Ẹ̀yà ara tó ń gbogun ti ọ̀fìnkìn, le tako àrùn Covid-19

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn oniwadi ijinlẹ ti ni awọn ọna ti ara eniyan n gba gbogun ti ọ̀fìnkìn funra rẹ lo le ṣe idaabobo fun-un lọwọ arun Covid-19 naa.Iwadi kekere ọhun, eyi ti wọn ṣe atẹjade rẹ ninu iwe kan ti wọn pe ni "Nature Communications" ni wọn ti ko awọn eeyan mejilelaadọta jọ, ti wọn si n gbe pẹlu ẹni kan to lugbadi arun Covid-19.Iwadii naa ni awọn eeyan ti ara wọn ti ni eroja fun ṣiṣe atako otutu aya lagọ ara wọn, ni iwadi naa ni yoo ṣoro fun lati ko kokoro Covid.
- A ti wọ́gilé àpèjẹ níbi ètò ìsìnkú àti ìgbéyàwó nítorí ìtànkálẹ̀ Covid 19 lẹ́ẹ̀kejì- Aarẹ Akufo Addo
- Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 181 pẹ̀lú Olùkọ́ lùgbàdì Covid 19 níléèwé aláàdáni kan nípinlẹ̀ Eko
- Wo ìmọràn tó lè jẹ kóo gbádùn ṣíṣe iṣẹ láti ilé lásìkò kónílé-ó-gbélé COVID 19 yìí
- Omicron: Kíni ìdí tí Nàìjíríà ṣe wà lára àwọn orílẹ̀-èdè tó léwu láti rírínàjò lágbàyé?
- Wàhálà ń bẹ ní Nàíjíríà bí wọn bá tún tako ọmọ onílùú láti wọlé - Soyinka
Ẹwẹ, awọn onimọ ijinlẹ ọhun ṣe kilọ kilọ pe eniyan ko gbọdọ gbe ara le eyi nikan amọ gbigba abẹrẹ ajẹsara lati dena Covid-19 ṣe koko.Bẹẹ ni wọn tun woye pe, iwadi yii le ṣe atọna si bi ara ṣe le gbaradi lati tako kokoro arun Coronavirus naa.Awọn Oluwadii yii tun sọ pe, o lewu lati lero pe eni to ba ti ni ọ̀fìnkìn ri, ti gba idaabobo ti yoo tako arun Covid 19.Bakan naa ni awọn oluwadii naa fi kun pe, awọn fẹ ni oye idi ti awọn kan fi n pada lugbadi arun Covid 19 lẹyin ti wọn ba ti ni arun naa lẹẹkan ri, amọ ti awọn miran kii gburo rẹ mọ.
- Mínísítà dèrò àgọ́ ọlọ́pàá nítorí ẹ̀sùn kíkó owó ìrànwọ́ Covid-19 sápò
- Wo orílẹ̀èdè tí ẹ̀dà Covid-19 tuntun Omicron rápálá wọ̀ l‘Áfíríkà
- Australia, New Zealand, Japan,àwọn orílẹ̀-èdè tó ti ṣáájú Nàìjíríà wọ ọdún 2022
- Wo ìdí tí Sanwo-Olu ṣe wọ́gilé ìrìn àláàfíà 'Walk for Peace' tó fẹ́ẹ̀ rìn pẹ̀lú àwọn ará Eko
- Wo ìdí tí ìjọba Najiria ṣe fẹ́ dáwọ́ gbígbà abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 dúró
Wọn wa doju iwadi wọn kọ ọkan gboogi lara awọn eroja to maa n gbogun ti arun lagọ ara, ti a mọ si T-Cells.Awọn T-Cells yIi lo maa n pa awọn sẹẹli ti awọn aisan bi ọ̀fìnkìn ba n ba finra lagọ ara.Ni kete ti otutu aya yii ba lọ tan, diẹ lara awọn T-cells yi ni yoo duro sinu agọ ara bii ọlọdẹ lati tete boju to irufẹ kokoro miran to ba fẹẹ yọju.








