Ilé ẹjọ́ gbà béèlì ìgba mílíọ̀nù Naira(N200m) lórí ẹsùn tí EFCC fi kàn Mompha

Ismail Mustapha

Oríṣun àwòrán, Mompha

Ile ẹjọ ti gba oniduro gbajumọ ori ayejulara Ismail Mustapha tawọn eeyan mọ si Mompha.

Adajọ Mojisola Dada ti ile ẹjọ awọn asayan ẹsun to wa ni Ikeja nipinlẹ Eko buwọlu beeli igba miliọnu Naira fun Mompha.

Lọjọ Isẹgun ni wọn gbe gbajumọ yi to fi Dubai se ibujoko wa sile ẹjọ lati wa jẹjọ ẹsun to ni se pẹlu fayawọ owo eleyi ti ajọ EFCC fi kan an.

Ninu esi rẹ, Mompha sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ọhun.

EFCC fẹsun onipele mẹjọ kan Mompha ati ileesẹ rẹ Ismalob Global Investment lori ẹsun pe o se fayawọ owo to fẹ ẹ to biliọnu mẹfa Naira.

Lọjọ Kọkanla osu kini ni Mompha yọju niwaju adajọ Mojisola Dada nibi ti EFCC ti sọ pe awọn fẹ ki wọn fi si ahamọ lọdọ awọn.

Amọ bi wọn se tẹsiwaju igbẹjọ naa lọjọ Kejidinlogun osu yi,agbẹjọro rẹ Boyega Oyewale sipẹ ki ile ẹjọ gba oniduro gbajumọ ori ayelujara yi nitori pe o ni arun Covid-19.

Lẹyin atotonu awọn agbẹjọro, adajọ gba ki wọn san igba miliọnu Naira lowo oniduro fun ẹni ọdun mejilelogoji yi.

Bakan naa ilẹ ẹjọ tun sọ pe:

•Mompha gbọdọ mu oniduro meji wa

•O gbọdo ko iwe irina pasipọti rẹ kalẹ

•Awọn oniduro yi gbọdọ bura pe awọn ni ohun ti wn yoo fi duro

•Awọn oniduro rẹ gbọdọ nisẹ to jọju lọwọ ti wọn si gbọdọ wa ni arọwọto ile ẹjọ

•Wọn gbọdọ safihan ẹri pe wọn san owo ori laarin ọdun mẹta sẹyin

•Ki awọn alasẹ fi Mompha sọdọ titi ti yoo fi ribi pari eto lori beeli rẹ

Adajọ Dada pada sun igbẹjọ di ọjọ mejidinlọgbọn ati ọjọ mọkandinlọgbọn osu kẹta .

Ọkan ninu awọn ẹ́sun ti wọn fi kan Mompha ati Ismalob ni pe wọn gbimọran lati gba owo lọna aitọ,gbe owo naa pamọ,ki wọn si salabapin owo naa fun afurasi kan Olayinka Jimoh ti inagijẹ rẹ n jẹ Nappy Boy to fi mọ pinpin owo naa fun ileesẹ rẹkọdi kan ati awọn mii.

Gẹgẹ bi iwe ipẹjọ, iye owo taa n wi yi jẹ N5,998,884.653.18, N32million, N120million ati N15,960,000, ti apapọ rẹ si jẹ N6billion.

Bẹẹ naa ni wọn sọ pe Mompha fi owo ele rẹ pamọ nipa awọn ago olow