Adewale Elesho: Ìdí rèé tí ǹ kò ṣe sí nínú eré àgbéléwò mọ́

Adewale Elesho Adeoye

Oríṣun àwòrán, Adewale Elesho Adeoye

Adewale Adeoye, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Adewale Elesho jẹ ọkan lara awọn agba ọjẹ ninu iṣẹ tiata Yoruba ti irawọ rẹ tan kaakiri agbaye.

Amọ ọpọ awọn eeyan lo n ṣakiyesi pe o ti tọ ọjọ mẹta ti awọn ti foju ganni rẹ kẹyin ninu ere.

Ninu ifọrọwerọ kan pẹlu awọn akọroyin, agba oṣere naa ṣalaye bi ọrọ ọhun ṣe jẹ.

O ni "Ọpọ eeyan lo ti n bere ibere yii lọwọ mi lẹnu ọjọ mẹta yii."

"Ti ẹ ba ṣakiyesi, ẹ oo ri pe ọpọ awọn ti a jọ jẹ sawawu ni ẹ ko fi bẹẹ ri ninu fiimu mọ, idi ni pe ọkan wa ko bale lori irufẹ awọn itan ti awọn ọmọ aye ode oni n kọ jade."

Àkọlé fídíò, Abiodun Duro Ladiipo, Moremi: Ǹ kò pé '40' ti Bàbá fi papòdà ṣùgbọ́n mo kọ̀ láti 'remarry'

"Koda ninu ile emi funra mi gan, mi o le wo ọpọ ninu awọn ere ti wọn n gbe jade mọ nitori ko ni ọgbọn kankan ninu."

"Pupọ ninu awọn oṣerebinrin ni kii wọ aṣọ to bojumu, amọ wọn ko gbọrọ si wa lẹnu nitori pe awa kọ ni baba wọn."

Elesho tẹsiwaju pe "Ẹ ko le maa reti ki ẹni ti awọn obi rẹ gan ko gbadun lati maa wu iwa ọmọluabi."

Agba oṣere apanilẹrin naa ṣo siwaju si pe bi awọn kọlọrọsi kan ṣe maa n ṣe ẹda awo sinima tun n ṣakoba fun ere tiata ni Naijiria.

Àkọlé fídíò, Ogun King Killing: Baálẹ̀ Agodo ní ààrin Ẹ̀gẹ́ ni òun sùn mọ́jú, tí òun kò sì rí aya, ọmọ

O ni "Ọpọ ninu wa lo maa ya owo ni banki lati fi ya fiimu, ṣugbọn lẹyinorẹyin, a kii jere lori rẹ."

"Akoko kan wa ti mo ka ẹnikan to ta ẹda fiimu ti mo gbe jade, amọ niṣe lo tun n halẹ mọ mi pe oun yoo fi oju mi ri mabo ti mo ba fi ọlọpaa gbe oun."

"A nilo ki ijọba ba wa da si ọrọ naa."

Ta ni Adewale Elesho?

Adewale Elesho jẹ ọkan lara awọn oṣere tiata Yoruba to dantọ ti irawọ rẹ si kan kaakiri agbaye.

Wọn bii lọjọ kẹwaa, ọsu Kinni, ọdun 1959 niluu Ikirun, ni ipinlẹ osun.

Ounnni Aarẹ ẹgbẹ oṣere tiata, igun ANTP.

Irawọ rẹ bẹrẹ si n tan lẹyin to kopa ninu ere "Taxi Driver" ti wọn gbe jade lọdun 1983.

Lara awọn tiata mii ti Elesho ti kopa to milẹ titi ni "Alaaru, Arike Osha, Oga Kan, Farugbotayin," ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Àkọlé fídíò, Ikere Ekiti: Olúkẹ̀ẹ́rẹ́ àti Ògògà tako ara wọn lórí ẹni tíí ṣe aláṣẹ ilú Ikere