Jennifer Anthony: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣàfihàn afurasí tó pa akẹ́kọ̀ọ́binrin Unijos

Oríṣun àwòrán, others
Àwọn ọlọpaa ti mu afurasi ẹni ogún ọdún to pa ọrẹbinrin rẹ. Baba afurasi ọ̀daràn ti ileesẹ ọlọ́pàá mu pe o pa ọrẹbinrin rẹ nilu Jos, Moses Oko, sọ pe ọmọ naa ma n mu igbo.
Ọjọ́rú ni ileesẹ ọlọ́pàá nipinlẹ Plateau safihan Oko, fun pe o pa ọrẹbinrin rẹ, Jennifer Anthony, to jẹ akẹ́kọ̀ọ́ fasiti ilu Jos. Ẹni ogun ọdún ni Moses Oko.
- Èèmọ̀! Saka dáná sun 'ààlè' rẹ̀ tọmọ-tọmọ n'Ibadan, òun nàá tún jóná kú
- Wo àwọn ọ̀rọ̀ táwọn ọmọ Naijiria fi kí Twitter kúàbọ̀ bí ìjọba ṣe gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí rẹ̀
- Ọkùnrin tó lẹ ''Super Glue'' mọ́ ǹkan ọkùnrin rẹ̀ láti rọ́pò ''condom'' ti dèrò ọ̀run
- Mo dé ilé alálùfáà àti babaláwo kí n tó rí ọ̀rẹ́bìnrin mi tó jí ìbọn mi gbé nínú ọ́físì mi- DPO
- Háà, nǹkan ṣe mí! Ikú pa ọ̀kan lára àwọn aláànú mi - Yinka Ayefele
Baba rẹ, Ọgbẹni Oko, to jẹ olùkọ́ ni fasiti ilu Jos sọ fun àwọn akọroyin pe ọmọ oun ni aisan ọpọlọ, to ṣe e ṣe ko jẹ nipasẹ igbó mimu.
Agbenusọ ọlọpaa, Ubah Ogaba sọ pe ipinlẹ Benue ni ọwọ ti tẹ afurasi naa.
Ọgbẹni Ogaba sọ pe àwọn yoo gbe afurasi naa lọ sile ẹjọ́ ni kia ti iwadii ba pari.
Ọjọ́ kọkanlelọgbọn, oṣù Kejila, ọdún 2021, ni Jennifer to wa ni ipele ẹ̀kọ́ kẹta, di awati, ki awọn ọlọpaa to o ri oku rẹ lọjọ kinni, oṣù Kinni ọdun yii.
Koda, ẹ̀yà ara rẹ ko pe mọ nigba ti wọn ri i ni ile itura kan to wa ni opopona ilu Zaria. Oju rẹ kan ko si nibẹ mọ.
Bawo lo ṣe ṣẹlẹ̀?
Ọrẹ oloogbe Jennifer, Jessica Dung, sọ fun BBC Pidgin pe Jennifer múra lọjọ naa, to si dagbere pe oun n wa isẹ lọ.
Nigba ti Jessica ko gburo ọrẹ rẹ, ti ko si ri ko pada sile, lo bẹ̀rẹ̀ si ni pe ẹ̀rọ ibanisọrọ, sugbọn nọmba rẹ ko lọ.

Oríṣun àwòrán, others
O ni kiakia ni oun mọ pe nkan ti ṣẹlẹ̀ si ọrẹ òun, nitori pe kii pa foonu rẹ, bẹẹni kii sọ̀wọ́n lori ayelujara.
Igba ti Jessica ko ri ọrẹ rẹ titi di ọjọ keji, lo ba gbe aworan rẹ si ori ayelujara pẹlu ikede pe ki ẹnikẹni to ba ri ko pe nọmba ti oun fi sinu ikede naa.
O salaye pe iyalẹnu lo jẹ nigba ti wọn pe oun lati ile itura kan pe ki oun wa a wo oku ọmọbìnrin kan, boya o ṣe e ṣe ko jẹ Jennifer.
- A tí ṣé tań láti díje fuń ipò ààre ní ọdún 2023
- Wo àwọn èèkàn mẹ́rin tí Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ pàdánù láàárín oṣù kan
- Bí Otunba Adebayo Alao Akala ṣe kú rèé, àti ibi tó dákẹ́ sí gangan - Amúgbálẹ́gbẹ́ Alao Akala
- Háà! Akẹ́kọ̀ọ́ forí gbálẹ̀, o di èrò ọ̀run ní Ondo
- Pásítọ̀ David Ibiyeomie, adarí ìjọ Salvation Ministry tò dàwó sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà
Nigba to de ibẹ, o ri awọn aṣọ Jennifer ni ilẹ̀, ati awọn nkan rẹ miran. Inu àgbàrá ẹ̀jẹ̀ si ni wọn ba a ni nkan bí aago mẹjọ ku isẹju mẹẹdogun ni alẹ.
Àwọn aláṣẹ ile itura Domus Pacis Guest House nilu Jos, sọ pe ni nkan bi aago mejila ọsan ni àwọn ri oku Jennifer ninu àgbàrá ẹ̀jẹ̀ ninu yaara.
Ẹ̀yà ara rẹ ko pe, bakan naa ni oju rẹ kan ti di awati.
Wọn fi iṣẹlẹ naa to ileesẹ ọlọpaa leti, ti awọn ọlọpaa si gbe oku naa lọ si ile igboku pamọ si.
Bákan naa ni wọn mú òṣìṣẹ́ ile ìtura naa meji.

Oríṣun àwòrán, others
Iwadii wọn lo si fihan pe o se e se ko jẹ ọrẹkunrin rẹ to ti sá lọ lo pa a.
Ọjọ́ kọkanla, osu Kinni, ni ọwọ tẹ ọrẹkunrin naa, Moses Oko nipinlẹ Benue nibi to salọ.















