Lassa Fever: Ìjọba ìpinlẹ̀ Oyo ní kí àwọn aráàlú má fòyà lẹ́yìn tí àrùn Lassa mú ẹ̀mí méjì lọ

Eku

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Eku

Ijọba ipinlẹ Oyo ti ke si awọn eeyan ipinlẹ naa lati má foya lẹyin ti wọn ṣawari arun iba Lasa ni ijọba ibilẹ Iwajowa ni ipinlẹ naa.

Kọmiṣọnna fun eto ilera ni ipinlẹ ọhun, dọkita Bode Ladipo lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ si awọn akọroyin niluu Ibadan.

O ni ijọba ti gbe awọn eto kan kalẹ lọna ati dena itankalẹ arun naa nipinlẹ Oyo.

Gẹgẹ bii nnkan to sọ, ijọba ipinlẹ Oyo ti ṣeto awọn abẹrẹ ati oogun lati ṣe itọju awọn to ti lugbadi arun naa.

O fi kun un pe awọn ti pese awọn irinṣẹ idabo bo ara ẹni fun awọn oṣiṣẹ eto ilera lagbegbe Iwere Ile ati Iganna.

Àkọlé fídíò, Eba

Atẹjade naa ni "Ileeṣẹ eto ilera ti gbọ nipa awọn ẹmi to sọnu ni ijọba ibilẹ Iwajowa lọjọ kejila, oṣu Kinni, ọdun 2022 yii."

"Lẹyin iroyin naa ni ikọ oluwadii ti kọmiṣọna eto ilera ko sọdi ṣabẹwo si ijọba ibilẹ naa lọjọ kẹwtala, oṣu Kinni yii kan naa."

"Lara awọn to wa ninu ikọ naa ni awọn ọga agba ni ileeṣẹ eto ilera, awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ eto ilera alabọde atawọn aṣoju ajọ to n ri si eto ilera lagbaye, WHO."

Àkọlé fídíò, Ẹni bá láyà kó wá wọ̀ọ́! Ta ni Ìgè Àdùbí nílẹ̀ Oodua?

Atẹja naa ṣalaye pe ikọ ọhun ṣabẹwo si abule Gaa Agbaruru nibi ti awọn ti aisan naa kọkọ kọlu n gbe.

Lẹyin naa ni wọn ṣe ayẹwo ẹjẹ awọn eeyan ọhun, to fi mọ omi ti wọn n mu, ti esi ayẹwo naa si fi han pe meji ninu awọn mẹwaa ti wọn yẹ wo ti lugbadi arun Lassa.

Àkọlé fídíò, Arinrinoge ti eyin rẹ kán

Bo tilẹ jẹ pe atẹjade naa ni awọn kan lara awọn ti wọn lugbadi arun ọhun ti n gbadun, awọn n ṣiṣẹ takuntakun ki arun naa ma ba tan kalẹ ju bo ṣe wa lọ.

Lẹyin naa ni lo fi awọn nọmba kan sita ti awọn eeyan le maa pe ti wọn ba ṣakiyesi arun ọhun ni sakani wọn.

Awọn nọmba naa ree: 09058704101, 08025245800 ati 08073431342

Eku

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Eku

Ibà Lassa tún ti ń sọṣẹ́ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà:

Okoolerugba-lemeji awọn eeyan ni wọn ti lugbadi arun iba lassa ti meji si ti rọrun alakeji laarin ọsẹ kan nipinlẹ mẹẹdogun ati olu ilu ilẹ yi.

Ọpọlọpọ ninu awọn akọsilẹ iṣẹlẹ yii ni owaye ni ipinle Edo, Ondo, ati Bauchi.

Ojọ ori awọn to fara kaṣa aarun yii wa laarin mọkanlelọgbọn ati ogoji ọdun.

Ajọ to n mojuto didena itankalẹ arun lorilẹ ede Naijiria, NCDC, lo sọ eleyi ninu atẹjade ọlọsẹẹse rẹ lọjọ Aje.

Ninu atẹjade naa, awọn mọkandilaadọrin ni wọn n gba itọju kaakiri awọn oriko itọju.

Ajọ naa ni alekun ti de ba iye awọn ti wọn fidi rẹ mulẹ pe wọn ni iba lassa jakejado Naijiria.

Ounka yi ni wọn lo ti pọ niye ti a ba fi we irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ ni ọdun 2021.

Àkọlé fídíò, Fatimah Abode Lybia

Ajọ naa ni wọn ti dari awọn ikọ ti yoo ṣe abojuto aarun iba ọrẹrẹ naa lọ si awọn ipinlẹ ti aarun naa ti gbinlẹ ju.

Aarun iba Lassa maa n wọ agọ ara eeyan ti wọn ba ti fọwọ kan awọn ohun elo ile tabi jẹ ounjẹ ti awọn ẹranko tabi eeyan to ni aisan naa ba fọwọ kan.

Awọn apẹẹrẹ aarun naa ni igbona ara, ori fifọ, ara riro, ikọ, eebi ati aya didun.

Ni igba miran ti aarun naa ba ti wọ ara tan, ẹjẹ a maa jade ni eti, oju, imu, ẹnu ati awọn oju ara miran.