Taiwo Hassan Ogogo: Àwọn èèyàn kan ní Cocaine ló tú sínú mi, àwọn míì ní mo ní HIV ni

Taiwo Hassan Ogogo

Oríṣun àwòrán, ogogotaiwohassan/Instagram

Ẹda kii wa laye ko ma ri amiwo nitori ẹni ti yoo ga ẹsẹ rẹ yoo tiirin.

Bẹẹ ni ọrọ ri fun osere tiata kan, Taiwo Hassan Ogogo lasiko kan to ri amiwo Ọba oke, to si la akoko aisan kan kọja.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ń wádìí kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí gbajúgbajà òṣèré naa lati mọ idi tí ó fi rù kan eegun láàárín ìgbà kan.

Àwọn kan tilẹ̀ ń gbé ìròyìn kiri láàárín ìgbà náà pé egbògi olóró Cocaine ló tú sí i nínú.

Bẹ́ẹ̀ ni àwọn mìíràn ní ààrùn kòógbògùn HIV ló kó látàrí bí àwọn obìnrin ṣe máa ń rọgba ká àwọn oníṣẹ́ tíátà ká.

Ki lo mu Ogogo to fi se aarẹ, to si ru kan egungun:

Nígbà tó n sọ̀rọ̀ loju opo City People TV lori ayelujara YouTube nipa àárẹ̀ tó da dùbúlẹ̀ fún ọdún mẹ́jọ gbáko, Ogogo tú pẹrẹpẹ́rẹ̀ ọ̀rọ̀ lórí bí ọgbẹ́ inú ṣe lu ìfun rẹ̀ láìmọ̀ àti bí ó ṣe ṣokùnfà kí ó máa rù han gogo.

Ogogo ní lọ́dún 2004 ni àárẹ̀ ọ̀hún bẹ̀rẹ̀ gan títí di ọdún 2012 amọ ọdún 2013 ni ara òun ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní bọ̀ sípò.

"Mo kàn máa ń gbọ́ nípa ọgbẹ́ inú ni, mi ò mọ bó ṣe máa ń ṣe ènìyàn. Mo ti múra fún iṣẹ́ tí mo ní ní òwúrọ̀ ọjọ́ náà ní Ipaja, iṣẹ́ Arakangudu ni."

Àkọlé fídíò, Murphy Afolabi: Kò dùn mí tí wọn bá ṣe yẹ̀yẹ́ mi torí mò fi sí pe ṣí, èdè Osogbo ìlú mi ni

Bi aisan ọgbẹ inu se bẹrẹ pẹlu Ogogo ree:

Ogogo ni ọjọ́ kẹrin nínú oṣù Ramadan ni ọjọ́ náà nigba ti oun bẹrẹ si kẹẹfin aisan naa.

"Mi ò kí sábà jẹ sààrì, ìyẹn oúnjẹ tí àwọn Mùsùlùmí máa ń jẹ ní ìdájí tí wọ́n bá ń gbàwẹ̀, dandan sì ni ààwẹ̀ nínu ìdílé mi.

Nígbà tí à ń lọ síbi iṣẹ́ ní òwúrọ̀ ọjọ́ náà, kí a tó dé Ikeja, mo ṣàkíyèsí pé ara mi ń ṣe bákan bákan, inú bẹ̀rẹ̀ sí ní dùn mí, èmi ni mo sì ń wa ọkọ̀.

Shina Bankole máa ń wà pẹ̀lú mi ní gbogbo ìgbà, ó ń bi mí pé kí ló ṣe mí ṣùgbọ́n mi ò rí àlàyé kankan ṣe fun. Mo ṣá gbìyànjú láti wa ọkọ̀ dé ibi iṣẹ́ náà."

Ogogo tẹsiwaju pe "ní kété tí a dé "location", nígbà tí Remi Surutu ṣàkíyèsí bí mo ṣe ń ṣe, nítorí mi ò rí iṣẹ́ kankan ṣe, ó ní "ẹ̀gbọ́n mi ẹ dúró, ṣé kìí ṣe Ulcer ni nǹkan tó ń ṣeyín yìí"

Ó ní kí Shina lọ ra omi àti mílìkì fún mi, kí n sì lọ ri dókítà lẹ́yìn náà nítorí ó dá òun lójú pé ọgbẹ́ inú ló ń ṣe mí.

Bawo ni Ogogo ti se nigba to mọ aisan to n see:

Taiwo Hassan Ogogo ni aya oun ja puọ nigba oun gbọ o seese ko jẹ ọgbẹ inu lo n se oun.

O ni bi wọn se tu miliki naa sinu omi, ti oun gbe mu, laarin isẹju diẹ, ara oun si walẹ, ni wọn ba ni ki oun lọ ri dokita.

Ó le débi wí pé ọ̀pọ̀ àwọn tí a jọ ń ṣiṣẹ́ gan kìí bà mí lọ́wọ́ mọ́, mo fi Ọlọ́hun ṣẹ̀rí gbogbo wọn sá fún mi ni.

Ìyàwó kejì tí mo fẹ́ jẹ́ ẹni tí a ti mọ ara wa fún ọdún méjì, lọ́jọ́ tí mo pàdé rẹ̀ kò dá mi mọ̀ mọ́, èmi ni mo pè é kí, ohùn ló fi dá mi mọ̀.

