Raymond Adegoke Cerebral Palsy: Ìgbà tó tó àsìkò tó yẹ kó jókòó, kó máa fà, ohun tójú wa rí nìyí - Ìyá
Ohun ti oju Ọgbẹni Raymond Adegoke ri gẹgẹ bi oṣiṣẹ ijọba to tun wa jẹ akanda eeyan kii ṣe kekere.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba, Raymond sọ bi iṣẹlẹ to ṣẹlẹ sii ṣe ba a ninu jẹ to tun wa di nkan to di ija ofin laarin rẹ ati ile iṣẹ ijọba to n ba ṣiṣẹ.
"Mo kunlẹ, mo bẹbẹ, mo ṣe gbogbo ẹ, amọ o ni ka ṣi maa lọ na afi ti gomina ba to ni ki oun gba a".
Iya rẹ ni wọn ba fun oun ni lẹta kan pe ki oun fun ọmọ rẹ, igba ti wọn ṣi i wo lo ba di iwe idaduro lẹnu iṣẹ.
- Ẹ má 'Pity' wa mọ́, Olorun ló dá àwa tí a ní 'Cerebral Palsy'- Olawale Dada, Oníṣòwò ilé títà
- "Ọpọlọ ọmọ mi kò pé, ó ní àìsàn ọ̀nà ọ̀fun, wárápá, tí kò sì rìn lọ́mọ́ ọdún méje àmọ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́, ayọ̀ ló já sí"
- Mo sọ Dókítà dí òpùrọ́ lórí ayé mi - Steph
- "Ọ̀mùtí kọlù mí lọ́mọ ọdún mẹ́rin, mo di ẹlẹ́sẹ̀ kan àmọ́ kò dí mi lọ́wọ́ láti kàwé di dókítà"
Ẹni Ogoji ọdun ni Raymond to ni aisan to ni ṣe pẹlu iṣan eyi ti oloyinbo n pe ni Cerebral Palsy.
Raymond ni nkan to n ṣe oun fara jọ ohun ti oloyinbo n pe ni "Cerebral Palsy" amọ orukọ ti eyi n jẹ gangan oun ko le sọ ọ.
Iya rẹ to ṣalaye ohun to la kọja gẹgẹ bi abiyamọ ṣalaye fun BBC pe ẹni to ba ri Raymond ni kekere ko le mọ pe bi ọrọ rẹ ṣe maa ri leleyii.
- Gbogbo àṣà àtijọ́ fún yíyàn Ọba, ṣíṣe ìsìnkú Ọba gbúdọ̀ dópin lónìí pẹ̀lú àṣẹ - Dapo Abiodun
- Àwàdà kẹríkẹrì ni ìgbésẹ̀ Tinubu láti du ipò Ààrẹ - Bode George
- "A ò lè sọ pàtó ibi tí Raheem Adedoyin wà báyìí"; "Àmọ́ ẹ mọ̀ nígbà tí ọlọ́pàá kò tíì wá a"- Agbẹjọ́rò Adedoyin àti ti ìdílé Timothy takurọ̀sọ
- Kìí ṣe ilẹ̀ Afíríkà ni mo wà nígbà tí mo kọ́kọ́ wá sílé ayé - àṣírí ọ̀rọ̀ tuntun rèé lẹ́nu Mummy G.O
- Wo bí ọ̀fìnkìn ṣe lè dáàbò bò ọ́ lọ́wọ́ àrùn Covid-19
- Dayo Kujore: Àgbà olórin juju dágbére fáyé pé ó dìgbòóṣe!
- 'Ìdí nìyí tí mo fi yọ kórópọ̀n mi kí n má lè bá obìnrin kankan sùn'
- Ìgbà márùn ùn ọtọ́ọ̀tọ tí Nàìjíríà àti Egypt kojú lórí pápá ní Afcon
"Mo maa gbe e joko, emi a joko sẹyin rẹ, mo maa ju nkan si i niwaju lati mọ boya yoo gbera. Igba to to ko lọ ile ẹkọ, mo maa n gbe e pọn ni".
O ni "igba ti mo bi i, o pupa, o rẹwa, ko sẹni to le mọ pe bi yoo ṣe pada ri leleyii".
Iya rẹ, Aderibigbe Margaret Adebisi sọ pe Raymond yege ninu gbogbo idanwo rẹ titi to fi ka ile ẹkọ girama to tun yege wọ ile ẹkọ giga fasiti to kẹkọọ gboye.
Raymond kọ lati jẹ ki aipe ara rẹ da a duro lati laluyọ laye. O wa ṣalaye bo ṣe bori gbogbo ipenija yii toun naa si di ẹni to riṣẹ to n lọ ọfiisi amọ ṣe ni orin tun yipada ti oniruuru iṣẹlẹ waye ti wọn fi da a duro ni ile iṣẹ rẹ koda ti gomina ipinlẹ naa d a si i.
Bo tilẹ jẹ pe Raymond ni wọn parọ mọ oun ni pe o to ọdun kan ti oun ti wa ibi iṣẹ gbẹyin, awọn aṣoju ijọba sọ fun BBC Yoruba pe bi wọn ba fẹ ẹri, awọn lee gbe faili rẹ jade.

