Katsina kidnap: Àwọn ajínigbé gbé Adájọ lọ nílé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Eemọ lukutu pẹbẹ, ọmọ loyun tan, iya gbe e sita.
Awọn janduku ajinigbe ti gbe Adajọ kan lọ nílé ẹjọ nipinlẹ Katsina.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Katsina, SP Gambo Isah lo fidi ọrọ naa mulẹ fawọn akọroyin.
SP Isa ni iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ ni bíi ago mẹta ọsan ninu kootu to wa ni ijọba ibilẹ Safana.
- Lizzy Anjorin sọ̀rọ̀ sókè lórí obìnrin tó ń ba fa sùrútù torí ọkọ rẹ̀
- Ẹ̀yin tí ẹ sọ pé irọ ni mo ń pa bayii ni yoo ri fún yín
- Wo ojú àwọn ọmọ Yahoo tí EFFC lọ́ mú l‘Osogbo, tí ọ̀rọ̀ fi dariwo
- Nǹkan dé o! Àwọn àgbébọn tún yìnbọn pa ọlọ́pàá méjì lẹ́nu iṣẹ́, wọ́n dáná sun àgọ́ ọlọ́pàá
- Nàìjíríà ti rí €4.2m gbà padà nínú owó tí James Ibori gbé- Malami
- Wo ìdí mẹ́fà tí ìjóba kò se tíì kápá Boko Haram
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni oun ko le sọ idi ti Adajọ naa fi lọ sí ileẹjọ lai sí ẹṣọ kankan pẹlu rẹ.
Isah fikun ọrọ rẹ pe gbogbo ileẹjọ lo wa ni titi pa bayii nitori iyanṣẹlodi awọn oṣiṣẹ eto idajọ.
O ṣalaye pe adajọ naa lọ sí ileẹjọ lati mu nkan nibẹ ni niwọn igba ti awọn oṣiṣẹ ẹka eto idajọ n yanṣẹ lodi lọwọ lọwọ.
"O yẹ ki adajọ yii beere fun agbofinro ti yoo tẹ le e lọ síbẹ pẹlu iṣoro eto abo to mẹhẹ ni Naijiria bayii," agbẹnusọ ọlọpaa lo sọ bẹẹ.
O ni ileeṣẹ ti bẹrẹ iwadii lati mọ ohun tó mu ki adajọ naa da lọ sile ẹjọ lai mu agbofinro lẹyin.














