2023 election aspirants: Ẹ wo àwọn olùdíje fuń ipò ààre tó ti fi èròńgbà hàn

Eto idibo ọdun 2023 ni o ti n sumọ'le ti awọn oloṣelu si ti n gbaradi, bo tilẹ jẹ pe ajọ eleto idibo, iyẹn INEC ko ti sọ pe iponlongo le bẹrẹ.
Lati ẹkun idibo mẹfẹẹfa Naijiria ni ọpọlọpọ awọn oludije ti n gbaradi fun ibo to ṣe pataki yi.
Oriṣiriṣi ipo ni o wa nilẹ ti gbogbo ẹni ti ofin ba gba laaye le dije fun.
Amọ ninu awọn ipo yi, eyi to ṣe gboogi julọ ni ti Aarẹ orilẹ-ede.
- O.Y.O ni Tinubu wa o, a kò ní ṣ'àtìlẹ̀yìn fún un ní 2023 àyàfi ... - Afenifere, Ilana Omo Oodua
- Tinubu ló lè ṣeé lọ́dún 2023, Pa Fasoranti àti Oba Osemawe Ondo sọ̀rọ̀ sókè
- Tinubu hùwà ọdàlẹ̀, Ọlọ́run kó sì ní gbà fún un lórí èròngbà rẹ̀ - Ohanaeze Ndigbo
- N kò rán ẹnikẹ́ni láti pín ìrẹ̀sì àti ẹ̀wà tórí ìbò ààrẹ 2023 - Bola Tinubu figbe ta
- Wo àwọn ọ̀rọ̀ táwọn ọmọ Naijiria fi kí Twitter kúàbọ̀ bí ìjọba ṣe gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí rẹ̀
Ta wa ni awọn oloselu to ti sọ erongba wọn lati dije fun ipo Aarẹ orilẹ-ede yii?
Die ree ninu awọn to ti fi erongba wọn han si araalu lasiko yi.Pius Ayim

Oríṣun àwòrán, Pius Ayim, Facebook
Aarẹ tẹlẹ rii ni ile Asofin agba ni ilu Abuja, Pius Ayim wa a lara awọn to kọkọ fi erongba wọn han lati dije fun ipo aare labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP.
Ayim to rọ gbogbo ẹgbẹ oṣelu lati fa oludije labẹ asia wọn kalẹ lati ila oorun-guusu Naijiria ṣalaye pe ko si oun ti yoo ṣe idina fun oun lati dije fun ipo aarẹ.
Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu, Facebook
Tinubu jẹ gomina tẹlẹri ni ipinlẹ Eko. Aṣiwaju ninu ẹgbẹ oṣelu onigbalẹ, iyẹn APC ati afọbajẹ to ti tukọ bi ọpọlọpọ oloṣelu ṣe di gomina, minisita, kọmiṣọna, sẹnetọ, ati bẹẹbẹẹ lọ.
Lẹyin ti o ba ààrẹ Mùhámádù Buhari ṣe ipade lori ipinnu rẹ lati dije fun ipo ààrẹ, Tinubu sọ fun awọn oniroyin pe ko si ofin to sọ pe afọbajẹ ko le jẹ ọba.
O ni erongba oun fun ọjọ pipẹ ni lati di aarẹ orileede Naijiria.
Orji Uzor kalu

Oríṣun àwòrán, Orji Uzor kalu, Facebook
Gomina tẹlẹ ri ni Kalu to si tun jẹ sẹnetọ to n ṣoju igun Ariwa ni ipinlẹ Abia.
Bẹẹ náà ni o jẹ olori akojanu ile aṣofin giga ni ilu Abuja.
Laipẹ yi ni o sọ fun awọn oniroyin ni ilu Abuja pe òun maa dije fun ipo aarẹ ti ẹgbẹ oun, iyen APC ba fa oludije labẹ asia ẹgbẹ naa kalẹ lati ila oorun-guusu ilẹ yi.
Dave Umahi

Oríṣun àwòrán, Dave Umahi, Facebook
Umahi ni gomina ipinlẹ Ebonyi ti o si jẹ ogbontarigi oloṣelu ti o ti ṣe igbakeji gomina ri.
Lẹyin ọpọlọpọ ọdun ninu ẹgbẹ PDP o dara pọ mọ ẹgbẹ APC ti osi sọ erongba rẹ lati du ipo ààrẹ nigbati oun naa ti ba ààrẹ Mùhámádù Buhari ṣe ipade ni Abuja.
Dele Momodu

Oríṣun àwòrán, Dele Momodu, Facebook
Momodu jẹ ogbontarigi oniroyin ti o ti dun ipo aarẹ ri labẹ asia ẹgbẹ National Conscience Party, NCP ni ọdun 2011 amọ to fidi rẹmi.
Ọ jẹ agba ojẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC lati ọdun 2015 ko to di pe ọ fi ẹgbẹ naa silẹ ni ọdun 2021 lati dara pọ mọ ẹgbẹ PDP.
Adebayo Adewole

Oríṣun àwòrán, ADEBAYO FACEBOOK
Adewole, oludasile ati alakoso ilẹ iṣẹ mohun-maworan Kaftan TV ni ilu Ondo ni o ti sọ erongba rẹ lati dije fun ipo to gaju ni orilẹ-ede Naijiria.
Yatọ si pe o je gbajugbaja oniṣjowo ni oke okun, ati ẹlẹyinju aanu, ko si akọsilẹ kankan pe o ti ko pa ninu ọṣelu ri.
Kingsley Moughalu

Oríṣun àwòrán, Kingsley Moghalu, Facebook
Moughalu jẹ igbakeji gomina tẹlẹ ri fun ile banki apapọ Naijiria, iyẹn CBN to si tun dije ni ọdun 2019 labẹ asia ẹgbẹ awọn ọdọ, Young Progressives Party.
Ogbontarigi ọmọwe ni lori ọrọ iṣuna to tun ti sọ igbaradi rẹ lati dije fun ipo aarẹ ni ọdun 2023.
Yatọ si awọn ti a ti mẹnuba yi, ọpọlọpọ oloṣelu naa ni awuyewuye ti gba igboro lori ipinnu wọn lati dije fun ipo aarẹ.












