Buhari's relationship with Kaduna: Kí ni ìbáṣepọ̀ Ààrẹ Buhari pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Kaduna

Oríṣun àwòrán, President Muhammadu Buhari
Ààrẹ Muhammadu Buhari tó wà ní ìpínlẹ̀ Kaduna lọ́wọ́ lọ́wọ́ fún àbẹ̀wò ọlọ́jọ́ méjì, jẹ́ ọmọ bibi ìlú Daura ní ìpínlẹ̀ Katsina ṣùgbọ́n tó ní ìbáṣepọ̀ tó pọ̀ pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Kaduna.
Ní ìlú Daura ni Ààrẹ ti lọ ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀, kí ó tó tẹ̀síwájú lọ sí ilé ẹ̀kọ́ girama ní Katsina.
Ní kété tí Ààrẹ parí ìwé mẹ́wàá ni ìrìnàjò rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Kaduna bẹ̀rẹ̀.
Ikọ̀ ìròyìn BBC ṣàgbéyẹ̀wò ìbáṣepọ̀ Ààrẹ Buhari pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Kaduna àti ipa tó ní nínú ìgbésí ayé rẹ̀ àti àwọn ẹbí rẹ̀.
Ìpínlẹ̀ Kaduna ló ti lo ọ̀pọ̀ ìgbésí ayé rẹ̀
Ní ìpínlẹ̀ Kaduna ni Ààrẹ Muhammadu Buhari ti lo ọ̀pọ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ kódà kó tó di Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Kaduna ló ń gbé pẹ̀lú àwọn ẹbí rẹ̀.
A leè sọ pé ìbáṣepọ̀ Ààrẹ Buhari pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Kaduna bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1962 nígbà tó darapọ̀ mọ́ ilé ẹ̀kọ́ iṣẹ́ ológun tí wọ́n ti pa orúkọ rẹ̀ dà sí Nigerian Defense Academy (NDA).
Lóòótọ́ ni pé Ààrẹ máa ń lọ fún ìsinmi ni Daura ṣùgbọ́n Kaduna ni àwọn ẹbí rẹ̀ wà.
Ní Ìpínlẹ̀ Kaduna ló ti pàdé ìyàwó àkọ́kọ́ rẹ̀.
Ààrẹ Buhari pàdé ìyàwó rẹ̀ àkọ́kọ́, Safinatu ní Ìpínlẹ̀ Kaduna níbi tí wọ́n ṣe ìgbéyàwó sí lọ́dún 1971.
Lẹ́yìn ìdìtẹ̀gbàjọba tó wáyé lọ́dún 1985, Ìpínlẹ̀ Kaduna ni Ààrẹ Buhari padà sí lẹ́yìn tó kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n.
Kódà lẹ́yìn ìgbà tí ó kọ Safinatu tó fẹ́ Aisha, Ìpínlẹ̀ Kaduna ni wọ́n tẹ̀síwájú láti máa gbé kó tó di Ààrẹ.
Kaduna ni àwọn ọmọ Buhari ti lọ sí ilé ẹkọ.
Nínú ìwé tí John N. Paden kọ nípa Ààrẹ Muhammadu Buhari ló ti ka àwọn orúkọ àwọn ọmọ Buhari àti àwọn ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n lọ ní Ìpínlẹ̀ Kaduna.
Nínú ìwé náà, Fatima lọ sí Government College, Kaduna àti ile ẹ̀kọ́ gíga fásitì Ahmadu Bello, Zaria, Nana Hadiza àti Safinatu lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Essence, Kaduna.
Bákan náà ni Halima, Yusuf, Zahra, Aisha àti Noor lọ sí Kaduna International School.
Púpọ̀ nínú àwọn ọ̀rẹ́ Buhari ló ń gbé Kaduna
Látàrí pé Ìpínlẹ̀ Kaduna ni Ààrẹ ti lo gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀, púpọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló wà ní Kaduna pàápàá àwọn tí wọ́n jọ ṣiṣẹ́ pọ̀.
Fún àpẹẹrẹ, olóògbé Shehu Musa Yar'Adua àti Colonel Ahmadu Ali jẹ́ alábàgbé Ààrẹ ní Kaduna. Bákan náà ni gómìnà Ìpínlẹ̀ Kaduna tẹ́lẹ̀ rí Usman Muazu.
Ní Kaduna ni wọ́n ti ṣe ìkọlù sí Buhari
Lọ́dún 2014 ni wọ́n ju àdó olóró sí Ààrẹ Buhari ni Kaduna.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Buhari kò fi ara pa níbi àkọlù náà tó wáyé ní Unguwar Kawo, àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò rẹ̀ mẹ́ta farapa níbẹ̀.
Láti Aso Rock padà sí Kaduna
Ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé tí Ààrẹ Muhammadu Buhari bá parí sáà rẹ̀ lọ́dún 2023, Kaduna ni yóò padà sí.
Gómìnà Ìpínlẹ̀ Kaduna Nasir El Rufai jẹ́rìí sí pé Ààrẹ Buhari yóò padà sí Kaduna lẹ́yìn sáà rẹ̀.














