Kaduna strike : NLC fòpin sí ìyanṣẹ́lódì Ọlọ́jọ́ mẹ́rin ní Kaduna

Kaduna strike : NLC fòpin sí ìyanṣẹ́lódì Ọlọ́jọ́ mẹ́rin ní Kaduna

Oríṣun àwòrán, El-rufai

Lale oni ojoru yìí ni egbe òṣìṣẹ́ ni Ipinle Kaduna fòpin sí ìyanṣẹ̀lódì tí wọ́n gin lè láti ọjọ́ merin seyinComrade Ayuba Magaji lọ fidie múlè fún BBC pé wọn tí wagbo dekun fún ìyanṣẹ́lódì náà. Wọn fòpin sí iyansẹ́lodi náà lẹ́yìn tí mínísítà ọ̀rọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ fún Naijiria, Chris Ngige dá sii

O ni kété tí ilè bá mọ lọ́la ojobo náà ni wọn yóò pàdé mínísítà fún ọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́ Ngige Chris ni AbujaComrade Ayuba ni Abuja ni wọ́n yóò ti yanjú gbogbo ọ̀rọ̀ to kú lola

Àwọn nọ́ọ̀sí àti àwọn òṣìṣẹ́ mííràn tó darapọ̀ mọ́ ìyásẹ́lódì le gbà ìwé ìdádúró

Kaduna State: Àwọn nọ́ọ̀sí àti àwọn òṣìṣẹ́ mííràn tó darapọ̀ mọ́ ìyásẹ́lódì le gbà ìwé ìdádúró

Oríṣun àwòrán, El-Rufai

Àwọn aláṣẹ ìjọba ni ìpínlẹ̀ Kaduna ti pàá láṣẹ fún ilé iṣẹ́ ètò ìlèra láti fún gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ nọ́ọ̀sì ilé iṣẹ́ náà ni ìwé lọ rọ́ọkún nílé, pàápàá jùlọ àwọn tó wà ni ipele kẹrinlá sí ìṣàlẹ̀ ti wọ́n sì dàrapọ̀ mọ́ ìfẹ̀hónúhàn tó ń lọ lọ́wọ́.

Oní ló pé ọjọ́ mẹ́ji ti ìyànṣẹ́lódì náà ti bẹ̀rẹ̀.

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ Nàìjíríà pè fún ìyànṣẹ́lódí lẹ́yìn ti gómìnà ìpińlẹ̀ náà Nasir El-Rufai yọ àwọn òṣìṣẹ́ ẹgbẹ̀rún méje níṣẹ́ láìrò tẹ́lẹ̀. Wọ́n gùnlé ìyásẹ́lódì ìkìlọ̀ ọlọ́jọ́ márùn, èyí sì tí dí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nnkan lọ́wọ́ tó fi mọ́ ọ̀rọ̀ iná mọ̀nàmọ́nà, ọ̀kọ̀ ìrìnà àti ilé ìwòsàn.

Nínú àtẹjáde kan ti agbẹ̀núsọ gọmìnà ìpińlẹ̀ Kaduna Muyiwa Adekeye fọwọ sí ló ti sàlàyé pé pé ìjọba ko ni wẹyin wo lórí dídá àwọn òṣìṣk náà dúró nítorí pé gómìnà ni ìgbàgba pé nnkan to tọnà láti ṣe ni lati ran ipinlẹ naa lọ́wọ́ nipa didaabo bo owo ilu.

Bákan náà lo fi kun pé gbogbo òṣìṣẹ́ Fasiti Kaduna to ba dan iyanṣẹlodi naa wo laṣa ti ko lọ si ibiṣẹ ni oun yọọ niṣẹ, to fi mọ gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ile iṣẹ ijọba gbogbo, ki wọ́n si maa gbe iwe ti wọn fi n kọ orukọ ẹni to ba wa si ibiṣẹ wa si ile ijọba lojoojumọ.

BBC gbiyanju lati ba adari ẹgbẹ NLC sọrọ láti mọ nnkan ti wọn yoo ṣe nitori ọrọ ti gọmina sọ yìí sùgbọn wọn ko gbe aago.

Sanni Ashir to jé olùgbe ipinlẹ Kaduna to ba BBC sọrọ slaye pe ti wọ́n ba le awọn eniyan yii lẹnu iṣẹ ọrọ naa yoo tun buru si ni paapaa julọ lẹka eto ilera.

"Ni Bayii ọpọ ile iwosan lo ti wa ni titi pa, ti awọn eniyan si n gbadura ki wọn pa da si ẹnu iṣẹ ti gomina ba tun wa yọ wọn niṣẹ iṣoro naa yoo pọ si ni. Adura wa ni pe kii gbogbo wahala toi wa nilẹ yii pari kia"

Ọjọ kẹta ree ti ko si ina to si ti pe ọjọ meji ti ko si ile epo kankan to n ta epo, eyi si ti mu ki ọpọ awọn ara ilu ko si inu wahala gidi.