Mother, son kill younger sibling: Bí àṣírí ọkùnrin tó fẹ́ fi àbúrò rẹ̀ ṣoògùn owó ṣe tú

Crime

Oríṣun àwòrán, independent.ng/

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tẹ okunrin kan ati iya rẹ lori ẹsun pe awọn mejeji pa aburo rẹ lọna ati fi ṣoogun owo.

Okunrin ọhun, Afeez Olalere jẹwọ fun ikọ akọṣẹmọṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko pe iya oun lo ti oun lẹyin lati pa aburo oun lọna ati fi ṣẹṣo.

Akara iya ati ọmọ naa tu sepo lasiko ti awọn ọlọpaa n yẹ ẹru wọn wo ni opopona Itamaga si Ikorodu, niluu Eko.

Àkọlé fídíò, 'Ká tó rí irú Akala, ó di "century" míì, kò sí olóṣèlú kankan tó máa ń ṣilẹ̀kùn rẹ̀ fún wa l'Ogbomoso'

Okunrin naa ni "Iya mi lo mu mi lọ sọdọ babalawo kan, ti iyẹn si sọ fun mi pe ti mo ba fẹ lu aluyọ nidi iṣẹ Yahoo ti mo n ṣe, mo ni lati fi ẹmi mọlẹbi mi kan rubọ."

"Awọn ohun to nilo lati ṣe eto naa fun mi ni ika ọwọ ẹni naa, irun, ika ẹsẹ ati aworan rẹ̀."

"Nigba ti a pada sile, emi ati iya mi jiroro lori ọrọ ọhun, iya mi si gba mi niyanju lati lo aburo mi okunrin niwọn igba to jẹ pe ẹni ọdun mọkanlelgun pere ni."

Àkọlé fídíò, Mo mọ èsì ọ̀rọ̀ kẹ̀, Queen Salawa Abeni ló kọ́kọ́ ta sí mi pé èmi 'Alaragbo ọmọ bàbá olójú kan' ní 1980s - Kuburat Alaragbo

Afeez tẹsiwaju pe "Iya mi lo fun ni majele ti a fi sinu ounjẹ rẹ, o si ku laarin ogun iṣẹju to jẹ ounjẹ naa tan."

O fi kun pe oun funra oun ni oun ge gbogbo ẹya ti wọn nilo lara oloogbe ọhun.

Lẹyin naa ni wọn we oku naa, ti wọn si gbe lọ sile igbokupamọsi.

Àkọlé fídíò, 'Mo sọ fún Dókítà pé èmi ò lè gé ọyàn mi, pé ṣọ́ọ̀ṣì yóò fi àdúrà ṣẹ́gun àìsàn jẹjẹrẹ ọmú mi'