EFCC. Babachir, Yero, Babangida, Adoke, Metuh, Orji, Maina: Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba nígbà kan tí wọ́n pé lẹ́jọ́ ni 2021.

EFCC

Wo àwọn gbajúgbajà ojú ti EFCC máa ba ṣe ẹjọ́ ní 2021

Àjọ to ń gbógun ti ṣíṣe owó ìlú mọ́kumọ̀ku, (EFCC) tí fi orúkọ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba nígbà kan rí síta láti ṣe ẹjọ́ wọn nínú ọdún yìí.

Àjọ náà àwọn n sapá lọ́wọ́ láti mú àwọn ọ̀daràn náà

Àwọn ènìyàn náà rèé:

1) George Turnah:

George Turnah jẹ́ olùbádámọ̀ràn Dan Abia ni ile iṣẹ́ Niger Delta (NDDC).

Wọ́n tún Turnah mú ní ọjọ́ kejilelogun oṣù kini pẹ̀lú Ebis Orubebe àti Uzorgor Silas Chidebere fún ẹ̀sùn ìkọ́wọ́ jẹ́ tó dín díẹ̀ ní bílíọ̀nù mẹ́ta náírà.

Bákan náà ni wọ́n tún fẹ̀sùn ìbanilórúkọ jẹ́ kàn wọ́n.

Wọ́n tí bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ láti ọdún 2017 yóò sì tẹ síwájú nínú ọdún 2021, ìgbẹ́jọ́ tí Muhammed Turaki tí ilé ẹjọ́ gíga ìlú Porthacourt yóò mú gbọ́.

Àkọlé fídíò, Ìtanijí lórí BBC Yorùbá: Odú Iwori Obara bá wa sọ̀rọ̀ lórí ìfaradà tó pọ̀

2) Adesola Amosu:

Amosu jẹ́ olórí ẹ̀ṣọ́ àbò ojú ofurufu nílé iṣẹ́ ọmọogun ojú ofurufu.

Ọ̀gbẹ́ni Amosu ń jẹ́jọ́ níwájú adájọ́ Chukwujekwu tí ilé ẹjọ́ gíga tí Ikoyi nípìnlẹ̀ Eko.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Asa Ondo: Wo ìdí tí Yorùbá ṣe ń lo Ìjàpá ni olú ẹ̀dá ìtàn Àlọ́ Àpagbé- Oyelo

Bakan ni wọ́n pèé lẹ́jọ́ pẹ̀lú ọmọogun ojú ofurufu Vice Marshall Jacobs Adigun, òun ló ń mójú tó àpò owó ilé iṣẹ ọmọogun Òfurufú tẹ́lẹ̀ rí.

Bákan náà ni Owodunni Olugbenga to jẹ́ adarí ètò owó ilé iṣẹ́ ọmọogun tẹ́lẹ̀.

Ẹ̀sùn ìkówó jẹ́ bílíọ̀nù mọ́kàndílógún náírà tó jẹ́ ti ilé iṣẹ́ ọmọogun ni wọ́n dà sapò.

Ìgbẹ́jọ́ náà yóò bẹ̀rẹ̀ padà ní ọjọ́ Kejìlá, ọjọ́karùndínlógún àti ogúnjọ́ oṣù kẹrin, ọdún 2021.

Àkọlé fídíò, World Cancer Day: Mo pàdánù ọkọ àti ọ̀rẹ́ bí mo ṣe ni 'Cancer'- Iwalade Adebimpe Adetunji

3) Babachir Lawal:

Ìgbẹ́jọ́ akọ̀wé ìjọba àpapọ̀ tẹ́lẹ̀ wà níwájú adájọ́ Charles Agba a ti ilé ẹjọ́ gíga Jabi nílùú Abuja.

Ìṣẹ́ kọngílá koríko gígí ni wọ́n fi fẹ̀sùn kan.

