EFCC in Osogbo: EFCC fi ojú àwọn afurasí ọmọ Yahoo tó mú kàwọn ọ̀dọ́ ìlú Osogbo yarí mọ́ wọn lọ́wọ́

Oríṣun àwòrán, Efcc
Ọdọmọdekunrin ẹni ọdun mejilelogun kan to sa kuro niṣẹ ologun wa, lara awọn ọdọ mẹrinlelọgbọn tawọn ẹṣọ EFCC ko, lasiko ti wọn wọ ilu Oṣogbo.
Awọn osisẹ ajọ EFCC naa lo lọ silu Osogbo lati lọ ko awọn afurasi onijibiti, ti ọpọ eeyan mọ si ọmọ Yahoo, lọjọ Aje mọju ọjọ Iṣẹgun.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọrọ kiko awọn ọmọ oni Yahoo naa da wahala silẹ nilu Osogbo fun ọpọlọpọ wakati, lasiko ti awọn ọdọ kan tawọn eeyan fura si pe wọn jẹ onijibiti ori ayelujara ti ọpọ mọ si yahooboys, dana wahala silẹ lawọn agbegbe kan ni igboro ilu Osogbo, bẹrẹ lati afẹmọjumọ ọjọ Iṣẹgun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Lizzy Anjorin sọ̀rọ̀ sókè lórí obìnrin tó ń ba fa sùrútù torí ọkọ rẹ̀
- Níbo ni Baba Ijesha wà lẹ́yìn wákàtí 48 tí wọ́n gba béèlì rẹ̀?
- Ọmọ Yahoo gba ọkọ̀ 25 padà lọ́wọ́ ẹ̀ṣọ́ EFCC lásìkò tí wọn dènà dè wọ́n l‘Osogbo
- Ẹ fún wa láàyè díẹ̀ si, kẹ tó fòfin de ẹ̀ran dídà nígboro - Fulani darandaran rawọ́ ẹ̀bẹ̀
- Òkú jíndé nígbà tó ku ìṣẹ́jú péréte ti wọ́n yóò se ètò ìkẹyìn fun
- Àwọn nọ́ọ̀sí àti àwọn òṣìṣẹ́ mííràn tó darapọ̀ mọ́ ìyásẹ́lódì le gbà ìwé ìdádúró
- Ọwọ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ sí Gómìnà Ogun ségi lórí ẹsùn jìbìtì $350,000
Ajọ EFCC ṣalaye loju opo ayelujara rẹ gbogbo pe, awọn ẹṣọ rẹ lati ẹka ileeṣẹ EFCC nilu Ibadan ni wọn lọ fi panpẹ ofin mu ọdọmọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Adebisi Jamiu.

Oríṣun àwòrán, Efcc
Bakan naa ni wọn ko awọn miran ti iwadi ọtẹlẹmuyẹ ajọ naa ti fidi rẹ mulẹ pe wọn lọwọ ninu gbigba owo kotọ nipa lilu jibiti ori ayelujara ti wọn n pe ni "Yahoo-yahoo".
Awọn yooku ti ajọ EFCC ni ọwọ awọn ẹṣọ awọn tun ba ni Muritala Olaniyi Lateef, Wasiu Olajide, Wasiu Sadiq, Olaniran Abiodun, Ayodeji Tosin, Olaniran Tayo, Oginni Oluwaseun, Oginni Olatunde, Ojuade Oluwafemi and Ibrahim Wande.
Bakan naa ni ọwọ ajọ naa tun tẹ Oladiran Olayinka, Akinjobi Akinwunmi, Abayomi Aderohunmi, Olaoluwa Temitope, Idowu Olawale, Lawrence Taiwo ati Ojo Gbenga.

Oríṣun àwòrán, @officialEFCC
Awọn yoku ni Tiamiyu Farouk, Oladele Seun, Akiniyi Boluwatife, Olaoluwa Mutiu, Olakunle Omolofe, Olalere Samad, Edbadon Johnson, Oketunbi Kayode ati Gbeyide Tomiwa.
Bakan naa ni wọn darukọ Oluwanisola Elmuqsit, Bathlomew John, Ibikunle James, Olamide Oluwaseyi, Yusuf Mohammed, Adebola Ibrahim, ati Ajayi Muyiwa.

