Covid-19: Wo àwọn kìnìún tó kó covid-19 lára àwọn èèyàn

Kiniun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Iṣeniyan ṣe ẹranko, ṣebi awọn eeyan lo n paya pe ki wọn maa lugbadi arun covid-19 to n ṣọṣẹ kaakiri agbaye.

Ewo tun wa ni tawọn ẹranko kan bayii ti iroyin sọ pe o ṣeeṣe ki wọn ti karun coronavirus.

Awọn onimọ sayẹnsi fasiti Pretoria lo sọ pe o ṣeeṣe kawọn olutọju ọgba ẹranko ẹranko lorilẹede South Africa ti ko arun covid-19 ran awọn kiniun kan lọgba ẹranko.

Awọn onimọ ijinlẹ sayẹnsi ọhun n kọminu iru ẹda covid-19 to le jẹyọ tawọn eeyan ba ko covid-19 lara awọn ẹranko yii.

Awọn onimọ ijinlẹ ṣe ayẹwo awọn ẹranko naa lẹyin ti wọn ṣe akiyesi apẹẹrẹ arun covid-19 lara awọn kiniun yii.

Wọn ri pe awọn kiniun yii ko le mi daadaa, wọn si tun n ṣe ikun, bakan naa ni wọn n wukọ.

Awọn onimọ sayẹnsi naa sọ pe esi ayẹwo ọhun fihan pe lara awọn to n tọju awọn ẹranko ọhun ni wọn ti ko covid-19.

Wọn ni ọpọ ninu awọn olutọju awọn ẹranko ọhun ni wọn ni arun covid-19 lasiko naa ṣugbọn wọn ko fi apẹẹrẹ han.

Awọn onimọ sayẹnsi naa wa rọ awọn olutọju ẹranko lati maa wọ ibomu ti wọn ba ti n tọju awọn ẹranko.