2023 Election: Seyi Makinde ní ẹni tí ọjọ́ orí rẹ̀ bá ti ju àádọ́rin ọdún lọ, kò yẹ ní Ààrẹ Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook
Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde tí ṣèkìlọ̀ fún àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà láti má dìbò fún ẹni tí ọjọ́ orí rẹ̀ bá ti ju àádọ́rin ọdún lọ gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ lọ́dún 2023.
Makinde tó ṣíṣọ lójú eégún ọ̀rọ̀ lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun ní ìlú Ibadan, ìpínlẹ̀ Oyo ní dípò yíyan awọn bàbabàbá gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ, ó sàn láti wá ọ̀dọ́ langba láti tukọ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lọ́dún 2023.
Makinde sọ̀rọ̀ yìí níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún márùndínláàdọ́rin Ààrẹ ẹgbẹ́ ọmọlẹ́yìn Kírísítẹ́ẹ̀nì (CAN), Ẹni ọ̀wọ̀ Samson Ayokunle àti ìfilọ́lẹ̀ ilé ìjọ.
- "Á lọ yíká gbogbo ilẹ̀ Yorùbá láti bèèrè fún ìdáǹdè Sunday Igboho"
- Omijé lójú, ọ̀rọ̀ ìdárò àti orin èpè ní ọ̀dọ́ Eruwa fi dárò ikú bí Timothy Adegoke ti yóò wọ ilẹ̀ sùn lónìí
- Òjòwú-bìnrin fi ẹ̀rọ ìlọṣọ gbígbónà jó ọkọ ní abẹ́ àti ojú láti ojú oorun, ó sì gba ibẹ̀ kú
- Dókítà àti Nọ́ọ̀sì di atọrọjẹ torí àjẹsílẹ̀ owọ oṣù mẹ́jọ
- Fathia Balogun kéde aṣọ ẹbí ₦150,000 àti ₦120,000 fún ọjọ́ ìbí rẹ̀
- Àlàyé rèé lórí àìsàn tó ṣe mi fọ́dún mẹ́jọ tí mo fi rù kan eegun - Ogogo
- Osun la fẹ́ kí ìgbẹ́jọ́ ikú Timothy Adegoke ti wáyé, kìí ṣe Abuja - Mọ̀lẹ́bí yarí
- Wo ohun tí ìjọba Oyo ṣe fún ẹni tí ọlọ́pàá SARS lù fọ́ lójú lẹ́yìn àbọ̀ ìgbìmọ̀ EndSARS
Ki lo de ti Makinde se tako iyansipo awọn eeyan to le ni aadọrin ọdun bii aarẹ?
Gomina Seyi Makinde, tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, ti wá rọ àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí láti la ojú wọn sílẹ̀ dáadáa lọ́dún 2023 lórí ẹni tí wọn ó yàn gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ.
Ó ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà nílò ẹni tí ó sán-an-gun láti ṣe Ààrẹ, fún ìdí èyí kí àwọn ọmọ Nàìjíríà dìbò fún ọ̀dọ́.
"A ti ri àwọn àgbàlagbà tí ọjọ́ orí wọn ti tó ọdún 75 sí 78 tí wọ́n ṣì ń gbèrò láti ṣe Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà."
"A ti wà lásìkò ètò òṣèlú, ohun tí mo lè sọ ni pé a nílò láti kíyèsára lórí àwọn tí a ó yàn sípò, kí a yan àwọn tí ó ní eegun láti sin ìlú."
Ẹ wo awọn oludije to ti le ni aadọrin ọdun to fẹ dije fun ipo aarẹ ni Naijiria:
Gómìnà ìpínlẹ̀ Eko tẹ́lẹ̀ rí, Bola Ahmed Tinubu ti fi èròńgbà rẹ̀ hàn láti díje sípò Ààrẹ lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Ọpọ eeyan lo si n ni Tinubu ti le ni ẹni aadọrin ọdun, ta ba wo ipo ti ara rẹ wa, to si ti ni awọn ọmọ-ọmọ nile aye.
Amọ gẹgẹ bi akọsilẹ ti Tinubu kede, o ni ẹni ọdun mejidinniaadọrin si ni oun bayii.
Bákan náà ni igbákejì Ààrẹ orílẹ̀ èdè yìí tẹ́lẹ̀ rí, Abubakar Atiku náà ti kéde èròńgbà rẹ̀ láti díje sípò Ààrẹ lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.
Amọ akọsilẹ jọ ori tiẹ fihan pe o ti le ni ẹni aadọrin ọdun, to si ti ni ọpọ ọmọ-ọmọ.


