Ọmọ Yahoo gba ọkọ̀ 25 padà lọ́wọ́ ẹ̀ṣọ́ EFCC lásìkò tí wọn dènà dè wọ́n l'Osogbo

Oríṣun àwòrán, TWITTER/SON OF OSUN
Ọkọ marundinlọgbọn tawọn ẹṣọ EFCC gba lọwọ awọn ọdọ ti wọn furasi pe wọn ṣe Yahoo Yahoo l'Osogbo, lawọn ọdọ naa gba pada lọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ atawọn iwa ọdanran miran ni Naijiria.
Ninu awọn iroyin abẹle to suyọ nilu Osogbo, awọn ọdọ naa fariga pe iwa idukokomọni awọn ẹṣọ EFCC naa ti pọ ju fun awọn lẹnu lọwọlọwọ yii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Baba Ijesha yóò jẹ́jọ́ ìwà tó hù, ohun tó bá gbà, ni màá fun - Iyabo Ojo
- Ẹ fún wa láàyè díẹ̀ si, kẹ tó fòfin de ẹ̀ran dídà nígboro - Fulani darandaran rawọ́ ẹ̀bẹ̀
- Òkú jíndé nígbà tó ku ìṣẹ́jú péréte ti wọ́n yóò se ètò ìkẹyìn fun
- Àwọn nọ́ọ̀sí àti àwọn òṣìṣẹ́ mííràn tó darapọ̀ mọ́ ìyásẹ́lódì le gbà ìwé ìdádúró
- Ọwọ́ amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ sí Gómìnà Ogun ségi lórí ẹsùn jìbìtì $350,000
- Àwọn ọmọ Yahoo dènà de ẹ̀ṣọ́ EFCC tó fòru wọ̀lú l'Osogbo, nǹkan yan
- Àwọn nọ́ọ̀sí àti àwọn òṣìṣẹ́ mííràn tó darapọ̀ mọ́ ìyásẹ́lódì le gbà ìwé ìdádúró
- Nàìjíríà ti rí €4.2m gbà padà nínú owó tí James Ibori gbé- Malami
- Wo ìdí mẹ́fà tí ìjóba kò se tíì kápá Boko Haram
Ni alẹ ọjọ Aje lawọn ẹṣọ ajọ EFCC kan wọlu Osogbo lati fi panpẹ ofin mu awsn eeyan kan ti wọn fura si pe wọn n lọwọ ninu owo jibiti ati gbajuẹ ori ayelujara ti ọpọ mọ si "Yahoo-yahoo"

Oríṣun àwòrán, Twitter/son of osun
Awọn akẹgbẹ wọn ṣa ara wọn jọ lati dena de awọn ọdọ naa ni abajade wọn.
Iroyin sọ pe awọn ọdọ naa gba awọn ọkọ ayọkẹlẹ olowo iyebiye ti wọn ko pẹlu awọn afurasi naa pada ki o to di pe wọn da wahala silẹ nilu Osogbo ni gbogbo ọjọ Iṣẹgun.

Oríṣun àwòrán, @jasimania

Àwọn ọmọ Yahoo dènà de ẹ̀ṣọ́ EFCC tó fòru wọ̀lú l'Osogbo, nǹkan yan

Oríṣun àwòrán, Twitter/Mayowa Olagunju
Ibẹrubojo lo gbode kan lawọn agbegbe kan lafẹmọjumọ ọjọ Iṣẹgun ni ilu Osogbo ni ipinlẹ Osun.
Awọn ọdọ kan ti ọpọ furasi gẹgẹ bi olowo jibiti ori ayelujara, ti ọpọ mọ si 'Yahoo boys' fariga, ti wọn si da igboro ru nigba tawọn oṣiṣẹ ajọ EFCC kan ba wọn lalejo lati fi panpẹ ofin mu wọn.
Awọn ẹṣọ ajọ EFCC naa ni iroyin sọ pe, wọn foru wọlu Osogbo lati mu awọn afurasi ọmọ yahoo, ki awọn ọdọ kan to da wọn lọna lẹyin ti wọn ti gba ogun ọkọ olowo iyebiye, ti wọn si tun mu awọn afurasi kan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Iyabo Ojo fèsì lórí béèlì tí wọ́n fún Baba Ijesha
- Princess pàrokò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ lẹ́yìn tí Baba Ijesha gba béélì
- Baba Ijesha gba béélì níléẹjọ́ Májísírétì, àmọ́ ọ̀rọ̀ kù kó tó jáde l’àhámọ́
- Ẹ̀yin ọdọ́, ẹ sọ́ra fún ìtànjẹ láti darapọ̀ mọ́ ìyapa Naijiria - YAF
- Sunday Igboho, jọ̀ọ́ má gbé ìwọ́de Yoruba Nation wọ Iseyin - Aseyin ṣèkìlọ̀
- Sunday Igboho lọ sọ́dọ̀ Guru Maharaji lórí ìdásílẹ̀ Yoruba Nation
- "Sunday Igboho kò fí lààkáyé kún ìjìjàgbara rẹ̀ nípa àtakò sí ìbò 2023"
- Mò ń wá olè tó jí nńkan ní ọọ́físì mi, ẹ̀bùn owó iyebíye rèé - Afeez Eniola
- Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìlú Modakeke àti Ile Ife
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Baba Ijesha ti jáde ní àhámọ́ ọlọ́pàá?
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ awọn ẹṣọ EFCC naa ni lati wa ibi gba fun aabo ẹmi ara wọn.
Awọn ọdọ naa dana si oju popo ni agbegbe Lameco ni olu ilu ipinlẹ Ọṣun naa.

Oríṣun àwòrán, Twitter/mayowa olagunju
Eeyan kan loju opo Twitter to pe orukọ ara rẹ ni Mayọwa Ọlagunju ṣalaye pe, oru lawọn ẹṣọ ajọ EFCC naa ya wọ agbegbe Adetunji Estate nilu Osogbo, lati ṣa awọn ti wọn fura si pe wọn jẹ "ọmọ yahoo".
N ṣe lawọn ọdọ agbegbe naa ba fọn sita, ti wọn si di gbogbo ọna ti awọn ẹṣọ EFCC naa lee gba jade.
O ni nṣe lawọn 'Ọmọ Yahoo' yari tan patapata, ti wọn si n pariwo pe "o to gẹ, iwa ilọnilọwọgba awọn ẹṣọ EFCC buru ju ti ọlọpaa kogberegbe SARS lọ"

Oríṣun àwòrán, Screenshot














