Ganduje: Gòmìna Ganduje ni yíyọ Sanusi nípò Emir Kano wà fún àtúnṣe ètò oyè jíjẹ ní ìlú Kano

Oríṣun àwòrán, Twitter/Maigaskiya
Gomina ipinlẹ Kano, Ganduje ti sọ pe oun ko kabamọ bi oun ṣe rọ Emir ilu Kano tẹlẹ, Sanusi Lamido Sanusi loye.
O ni tẹlẹ gan an kii ṣe Sanusi lo tọ si ipo naa, awọn alagbara ijọba nigba naa lo kan fi iyansipo rẹ ṣe ọna ati fi la aarẹ igba naa, Goodluck Jonathan loju.
- Òfin ìfipábánilòpọ̀ tuntun yóò fààye gba fífi kẹ́míkà tẹ ọkùnrin lọ́dàá
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Zamfara ti gbé iléèwé mẹ́wàá tìpa lkyìn tí wọ́n jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ iléèwé Kankara gbé
- Ṣé lọ́òtọ́ ni ọlọ́pàá dàwátì torí àti dóòlà ọmọ India méjì tí wọ́n jígbé?
- Wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ìpàdé àwọn èèkàn Yorùbá láti mú kẹ́ẹ dìbò fún Tinubu ní 2023
- Jide Kosoko forin sẹ́nu sọ pé òun ni igi lẹ́yìn ọgbà Mr Latin lórí ipò ààrẹ TAMPAN tó wà
Gomina Ganduje to sọrọ nibi ifilọlẹ iwe kan nipa aarẹ ana, Goodluck Jonathan ṣalaye kikun nipa iṣẹlẹ naa.
O ni wi pe lasiko ti wọn yan Sanusi Lamido Sanusi gẹgẹ bii Emi ilu Kano loṣu kẹfa, ọdun 2020, lẹyin oṣu meji ti aarẹ Jonathan yọọ nipo gomina banki apapọ Naijiria, oun mọ pe kii ṣe igbesẹ to tọ nigba naa.
O ni nikete ti oun di gomina loun ti sọ ọ fun ara oun pe oogun ti Jonathan lo lori ọrọ Sanusi ṣe pataki pupọ.
Ganduje ni aarẹ ana, Goodluck Jonathan gbe igbesẹ akin lati yọ Sanusi nipo gomina banki apapọ Naijiria nitootọ.
Bi o tilẹ jẹ pe o fa ẹtanu rẹ laarin awọn eeyan kan; sibẹ oun ri i gẹgẹ bi igbesẹ to tọ gẹgẹ bi oogun to yẹ ni lilo to dabi ọna abayọ lati wo wahala igba naa.
"Oogun naa, bi o tilẹ jẹ pe mi o kii ṣe dokita iṣegun oyinbo, oogun yii kan naa yoo wulo fun iṣẹ kan naa, arun kan naa ati fun eeyan kan naa.
Ganduje ni: "Nitori naa mo gbe igbesẹ oogun ti Jonathan gbe lati doola ilana ati eto Ọba jijẹ ni Kano, mo si lo o daadaa.
Fun idi eyi. igun kan naa lemi ati aarẹ ana, Jonathan wa.
Ẹ wo o, emi ko kabamọ rara nitori pe mo yọ Sanusi loye Emir ti Kano"
Lasiko iṣejọba Rabiu Kwankwaso gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Kano ni wọn fi Sanusi Lamido Sanusi joye Ẹmir ilu Kano ṣugbọn ni ọjọ Kẹsan an oṣu kẹta ọdun 2020 ni wọn rọọ loye.
- Ìyàwó mi fi mí sílẹ̀ kó lọ sílé ọkùnrin míì nínú báráàkì kan náà, àmọ́ mò sí tún fẹ́ràn rẹ̀- Sọ́jà
- Wo àwọn ìṣesí ojoojúmọ́ mẹ́wàá tó le ṣàkóbá fún ọpọlọ rẹ
- Coronavirus: ''Ìjọba kò tíì pàṣẹ ìlànà ìtakété-síra-ẹni padà nínú BRT la ò ṣe máa tẹ̀le''
- Wo àwọn Adelé-Ọba aládé méje tó jẹ́ obìnrin nílẹ̀ Yorùbá
- Ṣé lóòtọ́ ni Adajọ́ Àgbà Naijiria, Tanko Muhammad ti ní Covid-19?






















