2021 roundup Nigerian Celebrities Scandal: Wo àwọn Sẹlẹ́bírítì fíìmù àti Olórin Yorùbá tí ọ̀rọ̀ ìbálòpọ̀ wọ́n àti ìṣẹ̀lẹ̀ míì dagbro rú lọ́dún 2021

Awọn gbajugbaja

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ninu ọdun 2021, ọpọlọpọ iṣẹlẹ lo ti gbode kan to fun awọn ọmọ Naijiria ni ayọ. Ọrọ bii ija tabi akoba tabi aawọ laarin awọn gbajugbaja oṣere ati olorin si wa lara ohun ti awọn ọmọ Naijiria ma n fi ṣe ara rindin.

Wahala ati ija laarin awọn oṣere ati olorin yii tilẹ gba ipo mọ awọn iroyin bii oṣelu, iṣejọba, ofin orilede lọwọ daadaa lookan aya ọpọ ọmọ Naijiria.

Bo tilẹ jẹ pe omii iṣẹlẹ yii, ibanujẹ lo jẹ si ẹni to n ṣẹlẹ si tabi ohun to lee pa a tabi iṣẹ ati orukọ nla rẹ lara, awọn nkan wọnyii naa lo n mu agbo oṣere/olorin gba yuun si awọn ololufẹ wọn.

Àkọlé fídíò, Prophet Hezekiah New Year Prayer: Gbogbo wa ni ká ṣiṣẹ́ fún ìdàgbàsókè Naijiria

Lai fẹju wo ọpọlọpọ ọdun sẹyin, ọdun to n kasẹ nilẹ yii nikan gan kun fun ọpọlọpọ ohun tawọn eeyan ri bii fiimu yala ija ni tabi iṣẹlẹ tabi iwa aidaa laarin awọn oṣere.

BBC Yoruba ṣe akojọpọ lara pupọ awọn oṣere ati olorin ti nu ko ṣi lori wọn lọdun titi orukọ wọn fi de ori google.

Baba Ijesha

Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, other

Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, Olanrewaju Omiyinka ti ọpọ mọ si Baba Ijesha ṣi wa lọwọ ile ẹjọ ti ko tii mọ ohun ti yoo gbẹyin ẹsun ṣiṣe ọmọdebinrin baṣubaṣu eyi to jẹ ọmọ ti akẹgbẹ rẹ, Princess Comedian gba tọ.

Nigba ti ọrọ yii bẹrẹ gangan, lọjọ ti wọn fi ọlọpaa mu Baba Ijesha, ṣe ni Princess ṣe fidio to n wa ẹkun mu pe Baba Ijesha akẹgbẹ to tun jẹ ọrẹ timọ timọ oun ṣe iru aburu yii si oun labẹ igi imu oun.

Iroyin iṣẹlẹ yii ti tan kaakiri orilẹede Naijiria koda o ti de awọn ilu oyinbo ti awọn oṣere mii gan ti ja lori rẹ.

Àkọlé fídíò, Ṣé o mọ̀ ipò tí ìlú Owo l'Ondo ní lórí ìtẹ́ Ile Ife? Ẹ kálọ sí ìlú mi
Aworan Princess ati Baba Ijesha

Oríṣun àwòrán, other

Lara awọn to gbe ọrọ yii sori ati awọn mii to da sii to si n da ija silẹ laarin wọn ni Yomi Fabiyi, Iyabo Ojo, Damola Olatunji, Mama Rainbow, Nkechi Blessing, Olofa Ina, Mr Latin, Elesho ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ko to di igba ti wọn fi ofin gbe e fun sun ifipa ba ọmọde lopọ, oṣere ko fi bẹẹ tii moke pẹlu bo ṣe ti pẹ lagbo naa amọ kete ti ọwọ ofin tẹ ẹ, o di ilumọọka bo tilẹ jẹ pe fun nkan aburu ni.

