Soyinka: Nàíjíríà sì ń dojúrú lọ, a sì ń wòran

Oríṣun àwòrán, Wole Soyinka
Agba Onkọwe nni, Ọjọgbọn Wole Soyinka ti tẹnu bọ ọrọ lori ohun toju rẹ ri lori ọrọ iwe kaadi moyege Covid-19 lasiko to n dari irinajo bọ.
Irinajo rẹ yii lati orileede France pada si Naijiria ja si pabo diẹ tan, nigba tawọn oṣiṣẹ ileesẹ ofurufu to fẹ wọ yari pe ko ni wọ baalu lai si iwe aṣẹ lati rinrin ajo lọ si Naijiria.
Nibi apero kan to waye nilu Eko lori akori Covid, Tekinọlọji ati riran eeyan lọ si ẹyin odi, lo ti jiroro pẹlu awọn akọroyin.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọwọ́ ọlọ́pàá Cotonou tẹ akọ̀royìn tó fi fọ́nran ohùn Sunday Igboho síta
- Obìrin tó ń ta omi inú ọ̀rá subú pẹ̀lú ọmọ lẹ́yìn torí ebi
- Ẹ ṣì mí gbọ́ ni, a nílò ìrànwọ́ àwọn ìjọba ìpinlẹ̀ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n - Aregbesola
- Wo orúkọ tuntun tí Facebook yóò má jẹ́ láti àkókò yíì lọ
- Wọ́n gbé ọmọ mi tó jẹ́ Babaláwo Sunday Igboho, a kò mọ ìrìn rẹ̀ láti oṣù mẹ́ta
- Ọkùnrin kan wọ gàù torí ọ̀rọ̀ tó fi ránṣẹ́ sí aya aláya lórí Whatsapp
- "Ẹlẹ́wọ̀n Abolongo pa méjì lára ọdẹ ìbílẹ̀ lásìkò tà ń ṣà wọ́n kiri ìgboro Oyo"
- Ìwà ìkà sí Yorùbá ni bí ìjọba ṣe ti bodè Seme láti 2019 - Gani Adams
O ni lootọ ni wọn ko ran oun lọ si ẹyin odi amọ inira to ba oun lasiko wakati mejidinlaadọta ti oun fi n sa soke sa silẹ, fẹẹ jọ bẹẹ.
Gbogbo awọn arinrinajo to ba n pada wa si Naijiria ni wọn gbọdọ fi iroyin nipa rẹ soju opo kan ti ijọba Naijiria ṣe idasilẹ rẹ.
Lara ohun ti ẹni naa yoo kọ sibẹ ni pasipọọti ati nọmba tikẹti rẹ.
Lẹyin to ba fi awọn ilana yii ṣọwọ, ni wọn yoo fun ni ami moyege nipa ohun taa n pe ni ''barcode'' eleyi to fi han pe o lanfaani lati tẹsiwaju pẹlu irinajo rẹ.
Onkọwe naa sọ nipa iriri rẹ, to si ni iṣẹlẹ airotẹlẹ ko le ṣe ko ma waye tori naa, idiwọ yi kii ṣe nkan ti eeyan le ri nkan ṣe si.
Amọ o ni ''bi wọn ba tako ọmọ onilu lati wọ ilu abinibi rẹ latari aṣiṣe awọn ẹlomiran, wahala wa ni yẹn''
Soyinka ni gbogbo abẹrẹ Covid-19 to yẹ koun gba loun gba ni gbedeke iye wakati ti ijọba la kalẹ 'sugbọn o jọ pe o ni abẹrẹ kan ti wọn pe ni PCR ti oun ko mọ nipa rẹ ''
O ni wahala aisi orukọ oun ninu oju opo ijọba yi mu fakinfa wa fọpọ wakati ti awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ ọkọ ofurufu naa si n lọ ti wọn n bọ lati le yanju ọrọ yi.
Ninu alaye rẹ, o ni o le debi pe oun beere boya baalu miran wa to n lọ si orileede mi ni Afrika ti wọn ko nilo lati ṣe iru ayẹwo yi.
Wọn fesi pada pe ọkan wa to n lọ si Lome ṣugbọn ki Soyinka to darapọ mọ baalu naa ni wọn b sọ fun pe wọn fun ni iyọnda nitori ipo rẹ lati tẹsiwaju.
Lori iyọnda yi, Soyinka sọ pe ''ko yẹ ki wọn maa wo ipo eeyan lati le jẹ ki o wọ ilẹ baba rẹ tori naa ki awọn eleto tọrọ kan wa nkan ṣe si idiwọ yi.'
''Ilana yi ti wọn tori rẹ dami duro ṣe eeyan ni kayeefi nitori awọn ibeere ti wọn n beere loju opo naa ko ni nkan ṣe pẹlu Covid-19.Bo ṣe ileesẹ ilera ni tabi eleyi to n ṣeto aabo labẹle, wọn ni lati yanju ọrọ yi''
O ni o to ki wọn sinmi lati maa foju tabi hu iwa si awọn ọmọ Naijiri lajo bi igba pe ọdaran ni wọn.


