Babachir Lawal àti àbúrò rẹ̀, Hamidu Lawal, Suleiman Abubakar àti Apeh John Monday, to fi mọ́ ilé iṣẹ́ méjì kan Rholavision Engineering àti Jos on Technologies ni wọ́n fẹ̀sùn kan pọ̀.

Wọ́n fẹ̀sùn ìgbìmọ̀ pọ̀ láti hùwà ọ̀daràn àti níná mílíọ̀nù tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tà náírà nínàkúnàá.

Àjọ EFCC ni àwọn tí fojú Ẹlẹ́rìí méjì hàn pẹ̀lú àwọn ìwé láti ti ìgbẹ́jọ́ àwọn lẹ́yìn.

Ìgbẹ́jọ́ náà yóò bẹ̀rẹ̀ padà ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejì ọdún 2021.

Babachir

Oríṣun àwòrán, @Babachir

4) Abubakar Mohammed Sani:

Ó jẹ́ ìgbàkejì alága ìgbìmọ̀ ilé iṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ọgbà ẹ̀wọ̀n, wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó gba owó tó dín díẹ̀ ni mílíọ̀nù mẹta náírà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn tó ṣèlérí láti fún níṣẹ́.

Ṣáájú ni wọ́n ti fi sí gbaga ní ojọ́ Kẹ̀sán, ọdún 2020 tí adajọ Hadiza Sabi'u Shagari tí ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Katsina, ó ní òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn.

Wọ́n tí sún ìgbẹ́jọ́ náà sí ọjọ́ kẹrin, oṣù kejì, ọdún 2021.

5) Mukhtar Ramalan Yero:

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna tẹ́lẹ̀ náà ń jẹ́jọ́ níwájú adájọ́ ZB Abubakar tí ilé ẹjọ́ gíga Kaduna.

Wọ́n fẹ̀sùn fún bíbuwọ́lu pínpín owó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin miliọ́nù náírà tí mínísíta ọ̀rọ̀ epo rọ̀ọ̀bì tẹ́lẹ̀ rí Diezani Allison-Madueke gbékalé láti lò fún ṣíṣe ètò ìdìbò mọ́kumọ̀ku.

Yero àti mínísíta kékeré NuhuSomo Waya, alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tẹ́lẹ̀ri ni Kaduna, Abubakar Haruna Gaya àti akọ̀wé ijoba tẹ́lẹ̀ Hamza Isaq.

Wọ́n tí sún ìgbẹ́jọ́ náà sí ọjọ́ kẹtàdínlógbọ̀n, oṣù kejì, ọdún 2021

EFCC

Oríṣun àwòrán, facebook

6) Kabiru Tanimu Turaki:

Ìgbẹ́jọ́ mínísíta iṣẹ́ àkànṣe Sampson Okpetu náà yóò tẹ̀ síwájú lọ́jọ́ karùnlélógún oṣù kini ọdún 2021.

Kíkó owó tó dín díẹ̀ lẹ́ẹ̀dẹ́gbẹ̀rìn mílíọ̀nù jẹ ní ẹ̀sùn ni adájọ́ Inyang Ekwo to wà nídìí ìgbẹ́jọ́ náà fi kàn wọ́n nílé ẹjọ́ gíga ìlú Abuja.

Ìgbẹ́jọ́ náà yóò tún wáyé ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kejì, ọdún nílùú Abuja.

7) Babangida Aliyu:

Ìgbẹ́jọ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Niger tẹ́lẹ̀ri tí ni ìpèníjà onírúurú láti ọdún 2017 tí EFCC tí kọ́kọ́ pee lẹ́jọ́.

EFCC

Oríṣun àwòrán, others

Onírúurú adájọ́ ló sì ti dáa lẹ́bi.

Wọ́n sún ìgbẹ́jọ́ ré sí ọjọ́ kejìdínlógún oṣù kíní, ọdún 202 nítorí adájọ́ àgbà AB Aliyu kò wá sílé ẹjọ́.

Nítorí náà wọ́n sún ìgbẹ́jọ́ náà sí ọjọ́ kọkàndílọ́gbọ̀n, oṣù kẹta, ọdún 2021.

