Toyin Abraham: Èmi kọ́ ni mò ń gbọ́ bùkátà ilé wa - Toyin Abraham fọhùn

Oríṣun àwòrán, Toyin Abraham
Gbajúgbajà òṣèré tíátà, Kolawole Ajewole tó tún jẹ́ ọkọ gbajumọ òṣèré tíátà Toyin Abraham ti sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ fún àwọn tó ń fi ori àṣeyọrí rẹ̀ sọ ìyàwó rẹ̀ lórí ẹ̀rọ ayélujára.
Kolawole Ajewole tó ṣe ọjọ́ ìbí rẹ̀ ní ọjọ́ Ajé tó kọjá yìí ra ọkọ ayọ́kẹ́lẹ́ fún ara rẹ̀ láti fi ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí ṣùgbọ́n tí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ń sọ pé ìyàwó rẹ̀ ló rà á fún un. Nígbà tí ó ń fèsì sí ọ̀rọ̀ ọ̀hún lójú òpó Instagram rẹ̀, Kolawole ni ọ̀pọ̀ èèyàn ni yóò pa ara wọn lórí ọ̀rọ̀ òun nítorí òun ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mú ẹyẹ bọ̀ lápò ni. Ó ní "ní ọdún yìí àwọn aláburú àti aláìda ènìyàn yóò kú lórí ọ̀rọ̀ mi nítorí ẹ ò tí rí nǹkan kan, Ọlọ́run mi ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́".Ẹ̀wẹ̀, ìyàwó rẹ̀ náà Toyin Abraham ti pariwo sita pe oun kọ loun n gbọ bukata ọkọ oun, Kọlawole Ajeyẹmi.
Laipẹ yii ni Toyin ṣe ayẹyẹ ọjọọbi ọkọ rẹ, Ọjọọbi yii lo gbe Toyin lo sori ẹrọ ayelujara lati sọrọ to dun nipa ọkọ rẹ. Gbogbo ohun ti ọkunrin naa ṣe lasiko ọjọọbi yii, wọn ni Toyin iyawo rẹ lo ṣe e fun.Ṣugbọn nigba tawọn eeyan maa dahun sohun ti Toyin kọ nipa ọkọ rẹ, wọn ni Toyin lowo ju ọkọ rẹ lọ, ati pe oun lo n gbọ bukata ọkọ rẹ ati gbogbo ile.Ọrọ yii bi Toyin ninu lo ba fabinu yọ, o ni ọpọ eeyan maa n lero pe gbogbo awọn tirawọ wọn ba tan ni wọn maa n lowo bii ṣekere, o ni eyi ko ri bẹẹ, tori ọkọ oun n ṣiṣẹ karakara, bẹẹ lo si lowo tiẹ lọwọ to fi n gbọ bukata oun atawọn ọmọ rẹ.
Wo bí ọlọ́pàá ṣe rí òkú ọmọ ọdún márùn-ún tí wọ́n ní olùkọ́ rẹ̀ jígbé Mọto tuntun bọginni ti Kọla ṣẹṣẹ ra ti Toyin gbe sori ẹrọ ayelujara lo si fa awuyewuye yii, tawọn eeyan fi n sọrọ pe Toyin lo ra mọto fọkọ rẹ, obinrin oṣere naa sọ pe, ọkọ oun lo fowo ara rẹ ra mọto fun ra rẹ.Bakan naa lọmọbinrin naa tun gbe awọn eeyan ti wọn n tako ọkọ rẹ ṣepe, o ni, gbogbo awọn ti ko ba fẹ koun rimu mi lọdun, airoju airaye ni ki Ọlọrun gbe le wọn lọwọ.















