Ekiti state PDP Congress: Fayose, Olujimi, Oni ń forígbárí nítorí ìdìbò wọ́ọ̀dù tó wáyé lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP l'Ekiti

Oríṣun àwòrán, Others
Ina edeaiyede n jo laarin awọn eekan oloṣelu lẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Ekiti paapaa laarin igun gomina tẹlẹ, Ayọ Fayose ati igbakeji rẹ nigbakan ri to tun jẹ sẹnetọ lọwọ bayii nileegbimọ aṣofin apapọ Naijiria.
Ko si ohun meji to n fa awuyewuye laarin wọn ju abajade eto idibo ati yan awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọọdu to waye nipinlẹ Ekiti lọjọ Satide, ọjọ karundinlogun oṣu kinni ọdun 2022.
Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Sẹnetọ Abiọdun Olujimi ṣalaye pe lara ọna ati mu iṣọkan igbọraẹniye ati alaafia pada sagbo ẹgbẹ naa nipinlẹ Ekiti lawọn fi wo eto naa.
- Wo ibi ti ìgbẹ́jọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba méjì tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n ji ọmọ arábìnrin tó ní arùn ọpọlọ gbé ní Akure
- Ẹ yìnbọn pa ẹnikẹ́ni tó bá ṣe ìkọlù sí ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n- Mínístà Aregbesola
- Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nílé ẹjọ́ lónìí lórí ọ̀rọ̀ Kanu lẹ́yìn tó sọ pé òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án
- Fayose, Olujimi, Oni ń forígbárí nítorí ìdìbò wọ́ọ̀dù tó wáyé lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP l'Ekiti
- Ibà Lassa tún ti ń sọṣẹ́ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà
O ni igbagbọ awọn ṣaaju eto naa ni pe gbogbo ẹgun iṣaaju to da wahala silẹ ni wọn yoo dana sun.
Amọsa, o ni ọrọ ko ri bẹẹ nigba ti awọn rii pe meji ninu awọn eeyan to wa nidi wahala naa lati ipilẹ wa ni wọn tun yan lati ṣe akoso idibo aṣoju naa.
Sẹnatọ Abiọdun Olujimi fi ẹsun kan Oloye Ayọ Fayose pe oun gan ni eku ẹda to n da ina alaafia PDP ru paapa pẹlu ti idibo aṣoju wọọdu naa.
Sẹnetọ naa ṣalaye pe inu kọrọ ile kan ni awọn igun OPA to jẹ ti Fayoṣe ti kọ orukọ awọn aṣoju ti wọn fẹ laifi ti awọn igun ti 'Repositioning' to wa pẹlu Olujimi ṣe.

Oríṣun àwòrán, others
Ki ni Fayose sọ?
Amọṣa ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, gomina tẹlẹ nipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayoṣe ṣalaye pe oun o ba ẹnikẹni ja.
O ni eeyan oun ni gbogbo wọn, oun ko si tii ṣe ohnunkohun to buru gẹgẹ bii aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu naa.
Fayoṣe ṣalaye pe oun o mọ idi ti awọn oludije ti ọrọ kan ṣe n pariwo oun nigba ti wọn mọ pe oun kii ṣe Oludije.
- Àwọn àgbà oyè Ibadan fẹnukò láti gbé ẹjọ́ kúrò nílé ẹjọ́
- Lóòtọ́ ni àrùn Lassa ti wọ ìpìnlẹ́ Oyo, àmọ́ ẹ má mikàn- Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo
- DSS, ẹ jẹ́ kí Kanu pààrọ̀ aṣọ tó ń wọ̀ wá sílé ẹjọ́ mi bí bẹ́ẹ̀ kọ́.......- Adajọ Binta Nyako
- Ṣé lóòtọ́ ni gómìnà ìpínlẹ̀ Abia àti Imo wọ àṣo àsíí Biafra bí o ṣe jáde lórí ayélujára?
- Ọlọ́run Tinubu kìí ṣé Ọlọ́run témi torínáà mi o ní gbè lẹyìn rẹ̀ ní 2023- Ojudu
Oṣoko, gẹgẹ bi orukọ inagijẹ ti ọpọ maa n pe e ṣalaye pe niwọn igba to jẹ wi pe nitori pe awọn oludije naa ri oun gẹgẹ bii eeyan pataki lagbo oṣelu ni wọn fi n da orukọ oun.
O ni gbogbo awọn ileeṣẹ agbofinro ni wọn ni akọsilẹ pe eto idibo ati yan awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọọdu waye nipinlẹ Ekiti, oun kọ lo si gba wọn siṣẹ.

