Covid 19 fraud, Dapo Abiodun aid: Wo ǹkan méje tí o kò ma nípa Bidemi Rufai, tó wọ gàu l'Amerika lórí ẹ̀sùn jìbìtì N140m

Oríṣun àwòrán, @Bidemirufai
Wo kókó mẹ́jọ tó yẹ kí o mọ̀ nípa Abidemi Rufai
Lọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlogun oṣu karun ọdun 2021 yii ni ẹka eto idajọ orilẹ-ede Amẹrika kede pe oun ti gbe oludamọran Gomina Dapo Abiodun ipinlẹ Ogun, Abidemi Rufai lọ si ileẹjọ lori ẹsun lilu jìbìtì $350,000.
Ọdun 2020 ni Gomina ipinlẹ Ogun yan Rufai sipo ọkan lara awọn oluranlọwọ rẹ.
Ṣugbọn Gomina Abiodun ti jawe gbele ẹ fun Rufai lati igba ti iroyin ọhun ti jade lati Amerika.
- Lizzy Anjorin sọ̀rọ̀ sókè lórí obìnrin tó ń ba fa sùrútù torí ọkọ rẹ̀
- Ahmed Isah, Ordinary President, ṣàlàyé ìdí tó fí dá ìgbájú-ìgbámú bó obìnrin lórí afẹfẹ
- Èèmọ̀ wọ̀lú! Àwọn jàndùkú jí Adájọ́ gbé lọ nínú kóòtù lọ́sàn án gangan
- Ọwọ́ tẹ àwọn afurasí afipábánilòpọ̀ 206 l'Eko
- Wo ojú àwọn ọmọ Yahoo tí EFFC lọ́ mú l‘Osogbo, tí ọ̀rọ̀ fi dariwo
Wọnyii ni koko mẹjọ ti o yẹ ki o mọ nipa oluranlọwọ gomina ipinlẹ Ogun ti wọn gbe lọ si ileẹjọ lorilẹede Amerika lori ẹsun jibiti owo.
1. Abidemi Rufai fi igba kan dupo sí ile igbimọ aṣoju-ṣofin l'Abuja lẹkun aarin gbungbun Ijebu labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC.
2. Ọmọ ọdun mejilelogoji ni Rufai í ṣe, o si n gbe ni agbegbe Lekki niluu Eko
3. Rufai ni iṣẹ kara kata ilẹ ati ile ni oun n ṣe.
Ko da, o ni oun ni oludasilẹ ileeṣẹ Omo Mayodele Educational Foundation to maa n ran awọn ti ko rọwọ họri lawujọ lọwọ.
4. Ọjọ Ẹti tii ṣe ọjọ kẹrinla oṣu karun un ọdun 2021 ni wọn mu Rufai lori ẹsun jibiti owo to to ogoje mílíọ̀nù naira, N140m.
5. Gẹgẹ bí ohun tí ẹka eto idajọ orilẹ-ede Amẹrika sọ, laarin oṣu kẹta sì ikẹjọ ọdun 2020 ni Rufai Lu Jibiti owo naa
6. Rufai lo ọpọ awọn olugbe ilẹ Amerika ni Washington bíi ọgọrun lati lù Jibiti ogoje mílíọ̀nù naira owo to yẹ kó ṣanfaani fáwọn ti covid-19 ti ṣakoba iṣẹ wọn.
7. Ọjọ kọkandinlogun oṣu karun ọdun 2021 ni ignẹnọ Rufai bẹrẹ nile ẹjọ.
8. Ti o ba jẹbi awọn ẹsùn tí wọn fi kan an, Rufai le lọ fi aṣọ penpe roko ọba fún ọgbọn ọdun.














