Aisha Buhari, Dubai trip: Ṣé lóòtọ́ ni pé Aisha Buhari ti kó lọ sí Dubai? Ẹ wo òtítọ́ ọ̀rọ̀ nàá

Oríṣun àwòrán, Instagram/@Aishambuhari
Ọpọlọpọ eeyan lo ti n ṣe ariyanjiyan lori ayelujara Twitter ati awọn oju opo ayelujara ibaraẹnidọrẹ mii lori pe ṣe lootọ ni aya aarẹ, Aisha Buhari ko gbe ni Naijiria mọ?
Awuyewuye bẹrẹ lẹyin ti iwe iroyin Sahara Reporters, sọ pe ilu Dubai ni Aisha fi ṣe ibugbe bayii "nitori pe ko si aabo fun un ni ile ijọ Aso Rock'.
Iroyin sọ pe lati igba ti ọmọ rẹ Hanan ti ṣe igbeyawo, ni Aisha Buhari ti kuro ni Naijiria.
Eyi si mu ki ọpọlọpọ o ma a sọ pe ko si idi ti awọn ko fi gbọdọ salọ kuro ni Naijiria, ti iyawo aarẹ ba le ṣe bẹ ẹ.
- Ọmọ Ààrẹ lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ìgbéyàwó yálà àwọn ará ìlú fẹ́ràn ìjọba bàbá rẹ̀ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́ - Aisha Buhari
- Ǹjẹ́ ọmọ Buhari lásẹ láti wọ Ọkọ̀ òfúrufú Nigeria Air force lọ sí òde?
- Bí mo ṣe mórí bọ́ nínú ọkọ̀ bàálù tí kò bá já - Aisha Buhari
- Yusuf Buhari pada de lẹyin itọju lẹyin odi
- Mo sọ̀rọ̀ tako ọkọ mi torí òtítọ́ - aya Bùhárí
Otitọ to wa ninu ọrọ naa ree:
Oṣu Kẹsan-an ni Sahara Reporters sọ pe Aisha ti kuro ni Naijiria, ṣugbọn eyi kii ṣe otitọ rara.
Idi ni pe ni ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, to jẹ ayẹyẹ ọgọta ọdun ti Naijiria gba ominira, aṣọ to jẹ awọ kan naa pẹlu asia Naijiria lo wọ.
To si tun kopa nibi ayẹyẹ naa to waye nilu Abuja.

Oríṣun àwòrán, Twitter/@aishambuhari
Tako iroyin ti awọn ileeṣẹ iroyin kan gbe jade, iwadii ti BBC ṣe fihan pe lootọ ni iyawo aarẹ pada si ilu Dubai, ṣugbọn kii ṣe lati ma a gbe ibẹ.
O lọ fun eto ilera ara rẹ ni.
Ṣugbọn ṣa, ẹni to sọ ọrọ naa fun BBC nileeṣẹ aarẹ, ko sọ asiko ti aya aarẹ yoo pada sile.
Lasiko itankalẹ aarun Covid-19 , Aisha lọ si ilu Dubai fun itọju, to si jẹ pe igba to n pada bọ si Naijiria ni baalu ijọba to wa ninu rẹ ni ijamba.
- Jide Kosoko forin sẹ́nu sọ pé òun ni igi lẹ́yìn ọgbà Mr Latin lórí ipò ààrẹ TAMPAN tó wà
- Ìyàwó mi fi mí sílẹ̀ kó lọ sílé ọkùnrin míì nínú báráàkì kan náà, àmọ́ mò sí tún fẹ́ràn rẹ̀- Sọ́jà
- Wo àwọn ìṣesí ojoojúmọ́ mẹ́wàá tó le ṣàkóbá fún ọpọlọ rẹ
- Coronavirus: ''Ìjọba kò tíì pàṣẹ ìlànà ìtakété-síra-ẹni padà nínú BRT la ò ṣe máa tẹ̀le''
- Ìjọba gbé ilé ijó oníhòhò tì pa lórí ẹ̀sùn títàpá sí ìlànà àti dẹ́kun coronavirus



















