New Year 2022: Wo àwọn orílẹ̀-èdè tó ti ṣáájú Nàìjíríà wọ ọdún 2022

Australia

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi Naijiria ṣe n palẹmọ dun 2022, awọn orileede mii lagbaye ti n ki kaabọ

Amọ ṣa ofin idena to wa nil lawọn orileede kan ko j ki afẹfẹyẹyẹ dun pọ to ti tatyinwa.

Lawọn ibo mii, niṣe lawọn eeyan n figbe ''A ku ọdun '' ta ti wọn si jojo ayọ.

2px presentational grey line
Wọn tan abẹla ni Japan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni Japan, wọn tan ina abẹla 6,500 ni tẹmpili Hasedera awọn ẹlẹsin Budha to wa ni Kamakura.

Wọn fi ọrọ ikini ku dun ranṣẹ pẹlu rẹ si awọn eeyan ilẹ naa ati agbaye lati le bori ipenija ajakalẹ to gbode kan

China ko ṣe afẹfẹyẹyẹ ọdun pupọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Botil jẹ wi pe ọdun tuntun China ko ni waye titi di ọjọ Kini oṣu Keji, nilu Hangzhou wọn tan ina orisirisi lati fi ki 2022 kaabọ.

Pupọ awọn ayẹyẹ ọdun ti wọn la kalẹ ni wọn ti wọgile nitori ajakalẹ Coronavirus.

South Korea

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni olu ilu South Korea,Seoul, ayẹyẹ ọdun ko pọ lọ titi nitori ofin iṣede to bẹrẹ laago mẹsan alẹ.

Ṣugbọn wọn tan ina lati ori ile alaja mẹtalelọgọfa Lotte World Tower ti imọlẹ rẹ si gba oju sanmọ

Thailand

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bakan naa ni Thailand, ọpọ eeyan lo tan ina meremere ni olu ilu ilẹ naa Bangkok.

Aworan lati Sydney bi ọdun ṣe n lọ

Oríṣun àwòrán, EPA

Australia naa ko ṣe ayẹyẹ pupọ nitori ẹda Covid-19 Omicron to n ja rainrain kaakiri.

Ilu Sydney ti ọpọ mọ pẹlu ina ati awọn nkan meremere ti wọn maa n tan soju ọrun ṣe bi wọn ti ṣe maa n ṣe.

A light show from di Skytower and harbour bridge will see in New Year in Auckland, New Zealand

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni New Zealand wọn ṣeto lati tan ina sori afara Auckland Harbour dipo ina ti wọn maa n tan soju ọrun lọdọọdun.

Àkọlé fídíò, Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ abàmì àti Kàyéfì tó wáyé lọ́dún 2021 rèé nínú fídíò
2px presentational grey line

Awọn ilu ti ayẹyẹ ọdun 2022 ko ni la ariwo lọ

York Minister

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Agogo ti wọn maa n lu ni York Minister ni ilẹ Gẹẹsi pa lọọlọ ni ti wọn ko si kede aisun ọdun tuntun fun igba keji lera.

Ṣaaju Covid-19 ọpọ lo maa n peju siwaju ile yi lati ki ọdun tuntun kaabọ.

Amọ awọn oṣiṣẹ York Minisiter sọ pe lọdun yi ko ni si ipolongo kankan nitori ẹda Covid-19 Omicron

.

Oríṣun àwòrán, PA Media

Gbogbo awọn agbegbe to wa ni Edinburgh England wọgile gbogbo ayẹyẹ ọdun.

Gbogbo iwgile yi ko si sẹyin ajakalẹ Covid-19.

Hogmanay

Oríṣun àwòrán, Getty Images

London ati Paris wọgile ayẹyẹ aisun ọdun.