le se fun, Oyedepo ni "Láéláé! Oluranlọwọ mi si wa loke titi ayeraye ati pe awọn gan an mọ pe n ko beere nkan kan ri lọwọ ẹnikẹni.
Ẹ jẹ ki Ọlọrun ṣe atọna yin ninu irinajo oselu yin, ẹ ma jẹ ko jẹ pe ojukokoro lo n ti yin.
Ẹ ma ṣi mi gbọ o, Ọlọrun le yan aarẹ orilẹede Naijiria lati inu ijọ yii.
Koda, ẹni naa le jẹ aarẹ obinrin akọkọ orilẹ-ede Naijiria," Oyedepo lo sọ bẹẹ.
Ta ni Bisọọbu David Oyedepo?
Bisọọbu David Oyedepo ni gbajumọ ojisẹ Ọlọrun ti olu ijọ rẹ tẹdo si orilẹede Naijiria, o tun jẹ oniwaasu, onkọwe Kristiẹni yika agbaye.
Bakan naa ni ibujoko ijọ rẹ to tobi julọ wa nilu Sango Ota nipinlẹ Ogun, ti ẹka ijọ rẹ si tan yika ilu to le ni ọọdunrun ni Naijiria ati ni orilẹede agbaye bii marundinlaadọta to fi mọ ilẹ UK, Amẹrika Yuroopu, Asia, Canada ati Dubai.
Bakan naa lo se idasilẹ ile ẹkọ fasiti aladani nla meji, Covenant University ati Landmark University, ti iwe iroyin atigbadegba Forbes si ni o wa lara awọn oniwaasu to gbajumọ julọ ni Naijiria.
Oyedepo wa lara awọn ojisẹ Ọlọrun to ra baalu fun isẹ ihinrere ni Naijiria, to si maa n bu ẹnu atẹ lu isejọba ti ko dara ati iwa ajẹbanu to gogo nilẹ Afirika.

