Gómìnà nígbà kan rí ọ̀hún àti aṣojú osisẹ̀ ilé ìjọba rẹ̀, Umar Nasako ni wọ́n jọ fi ẹ̀sùn bílíọ̀nù méjì náírà kàn. 8) Andrew Yakubu:

Adájọ́ àgbà ilé ẹjọ́ gíga ìlú Abuja Ahmed Mohammed tí fi ìdajọ́ si ọjọ́ keje, oṣù kejì, ọdún 2021, pe ki EFCC sàbẹ̀wò sí banki àpapọ̀ Nàìjíríà, eka tí Kano, láti ṣe ìwádìí ìkọ́wọ́ jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́wàá dọ́là dín díẹ̀.

Àkọlé fídíò, Big breast: Oluwatosin Adegboro, Oluwaseun Amoo, Remi Fatolu: Ẹlòmíì ń fi irú ọyàn wa tọrọ

Yakubu ni adarí ilé iṣẹ́ NNPC tẹ́lẹ̀ri.

EFCC tí fi ẹ̀sùn ìkówó jẹ kan Yakubu lẹ́yìn tí asòfófó ìwà ìbàjẹ́ gbowó kan tí tú àṣírí fún EFCC.

EFCC lọ tún ilé rẹ̀ ní agbègbè Sabon Tasha nílùú Kaduna tí wọ̀n si ri owó iyebíye tó kó pamọ́ sílé.

Wọ́n sún igbẹ́jọ́ sí ojọ́ kọkàndílọ́gbọ̀n oṣù kẹta ọdún 2021.

9) Mohammed Adoke:

Igbẹ́jọ́ tí minisita ètò ìdajọ́ àti agbẹjọ́rò ìjọba àpapọ̀ Nàìjíríà Mohammed Adoke tí wọ́n fẹ̀sùn ṣíṣe owó ìlú mọkumọku tí wọ́n fi kàn ní wón sún sì ọjọ́ kọkànlá oṣù kini ọdún 2021, nítorí ọ̀daràn náà kò fojú hàn nílé ẹjọ́.

Adájọ́ Inyang Ekwo ìlú Abuja lọ ń gbọ́ ẹjọ́ náà.

Ìròyìn kan sọ pé Adoke tàn sí ìlú Dubai laipẹ́ lẹ́yìn to ni ààrùn Coronavirus, wọ́n gbáà láàyè láti lọ fún àyẹ̀wò ara rẹ̀ ṣùgbọ́n ó kú díẹ̀ kò padà sílé ni wọ́n ríi pé ó ní ààrùn naa

EFCC

Oríṣun àwòrán, @Efcc

10) Olisa Metuh:

Láti ìgbà pípẹ́ wọn ò tí gbejọ́ agbenusọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC tẹ́lẹ̀ Olisa Metuh.

EFCC fìdí ré mulé wọ́n ṣe ìdajọ́ ré nínú oṣù kejì ọdún 2020.

Ẹ̀wẹ̀ lẹ́yìn àtúngbẹ́yéwò ìdajọ́ náà ni ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn da igbẹ́jọ́ náà nù pé ilé ẹjọ́ ṣe àwọn àṣìṣe kan nínú ìdajọ́ ré.

EFCC

Oríṣun àwòrán, @Kalu

11) Orji Uzor Kalu:

Gómìnà ìpínlẹ̀ Abia nígbà kan rí tó tún jẹ́ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà ti bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe ẹ̀wọ̀n ọlọ́dún méjìlá tí wọ́n dá fún ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Kuje kí ilé ẹjọ́ gíga tó yí ìdajọ́ adájọ́ Idris Mohamme tí ìlú Èkó dànù.

Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí wọ́n tún igbẹ́jọ́ bẹ̀rẹ̀ lórí ẹ̀sùn ìkówójẹ òní bílíọ̀nù méje àti díẹ̀ náírà

Ilé ẹjọ́ gíga Abuja tí fi igbẹ́jọ́ sí ọjọ́ kejì oṣù kejì ọdún, 2021.

