Ìrànwọ̀ Gẹ̀ẹ́sì: Bùhárí se káre lóríi ìrànwọ́ £1m

Ààrẹ orílẹ̀èdè Nàíjíríà, Mùhámádù Bùhárí pẹ̀lú olóòtú ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Theresa May duro niwaju ile ijọba ilẹ Gẹẹsi

Oríṣun àwòrán, Nigeria presidency

Àkọlé àwòrán, Bí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì bá jáde kúrò lájọ Yúrópù, àjọṣepọ̀ okòòwò àti ọ̀rọ̀ ajé láàárín orílẹ̀èdè méjèèjì gbópọn síi.

Ààrẹ orílẹ̀èdè Nàíjíríà, Mùhámádù Bùhárí pẹ̀lú olóòtú ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Theresa May, ti pinnu láti jùmọ tẹ̀síwájú nínú lìlépa ìfìdímúlẹ̀ ìṣèjọba àwarawa, tó fi mọ́ gbígbógun ti ìwà ìbàjẹ́ àti ṣíṣí ilẹ̀kùn ètò ẹ̀kọ́ sílẹ̀ gbayawu fún aráàlú.

Ilé ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́s,ì tó wà ni ojúlé kẹwàá, òpópónà Downing ní ìlú London ni ìpàdé náà ti wáyé.

Bùhárí àti Arábìnrin May tún fohùn ṣọ̀kan lórí àjọṣepọ̀ nípa ọ̀rọ̀ iléeṣẹ́ ológun pẹ̀lú ètò ààbò, pàápàá jùlọ lórí ọ̀rọ̀ wíwa ọwọ́ gulegule Boko haram àti ẹgbẹ́ agbésùmọ̀mí Islamic State West Africa bọlẹ̀.

Ààrẹ orílẹ̀èdè Nàíjíríà, Mùhámádù Bùhárí pẹ̀lú olóòtú ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Theresa May n joko sọrọ

Oríṣun àwòrán, Nigeria presidency

Àkọlé àwòrán, Theresa May kọminú lórí bí àwọn ọmọ obìnrin ṣe ń fara kó ááṣá wàhálà ọ̀rọ̀ ààbò tó mẹ́hẹ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà

Agbẹnusọ fún Ilé ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tún ṣàlàyé pé, àwọn olórí ìjọba méjèèjì tún jíròrò lórí ètò ìrànlọ́wọ́ owó oní mílíọ̀nù kan pọ́ùn owó ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, láti ra àwọn nǹkan ijàgun adójú tàdó olóró, fún ìdáàbòbò àwọn ológun àti aráàlú lórílẹ̀èdè Nàìjíríà.

"Olóòtú ìjọba kò ṣàì fi àìdùnnú rẹ̀ hàn pẹ̀lú bí àwọn ọmọ obìnrin ṣe ń fara kó ááṣá wàhálà ọ̀rọ̀ ààbò tó mẹ́hẹ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Olóòtú ìjọba, Theresa May tún kan sáárá sí Ààrẹ Mùhámmádù Bùhárí, lórí àtúntò okòòwò àti ọ̀rọ̀ ajé lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, tó sì tún sọọ́ di mímọ̀ pé, jíjáde tí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fẹ ́jáde kúrò lájọ orílẹ̀èdè Yúrópù, yóò túbọ̀ mú kí okùn àjọṣepọ̀ okòòwò àti ọ̀rọ̀ ajé láàárín orílẹ̀èdè méjèèjì gbópọn síi."

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ Ààrẹ Mùhámádù Bùhárí lu olóòtú ìjọba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ́gọ ẹnu, fún àtìlẹ́yìn rẹ̀ lóríi gbígbógunti ìdúnkùkùlajà Boko haram.