Ó dúró tìmí lásìkò náà àti pé Ọlọ́hun ti kọ́ pé a ó fẹ́ra ni. Ọmọ méjì ló ti bí fún mi. Ìyálé mi gba kádàrá ló nítorí ó mọ̀ pé mi ò kìí ṣe ṣìná.

A nílò láti máa ṣọ́ra gidi nítorí ènìyàn burú gan an ni.

Àkọlé fídíò, Femi Branch: Gbogbo dúkìá mi àti ti ìyá mi ni mo tà láti tọ́jú ẹsẹ̀ mi fún ọdún méjì

Mo pa sinima ti mo n ya ti, lai le pari rẹ tori aisan ọgbẹ inu - Ogogo

Nigba to n sọrọ lori ipa nla ti aisan naa ni lori isẹ oun, Ogogo ni isọri meje ni oun tiraka ya ninu isọri mọkanla ti wọn fun oun lati se ninu sinima ti awọn n ya lọwọ.

O ni oun lọ ri dokita lootọ to si se ara ara fun oun, bakan naa lo ni o fi oniruuru egbo to wa ninu oun han oun eyi to ya oun lẹnu pe se inu oun ni awọn egbo yii wa lootọ.

"Ti mo ba jẹ irẹsi horo kan, maa maa bi ni, ma si maa pọ ẹjẹ. Bi igba ti aye fẹ parẹ fun mi ni.

Onigbagbọ ati Musulumi pariwo, mo mọ pe Oso ati Ajẹ naa sọ fun Ọlọrun Ọba pe ko da ẹmi mi si - Ogogo

Ogogo tẹsiwaju pe "Fun odidi osu meje ni mo fi wa ni ori ijoko, mo wa ni ki n jade lọjọ kan, ki n lọ gẹrun, se ni atẹgun n gbe mi rin.

Mo ri ara mi ninu gilaasi nile agẹrun, mo si bu sẹkun pe se bi mo se da ree.

Mo pẹ lẹnu rẹ, amọ ki ni aye ko sọ tan, wọn ni mo gbe Cocaine ni, awọn mii ni mo ko kokoro HIV ni tori obinrin ti pọ ju.

Mo lọ kaakiri, ko si ohun ti n ko se, bi awọn Onigbagbọ se n pariwo, ni awọn Musulumi n pariwo amọ mo mọ pe Oso ati Ajẹ naa sọ fun Ọlọrun ọba pe ko da ẹmi mi si."

Àkọlé fídíò, yyyy

"Obinrin kan mu orukọ mi lọ sọdọ Wolii kan lati gbadura fun mi fun ọjọ meje pe ki ara mi le ya"

Ogogo tẹsiwaju pe ni ọjọ kan, wolii kan pe oun ni ori ago, to si n sadura fun oun pe ki oun maa se ami.

O ni wolii naa ni obinrin kan lo mu orukọ oun wa si sọọsi oun pe ki oun gbadura fun oun ki ara oun le ya.

"Wolii naa ni ọjọ keje ti awọn ti n gbadura fun mi ree, ti awọn si pe mi ki n le se amin si awọn adura naa.

Nigba ti ara mi ya tan, mo lọ si London, mo si pade ọkunrin kan nile ounjẹ, ẹni to juwe ara rẹ bii wolii naa."

Ogogo wa salaye pe oun ni iyawo to jẹ Kristiẹni, ti oun si gbalaaye lati maa se ẹsin rẹ nitori oun ri oore lati ara kristiẹni.

Amọ o fikun pe ẹsin Islam ni awọn ọmọ oun n se.

Ta ni Taiwo Hassan Ogogo?

Ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù kẹwàá, ọdún 1959 ni wọn bí Ogogo ní Ilaro, ìpínlẹ̀ Ogun.

Ó lọ ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ̀rẹ̀ Christ Church School, Ilaro, kí ó tó tẹ̀síwájú lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Technical láti kọ́ nípa bí a ṣe ń tún ọkọ̀ ṣe ìyẹn Mechanic.

Ogogo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ tíátà lọ́dún 1981 lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ omi. Ọdún mẹ́tàlá ló fi ṣiṣẹ́ ìjọba ní ilé iṣẹ́ omi yìí kí ó tó kọ̀wé fiṣẹ́ silẹ̀ lọ́dún 1994 láti gbájúmọ́ iṣẹ́ tíátà.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló fẹ́ràn Ogogo fún ìwà pẹ̀lẹ́ tó máa ń wù nínú eré.

Ìyàwó méjì ni ó ní, tí Ọlọ́hun sì fi àwọn ọmọ jí ǹ kí rẹ̀.

Ó ti kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré tó lé ní àádọ́ta bí i Iru ẹṣin, owó ẹ̀jẹ̀, àti bẹ́ẹ̀ lọ, ti o si ti gba ami ẹyẹ ninu isẹ tiata lorisirisi.

Àkọlé fídíò, Ogun King Killing: Baálẹ̀ Agodo ní ààrin Ẹ̀gẹ́ ni òun sùn mọ́jú, tí òun kò sì rí aya, ọmọ