Boko Haram reasons group not crushed: Wo ìdí mẹ́fà tí ìjóba kò se tíì kápá Boko Haram

Iwadii lorisirisi lo fi han pe awon alakatakiti Boko Haramsi n ba Naijiria wóya ija ni eyi to jẹ́ pe irọ́ ni pe wọ́n ti bori wón.
Ni osu meje lẹ́yin ti Aaré Buhari Muhaamadu gori aleefa lọ́dun 2015 lo ti n pariwo pe wọ́n ti run awon Boko Haram tuutuu ni Naijiria sugbon sibẹ̀, Boko Haram si n sọsẹ́ nibẹ̀.
Nitooto ni awon omo ogun ilẹ̀ NAijiria gbiyanju lati gba awon ilẹ̀ kan pada lọ́wọ́ awon onise ibi Boko Haram ki wọ́n si le wọn jinna ni agbegbe ariwa ila oorun Naijiria nibi ti awon alakatakiti esin Islam naa ti n sọsẹ́ julo.
Sugbon ibeere ọ̀pọ̀ eeyan ni pe to ba jẹ́ pe ijoba Buhari ti fọ́ Boko Haram si wẹ́wẹ́ bi o se ti n so lati 2015 kini o wa yi n selẹ̀ bayii?
Wo idi mẹ́fa ti Naijiria ko se tii bori ogun Boko Haram:
1) Won ko tii wa ojutu si awon isoro ti wọ́n n mẹ́nuba titi di asiko yii:
Kabiru Adamu to je akosemose nipa eto aabo ni Beacon Consulting salaye pe ijoba Naijiri ti gbọ́kan le awon ọmọ ogun ilẹ̀ pupọ̀ ju.
O so fun BBC pe: O seni laanu pe leyin ọdun mejila ti Naijiria ti n jagun Boko Haram, ko i tii si ọ̀nà abayo titi di sinyii.
O ni o se pataki ki awon omo ogun da dojuko Boko Haram ni, ki wọ́n ra ohun eelo t ye, ki wọ́n tun ero wọ́n pa si ọ̀na miran ki ogun to le ọ̀pọ̀ kuro nile ati ilu wọ́n le pari
O ni ki enikeni to el bori agbesunmomi, wọ́n gbadọ̀ tun ero wọ́n pa ni nitori ki se omo ogunilẹ̀ nikan ni eeyan n lo fi bori igbesunmomi rara.
O di dandan ki won kọ́kọ́ wa ojutu si ohun to sokunfa iwa ibi naa ni NaijiriaAdamu ni titi di asiko yii, ijoba Naijiria ko tii be orisun wahala yii wo ki won le mọ ohun to kan ni sise.
Bulama Bukarti to je akosemose lati Tony Blair ni o yẹ́ ki ijoba fi kun ise awon omo ogyun ni kete ti won ba ti gbiyanju lati yi ero awon alakatakiti Boko Haram pada tan bo se sele ni Syria fun awon to kuro ni Islamic state Group.
2) Bawo ni Boko Haram se n ri ọmọ́ ogun labẹ́ ara wọn?
Isẹ́ ati òsì to n fi ebi pa awon eeyan ni ẹkun yii n jẹ́ ko rorun fun awon eeyan lati dara pọ̀ mọ́ awon Boko Haram.
Lati odun 2014 titi di 2021 ni Boko Haram ti n sose ni NAijiria ti wọ́n si n ni awon to n tẹ̀lẹ́ on titi di asiko yii.
ọ̀pọ̀ n darapo mọ́ won nitori ki ebi ma pa won ku ati nitori òsì to n ba wan finra.
Ogbeni Bukarti salaye lori bi spọ̀ ọ̀dọ́ se n darapọ̀ mọ́ Boko Haram.
Koda, Gomina Babangida Zulum to n tuko ipinle Borno so fun BBC pe awon eeyan ilu nibe n darapo mọ́ Boko Haram to el won kuro nile won to so won di asatipo.
3) Aisi ohun eelo ijagun to peye:
Ogbeni Adamu tun salaye fun BBC pe ko si ohun eelo ijagun to peye lati fi koju Boko Haram ni Naijiria.
O ni aown ohun eelo ijagun ti awon omo ogun NAijiria ri gab lọ́wọ́ awon Boko Haram fihan pe Boko Haram ni ohun ija ogun to dara ju ti omo ogun ill NAijria lo.
Die lara ohun eelo ti won fihan ni 120th Battalion in Goniri, ni ipinle Yobe fihan pe kekere kọ́ nike Ramo ni ọ̀rọ̀ ohun eelo ogun Boko Haram .
4) Iwa Ajebanu awon kan ninu jija ogun Boko Haram
Iwa ajebanu awon kan tun je koko pataki kan ti ko je ki ogun Boko Haram ko tete pari.
Won fesun kan pe opolopo owo iyebiye nijoba n na lori ogun Boko Haram yii.
Ogbeni Yalwa ni awon kan ti so ogun Boko Haram di ogun Olorun ni eyi ti ko ri bee rara nitori pe eeyan ni awon Boko Haram.
O ni awon kan ti so ogun naa di ona taije fun ona lati maa ri owo na.
Aare Buhari ati Goodluck Jonathan ti ni ariwisi ni opo igba seyin lori agbara ofin nkan eelo ogun ile America ni lilo
Lodun 2018 nikan ni Aare Donald Trump sun ipese awon nkan ogun miran ni pipese fun Naijiria ni eyi ti Adamu gbagbo pe o ye ko ran omo ogun Naijiria lowo ti won ba loo daadaa
Sugbon orisirisi esun lo ti jade lori bi won se n na owo tijoba pese fun jija ogun Boko Haram
5) Eto aarin awon omo ogun NAijiria ko dara tó:
Ogbeni Bukarti salaye fun BBC pe awon omo goun Boko Haram ti mo ona amuse ise akanse awon omo ogun Naijiria daadaa,
Koda, won mo igbese awon omo ogun ati igba ti won n kolu won, lati bi odun kan seyin ni awon omo goun NAijria ti n ko awon omo ogun won kuro nilẹ̀ bayii.
Awon onimo ni igbese yii si ti so opo di asatipo ti won ko le duro si ilu won mo.
Ogbeni Adamu ni O buru jai
6) Ogun Boko Haram kii se ogun enikan:
Awon alase fi ikede sita losu keta pe awon Boko Haram tun ti wo awon ibi kan lati koju ija sawon to n gbe nibe
Osu kejila ni adari ogun ni ija Boko Haram le t ogun odun
Bakan naa ni Tukur Buratai ni laisi ifowosowopo awon omo ogun ati ti awon ara ilu Naijiria ko el bori ogun Boko Haram
Fun idi eyi, o digba ti ara ilu ati omo goun ba jo ja ija naa ni won yoo to bori ogun Boko Haram.














