Trump kò yẹ láti jẹ́ ààrẹ- Adarí FBI tẹ́lẹ̀rí

James Comey àti Donald Trump

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Comey ní ẹnití wọ́n bá pè ní ààrẹ gbọdọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn èèyàn

Olùdarí àgbà tẹ́lẹ̀ fún iléeṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ní orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà (FBI), James Comey ní, Donald Trump kò ní ìwà tó yẹ láti jẹ́ ààrẹ nítorí ó máa ń ṣe àwọn obìnrin bíi ekìrí ẹran.

Ọ̀gbẹ́ni Comey ṣàlàyé ọ̀rọ̀ yìí nínú ètò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àkọ́kọ́ kan tó se lórí tẹlifísàn lẹ́yìn tí Trump yọọ́ nípò, tí Trump sì tún nàka àléébù síi pé òpùrọ́ ni Comey nínú ètò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan.

Comey ní Trump jẹ́ òpùrọ́ àti ẹni tó máa yí ìdájọ́ po pẹ̀lú àfikún pé òun kò fara mọ́ọ pé Trump kò pé tó ní ọpọlọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Èmi kò gbà pé Trump kò ní ìlera tó dápé láti jẹ ààrẹ, sùgbọ́n kò ní àwọn àbùdá tó yẹ gẹ́gẹ́ bíi ààrẹ Amẹ́ríkà."

Ẹnití yóò jẹ ààrẹ Amẹ́ríkà gbọdọ̀ tẹ̀lé ìlànà ìdúróṣinṣin

Ó ní ẹnití wọ́n bá pè ní ààrẹ gbọdọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn èèyàn, tí yóò sì máa tẹ̀lé àwọn ìlànà tó se iyebíye fún ìdúró sinsin orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà.