Wukari monarch death: Ẹlẹ́ṣin tó gbé òkú Ọba Wukari pọ̀n wọ inú igbó rèé o! Ó sọ ìrírí rẹ ó sì tún já irọ ìròyìn orí ayélujára nípa rẹ̀

Ẹlẹṣin Sallah

Oríṣun àwòrán, Sallah Atobe

Kii ṣe ni ìjọba ilu Wukari ni aarin gbungbun orileede Naijiria nìkan bi ko ṣe kaakiri orileede ni ó jẹ pe ọrọ to n kùn yumuyumu ju lẹ́nu awọn eeyan ni nkan bíi ọjọ melo kan sẹyin ni ọrọ Ẹlẹ́ṣin kan tó gbe oku ọba ilu rẹ, Ọmọwe Shekarau Angyu Masa-Ibi pọn sẹyin wọ inu igbo Nando lọ lori ẹṣin fun isinku lọjọ Abameta to kọja.

Laye taa wa yii?

Níbi taye laju de yii?

Iru eeyan wo ni ẹlẹ́ṣin yii jẹ?

Abi o ti gba owó ẹ̀mí rẹ ni?

Ẹlẹṣin atawọn abanisọkun

Oríṣun àwòrán, Tijjani Sale Angyui

Eyi ati ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibeere lo n fọn jade lẹ́nu awọn ọmọ Naijiria pẹlu bi fọto àti fidio ohun tí Ẹlẹ́ṣin Sallah Atobe ṣe yii se gba ori ayelujara kan.

Ẹni ọdun marundinlogoji ni Sallah Atobe, to ni iyawo, to si ti bí ọmọ mẹta ni Ẹlẹ́ṣin Ọba naa o si ba BBC sọ̀rọ̀ nípa ojúṣe ńlá to tobi ju eyi to ṣe laye rẹ.

Ọ̀pọ̀ eeyan lo ti n ro o lati òpin ọ̀sẹ̀ pe ki ni yoo sẹlẹ si ẹlẹ́ṣin to wọ igbó lọ pẹlu oku ọba to waja.

"Iṣẹ nla to tobi ju laye mi"!

"O jẹ nkan iyi pe emi ni wọn mu láti ṣe iṣẹ́ gbigbe ọba wá Aku lọ si ibi ti awọn baba nla rẹ wà, ko si si ibẹru kankan lọkan mi pé aburu kankan yoo sẹlẹ si mi".

"Ojúṣe naa kii ṣe fun onibẹru rara àmọ́ bi mo ṣe ń gun ẹṣin naa lọ, ohun to wa lọkan mi ni pe inu igbo ti mo n lọ yii, awọn baba nla baba mi lo wa nibẹ ko si si ohun búburú kankan ti yoo ṣe mi". Atobe Sallah sọ fun BBC.

Bo tilẹ̀ jẹ pe àṣà ati iṣẹṣe kò gba Sallah laye lati sọ ohun ti oju rẹ ri to si ṣe ninu igbo Nando, o papa sọ nípa ẹmi aibẹru to gbe wọ àti ibowo to ni fun àṣà gẹgẹ bi ara awọn nkan to ran an lọwọ lati borí.

Ẹlẹ́ṣin to ti wá di ẹni iyi bayii to pada de si ilu ni Ọjọ Aje lẹyin to sun oorun alẹ ọjọ meji ninu igbó aginjù ti ṣe ibewo si ibi àṣà wọn fun etutu ìwẹ̀mo ó si ti dantọ lati maa ba igbe ayé rẹ lọ.

Gẹgẹ bi ọmọọba Jolly Agbu Masa-Ibi náà ṣe ṣàlàyé fun BBC bákan naa ni ẹlẹ́ṣin Sallah ṣe ni irọ nla ni pé wọn ti san owó mílíọ̀nù márùn-ún náírà fún ẹbi òun toripe wọn ni oun ko ni le pada jáde lati inu igbo naa mọ.

Ẹlẹṣin atawọn abanisọkun

Oríṣun àwòrán, Tijjani Sale Angyui

"Iyẹn kii ṣe òótọ́, ko sohun to jọ ọrọ N5m tabi owo kankan. Ohun ti mo ṣe láti inu ara mi ni eleyi mo si ṣe pẹlu idunu ni toripe mo bọ̀wọ̀ fún àṣà ìlú mi".

"Bó tilẹ̀ jẹ pe nigba ti mo pada de, iyawo mi wa ni ile iwosan tori o ro pe mi o ni pada wa tori èyí, ó dubulẹ aisan amọ ara rẹ ti ya o si ti wa nile bayii ".

Lakotan, Sallah ni oun ko gba ohun ti awọn eeyan n sọ pé asiko ti to wayii láti yí àṣà yìí pada nítorí ipenija to lee fa fun ẹlẹ́ṣin naa.

"Àṣà wa ati ajogunba ni eleyii, mi ò sì gba pẹlu awọn eeyan to n sọ pé kí a yìí padà, inú mi dùn sii mo sì fẹ́ kó wá bẹẹ.

Àwọn èèyàn Wukari pẹlu àṣà ìsìnkú 'Aku'

Ọdun marundinlaadọta ni Ọba ẹni ọdun marunlelogorin to waja ni ilu Wukari lo lórí apere ko to dagbere faye nínú oṣù Kẹwàá ọdún 2020.

Ọpọlọpọ ara ilu Wukari lo jẹ ẹ̀yà Jukun.

Àṣà wọn si ni pé ẹlẹ́ṣin yoo sìn olóògbé ọba wọ inú igbó lọ níbi tí wọn yóò ti sinku rẹ ni ìlànà àṣà wọn.

Àkọlé fídíò, Sikiru Alabi

"Wọn ti máa ń yan ẹlẹ́ṣin ti yoo ṣe iṣẹ́ yìí ni ọjọ díẹ̀ ṣáájú ọjọ ìsìnkú lẹyin ti wọn ba ti ba awọn òrìṣà ni gbolohun.

Torinaa kii ṣe pe o ni ẹbi kan pato tí wọn fi jíǹkí pé lati kékeré ni ẹni ohun yóò ti mọ isẹ rẹ".

Gẹgẹ bo ṣe sọ, bí opo èèyàn bá ti ń sìn ẹlẹ́ṣin náà lọ, lọkọ̀ọ̀kan ni wọn yóò padà títí yóò fi dé ibi to jẹ pe ẹlẹ́ṣin nìkan ni yóò dá tesiwaju láti gbé òkú Ọba náà lọ ibùgbé ìkẹyìn rẹ.

Mọ nípa Ẹlẹ́ṣin Sallah Atobe ẹni ọdun merindinlogoji

Sallah ń ṣiṣẹ́ pẹlu ile ẹ̀kọ́ gíga Fáṣítì Wukari ó sì wá pẹlu ẹ̀ka awọn ẹsọ alaabo Fáṣítì náà.

Fáṣítì yìí kan náà lo ti kàwé gboyè leyin to parí ilé ẹ̀kọ́ gírámà Wukari.

Ó ni òun yóò tesiwaju ninu isẹ oun bí òun ṣe ń ṣe lojoojumo.

Bákan náà, òun ni olórí àwọn ọdọ Wukari fun idagbasoke ìlú.