Dapo Abiodun SSA: Ìjọba Ogun júwe ọ̀nà ilé fún amúgbálẹ́gbẹ́ẹ̀ tó ń jẹ́jọ́ ẹ̀ṣùn lílu jìbìtì

Aworan Abidemni ati Gomina Abiodun

Oríṣun àwòrán, Facebook/Abidemi Rufai

Iroyin kan to n tẹwa lọwọ sọ pe amugbalẹgbẹ kan fun Gomina ipinlẹ Ogun, Abidemi Rufai, ti ko si gbaga awọn agbofinro FBI nilẹ Amẹrika.

Eyi ko si sẹyin ẹsun ti wọn fi kan pe o kopa ninu jibiti kan ti wọn fẹ lu ẹka to n pese iranwọ faraalu ti ko niṣẹ lọwọ ni Washington.

Gẹgẹ bi atẹjade ti agbẹjọro agba Tessa Gorman fi sita lorukọ ẹka ipese iranwọ ijọba, ọjọ Ẹti ni wọn mu afurasi naa ni papakọ ofurufu JFK.

Bakan naa ni wọn lo ṣagbatẹru awọn iwa jibiti to fẹ lu ijọba ni gbajuẹ owo to le ni ẹgbẹrun lọna ọtalelọọdunrun din mẹwaa dọla.

Lọjọru ni wọn yoo bẹrẹ igbẹjọ rẹ.

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Ahmed Isah rèé tíí ṣe ààrẹ lásán làsàn ní Nàíjíríà tí inú aráàlú dùn sí

Ijọba Ogun sọrọ soke lori amugbalẹgbẹ rẹ ti wọn fi ẹsun lilu jibiti kan

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Ogun ti sọrọ soke lori isẹlẹ yii, to si ni oun ko tako pe ki afurasi naa foju wina ofin lori ẹsun ti wọn fi kan.

Agbẹnusọ fun Gomina Dapo Abiodun, Kunle Somorin fi to BBC leti pe '' Ipinu ijọba ni pe ki afurasi naa foju wina ofin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹwẹ, Gomina Abiodun ti paṣẹ pe ki wọn da afurasi naa duro rẹ lẹnu iṣẹ, titi ti yoo fi jẹjọ tan lori ẹsun ti wọn fi kan.

O ni laipẹ, ijọba ipinlẹ Ogun yoo fi atẹjade kan sita lati sọ ipinnu rẹ lori isẹlẹ naa lẹkunrẹrẹ.