Bank alert scam: EFCC gbé ọkùnrin kan tó ná N20m tó ṣàdéédéé gba ''alert'' rẹ̀

Haruna Samuel

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ati ẹbi, ati are, ki Eleduwa maa jẹ ki a ri ẹjọ o.

Ọkunrin kan ni ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ibajẹ lawujọ ti gbe lọ si ileẹjọ bayii lori ẹsun pe o na ogun miliọnu naira to ṣadeedee wọ inu akaunti rẹ.

Ẹka ajọ EFCC ni Kaduna to gbe ọkunrin lọ si iwaju adajọ Darius Khobo ti ile ẹjọ ipinlẹ Kaduna ṣalaye pe ọdun 2020 ni o huwa ọdaran naa.

Lọjọ Iṣẹgun ọjọ kejidinlogun oṣu kinni ọdun 2022 yii ni Lance Corporal Haruna Samuel to n ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ ọmogun ofurufu foju ba ile ẹjọ ni Kaduna.

EFCC ṣalaye pe ọjọ kẹta oṣu kejila ọdun 2020 ni Samuel gba atẹjiṣẹ eyiun ni ''alert'' pe N20, 014,300 ti wọ inu akaunti rẹ.

Ajọ EFCC ni aṣiṣe ni ọga Samuel ṣe fi owo naa ranṣẹ si akaunti rẹ.

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

Samuel sa kuro lẹnu iṣẹ rẹ ni nipinlẹ Plateau lẹyin ti owo naa wọ akuanti rẹ tan nibi ti EFCC ti pada mu un.

Ẹsun ti EFCC fi kan Sama

Lara ẹsun ti wọn kan an ni pe o ṣe ogun miliọnu naira( N20, 014,300.00) to ṣeesi wọ inu akaunti rẹ tii ṣe owo ileeṣẹ ọmogun ofurufu kumọkumọ.

Ile ẹjọ ni Samuel sọ owo yii di tirẹ, o ṣi bẹrẹ si ni na owo naa bi o ṣe wu hu.

Ile ẹjọ ṣalaye pe o tapa si ofin abala 293 ipinlẹ Kaduna eleyii ti ijiya wa fun ni abala 294.

Amọ, Haruna ni oun ko jẹbi gbogbo ẹsun ti wọn fi kan oun.

Agbẹjọro olupẹjọ, Precious C. Onyeneho, rọ ileẹjọ lati dajọ ti igbẹjọ naa yoo bẹrẹ.

Ṣugbọn S.A. Yahaya to jẹ agbẹjọro Haruna beere fun beeli onibara rẹ.

Lẹyin naa ni adajọ gba beeli rẹ pẹlu miliọnu naira pẹlu oniduro kan.

Wọn ti sun igbẹjọ naa si ọjọ kẹwaa oṣu kẹta ọdun 2022 yii.