Covid 19 Palliative: Mínísítà dèrò àgọ́ ọlọ́pàá nítorí ẹ̀sùn kíkó owó ìrànwọ́ Covid-19 sápò

Coronavirus

Oríṣun àwòrán, NCDC/Twitter

Mínísítà dèrò àtìmọ́lé lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó lu owó ìrànwọ́ Covid-19 ní pónpó.

Minisita kan ti dero atimọle ni Indonesia lẹyin ti wọn fẹsun kan pe o gbọna ẹburu ji owo iranwọ Covid-19.

Wọn ti fi panpẹ ofin mu minisita to n ri si ọrọ awujọ ni Indonesia lẹyin ti wọn fẹsun kan pe o gba riba $1.2 miliọnu lori owo iranwọ ounjẹ fun awọn ti Covid-19 ṣakoba fun.

Wọn fẹsun kan Juliari Batubara lẹtin ti awọn ọlọpaa ṣawari orisiriṣi apo ti owo ọhun wa ni ikawọ rẹ.

Covid

Oríṣun àwòrán, others

Lẹyin naa lo lọ fa ara rẹ le ọlọpaa lọwọ, eyii to mu ko jẹ ẹni keji ti aje iwa ibaje yoo ṣi mọ lori ninu ijọba Aarẹ Joko Widodo laarin ọsẹ diẹ sira wọn.

Nigba to n sọrọ lori ẹsun ti wọn fi kan minisita naa, Aarẹ Widodo sọ pe oun ko ni bo aṣiri ẹnikẹni ti wọn ba ka iwa ibajẹ mọ lọwọ.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa: Mọ̀ síi nípa ìró afárànma àti agbárànmọ́ fáwẹ́ẹ̀lì Yorùbá

Ṣaaju ni eto ọrọ aje Indonesia ti dẹnu kọlẹ nitori ajakalẹ arun Covid-19 to n ba gbogbo agbeye finra.

Lara ẹsun ti wọn fi kan Batubara ni pe o gba owo to le ni miliọnu kan dollar lọwọ awọn agbaṣẹṣe meji ti ijọba gbeṣẹ fun lati pese ounjẹ fun awọn ti arun Covid-19 ṣakoba fun eto ọrọ aje wọn.

Wọn ni minisita naa n gba nnkan bii ẹgbẹrun mẹwaa owo orilẹ-ede ọhun lori ounjẹ ti eeyan kọkan n gba lati ọdọ ijọba.

To ba jẹbi ẹsun ti wọn kan, o ṣeeṣe ko lọ sọgba ẹwọn fun nnkan bii ogun ọdun tabi ko san biliọnu kan owo orilẹ-ede ọhun gẹgẹ bii owo itanran.

Àkọlé fídíò, Florence Onwuasoanya: Mo jẹ́ àsèjẹ, mo mu àgbo tí kò ṣe e fẹnu sọ kí ń lè gbé ọmọ jó ṣùgbọ