Oríṣun àwòrán, Tvc
Fayose, Olujimi, Oni ń forígbárí nítorí ìdìbò wọ́ọ̀dù tó wáyé lẹ́gbẹ́ òṣèlú PDP l'Ekiti
Lara awọn eekan oloṣelu ni ipinlẹ Ekiti to n gbaradi lati dije fun ipo gomina labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Ekiti, Biọdun Olujimi ati Ṣẹgun Oni fọn si igboro ilu Ado Ekiti lati ṣe iwọde takogomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Ayọdele Fayose.
Ẹsun ti wọn n fi kan Fayose ni pe o ti n dọwọ ru pẹlu ibo yiyan awọn adari ati aṣoju ẹgbẹ naa lẹsẹpupu wọọdu eyi to waye lọjọ Satide ọjọ karundinlogun, oṣu Kinni dun 2022.
Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP kan dara pọ wọ iwọde naa ti wọn si n ke sawọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu naa lati fofin de Fayoṣe lẹgbẹ oṣelu naa.
- Ikú Esther Anguju ní ìpínlẹ̀ Nasarawa dá inú fu, àyà fo kalẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn ìpànìyàn kan ọkọ rẹ̀
- Àwọn gómìnà PDP parí ìpàdé, wọ́n ní Buhari ti dojú ọrọ̀ ajé Nàìjíríà rú
- Wo àwọn ọmọ Yorùbá mẹ́fà tí ẹnu ń kùn lórí ìbò ààrẹ ọdún 2023
- Ọkùnrin kan gún ìyàwó rẹ̀ ọlọ́mọ mẹ́jọ pa nítorí pé ó ń ti ilẹ̀kùn mọ́rí
Wọn ni o n ṣe agbẹyinbẹbọjẹ fun gbogbo ilakaka awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu naa nipa dida ṣe idibo yiyan awọn adari wọdu ni gbọngan adani rẹ kan lasiko to si jẹ pe ipade idibo ti ẹgbẹ fọwọ si gan n lọ kaakiri awọn wọọdu mẹtadinlọgọsan nipinlẹ naa.
Awọn oludije mejeeji naa wa ke sawọn adari ẹgbẹ oṣelu naa lati maṣẹ fọwọ kan iwe orukọ awọn adari wọọdu yoowu ti Ayọdele Fayose ba fi ranṣẹ si wọn nitori pe, ni ti awọn o, ipade idibo yiyan adari ẹgbẹ oṣelu PDP lawọn wọọdu nipinlẹ Ekiti ko waye.
Ki ni olu ileeṣẹ ẹgbẹ oṣelu PDP sọ nipa idibo adari wọọdu nibẹ?
Awọn alaṣẹ apapọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni awọn ti tẹwọ gba abajade ipade idibo yiyan awọn adari ati aṣoju ẹgbẹ naa lẹsẹpupu wọọdu lati ipinlẹ Ekiti.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi si oju opo ikanni Twitter ẹgbẹ oṣelu PDP awọn alaṣẹ ẹgbẹ oṣelu naa ni awọn yoo wa ojutu si awọn aawọ to suyọ lasiko ipade idibo naa.
Atẹjade ọhun ti alukoro ẹgbẹ oṣelu PDP lapapọ, Debọ Ologunagba fọwọ si ṣalaye pe bi wọn ṣe n tẹwọ gba esi idibo naa ni wọn tun tẹwọ gba awọn iwe ẹhonu latọdọ awọn mọ ẹgbẹ to ni ẹhonu kan kabi omiran.
O ni gbogbo rẹ ni wọn yoo yẹwo lati rii daju pe alaafia n jọba.



















