Ondo student dies: Ọmọ ọduń 16 ni Ojo tó kú ikú òjijì ní kíláàsì

Oríṣun àwòrán, CAC GRAMMAR SCHOOL
Akẹkọọ kan ni ipinlẹ Ondo, Emmanuel Ojo ni o ti ku iku ojiji lẹyin to fori gbalẹ nibi to ti n ba awọn akẹgbẹ rẹ ṣere nille ẹkọ CAC Grammar School Akure.
Iroyin ni Ojo to jẹ ọmọ ọdun 16 farapa lẹyin to fori gba ogiri lẹba oju ferese to si tubọ fori naa ṣubu lulẹ.
Kete to ṣẹlẹ ni awọn akẹgbẹ Ojo ke gbajare ti awọn olukọ rẹ si gbe e digba-digba lọ sile iwosan ijọba ni ilu Akure.
- Ọkọ mi pa ọmọ wa mẹ́ta, o kó òkú wọn sínú fírísà - Milliscent Amadikwa
- Ọ̀dọ́ márùn-ún forí la ikú nínú oko lọ́wọ́ agbébọn tó tún ṣèkọlù l'Ondo
- Pásítọ̀ David Ibiyeomie, adarí ìjọ Salvation Ministry tò dàwó sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà
- Wo ìdí tí ìjọba Naijiria ṣẹ̀ṣẹ̀ gbẹ́sẹ́ kúrò lórí òfin tó fi de Twitter lẹ́yìn oṣù Méje
- Wo àwọn ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Alao Akala tó dágbére fáyé lẹ́ni ọdún 71
- Wo àwọn èèkàn mẹ́rin tí Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ pàdánù láàárín oṣù kan
- A gbọ́dọ̀ padà sí ìlànà tà ń gbà jẹ Olubadan tẹ́lẹ̀ – Seyi Makinde
Amọ o dake ko to de ile iwosan naa.
Ẹ̀wẹ, ijọba ipinlẹ Ondo ti ba ẹbi akẹkọọ ọhun kẹdun. nipa ṣiṣe
Ikọ ijọba to lọ si ile rẹ ti komiṣona fun ọrọ ẹkọ ati imọ sayẹnsi Femi Agagu ṣoju fun parọwa fun ẹbi Ojo lati ri iṣẹlẹ ọhun gẹgẹ bi amuwa Ọlọrun.
Baba akẹkọọ ọun to jẹ Pasitọ ni ijọ kan, Alufa Joshua Ojo sọ pe Ọlọrun nikan ni iṣẹlẹ naa ye o.

