EFCC

Oríṣun àwòrán, @Maina facebook

12) Abdulrasheed Maina:

Lẹ́yìn Ẹlẹ́rìí mẹ́sàn láti fìdí ré mulé pé Maina kò bílíọ̀nù méjì náírà owó ifeyinti je, ó sọ fún ilé pé kí wọ́n dá òun silẹ ni ojo kẹsàn-án oṣù Kejìlá ọdún 2020 níwájú adájọ́ Okon Abang nílùú Abuja.

Adájọ́ Abang sún igbẹ́jọ́ si ọjọ́ kẹwàá oṣù Kejìlá láti fún Maina láàyè sọ tẹnu rẹ̀ kí EFCC náà sì sò ìdí tí wọ́n fí ń pèé lẹ́jọ́

Maina tí kọ̀ láti yọjú sì ilé ẹjọ́ tẹ́lẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n yọnda ré, èyí sì mú kí wọ̀n tí oniduro ré sẹ́nátọ̀ Ali Ndume mọ́lẹ̀ títí di ìgbà tí wọ́n fi rí mú ní Niger láti wá fún igbẹ́jọ́.

EFCC

Oríṣun àwòrán, others

13) Murtala Nyako:

Ọjọ́ kerin dínlógún, oṣù kini ọdún 2020 ni EFCC parí igbẹ́jọ́ ẹ̀sùn àjẹbànu òní bílíọ̀nù mọ́kàndílọ́gbọ̀n to fi kan gómìnà ìpínlẹ̀ Adamawa tẹ́lẹ̀ Murtala Nyako.

Ṣùgbọ́n kàkà kí Nyako lọ fún igbẹ́jọ́ Nyako àti àwọn olùjẹ́jọ́ tó kù tó fi mọ́ ọmọ rẹ̀ Abdul-Aziz sọ pé ilé ẹjọ́ tí dá ẹjọ́ náà nù.

Ìdí rèé tí adájọ́ Okon Abang tí gbé àsìkò ìgbẹ́jọ́ tuntun sí ọjọ́ kerindinlogbọ̀n oṣù kejì ọdún 2021 láti tún ẹjọ́ rẹ̀ gbọ́.

EFCC

Oríṣun àwòrán, Getty Images

14) Gabriel Suswam:

Gabriel Suswam jẹ́ igbẹ́jọ́ tó ti gùn jùlọ lára àwọn gómìnà tẹ́lẹ̀ri.

Gómìnà ọ̀hún àti Kọmísọ́nnà ètò owó rẹ̀ Omodachi Okolobia ni wọn kò wá sí sílé ẹjọ́ ni ọjọ́ kejì oṣù kọkànlá, ọdún 2020 níwájú adájọ́ Ahmed Mohammed nílùú Abuja.

Wọ́n fẹ̀sùn kan pé ó kó bílíọ̀nù mẹ́ta àti díẹ̀ náírà jẹ.

EFCC

Oríṣun àwòrán, facebook

15) Doyin Okupe:

Okupe jẹ́ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún ààrẹ Goodluck Jonathan, àjọ EFCC ń bá òun àti ilé iṣẹ́ rẹ̀ méjì sẹ́jọ́ fún lílu mílíọ̀nù tó lé díẹ̀ ni ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin náírà ni pónpó.

Adájọ́ Ijeoma Ojukwu tí ilé ẹjọ́ gíga ìlú Abuja sún igbẹ́jọ́ Okupe sì ojokerindinlogun oṣù kọkànlá ọdún 2020.

16) Winifred Oyo-Ita:

Ó jẹ́ olórí àwọn òṣìṣẹ́ nígbà kan rí, tí wọ́n sì fi esun ìkówójẹ tó lè ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tà mílíọ̀nù náírà jẹ

Oyo-Ita ni wọ́n pè lẹ́jọ́ pẹ̀lú àwọn ilé iṣẹ́ míràn.

Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