Àkọlé fídíò, Baba Ijesha Rape Case: Yomi Fabiyi ní òun nìkàn lòun rí ara òun tó dúró tí Baba Ijesha

Toyin Abraham Vs Lizzy Anjorin lori ọrọ ọmọ

Toyin Lizzy Anjorin ati Abraham

Oríṣun àwòrán, @trafficwaka

Ija o ki mi ku ewu ọmọ oo ki mi ku ewu ọmọ ti n rugbo laarin gbajugbaja oṣere meji, Lizzy Anjorin ati Toyin Abraham amọ eyi to gbẹyin ju ni igba ti gbajugbaja sọrọ sọrọ ori ayelujara ESABOD pe awọn mejeji lori ẹrọ Zoom lati ba wọn pari ija.

Ọrọ naa fẹ loju gidi to bẹẹ ti epe n jade lori eto ilaja ọhun lẹnu ẹnikan, bakan naa ni fifi iwe mimọ bura tu yọju latọdọ ẹnikeji.

Lizzy Anjorin ni Toyin Abraham ko ki oun ku ewu nigba toun bimọ to si jẹ pe oun ki i nigba tirẹ. Igba tirẹ to n s yii ni ija nla kan burẹkẹ ni eyi ti Lizzy Anjorin n gbe iroyin kiri pe ile alagbo kan ni Toyin lọ bimọ si kii ẹ họsibitu awọn oyinbo ti wọn n gbe fidio rẹ jade.

Asẹyinwa asẹyinbọ, nipasẹ Ether Aboderin ti ọpọ mọ si ESABOD ti ọpọ awọn oṣere si bọwọ fun, wọn ni wọn ti ri ija ọhun pari.

Lẹyin eyi ni Toyin tun n wi lelẹ pe, oun ko lọwọ tabi mọ ohunkohun nipa bi ẹnikẹni to ba ni oun n gbeja oun, se n bu ẹnikẹni.

Toyin ni ki wọn mase di ẹbi kankan ru oun ti ẹni to n gbeja oun ba n sepe tabi se ẹẹkẹ eebu.

"Mo ri awọn fidio kan lori ayelujara ninu eyi ti awọn eeyan kan ti wọn ni awọn n gbeja mi ti n sẹ epe fawọn eeyan miran.

Àkọlé fídíò, Orí Tẹlifísàn ni mo ti rí Sunday Igboho rí láyé mi, bí ìyà ṣe jẹ mi gbé láti Ibadan, dé Àtìmọ́lé DSS rèé - Ifasooto Dada

ESABOD ati oṣere Mr. Portable

Lẹyin ti gbajugbaja sọrọ sọrọ pe awọn agba oṣere kan lati sọrọ si wọn lori bi nkan ṣe n daru lagbo oṣere nigba aye wn ni oṣere Mr Portable ba gbana jẹ to si n sọ oko ọrọ sii.

Mr Portable ati ESABOD

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Àkọlé fídíò, Esabod, Sunday Igboho: Kò burú bí Igboho ṣe wà lẹ́wọ̀n báyìí,ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí i ti aláboyún
Àkọlé fídíò, Kemi Olunloyo on Sunday Igboho: Mi ò gbè lẹ́yìn Yoruba Nation àmọ́ mo wà lẹ́yìn Sunday Igb

Fiimu Ọkọ Iyabo - Yomi Fabiyi vs Iyabo Ojo

Iyabo Ojo ati Yomi Fabiyi

Oríṣun àwòrán, Instagram/Iyabo Ojo

Ẹsun Baba Ijesha yii burẹkẹ debi pe oṣere to n gbaruku ti Baba Ijesha ninu ẹjọ yii, Yomi Fabiyi gbe sinima kan jade lẹyin ọpọlọpọ ija ori ayelujara ti oun ati akẹgbẹ rẹ Iyabo Ojo ti jọ ja.

Yomi pe sinima ọhun ni ọkọ Iyabo to si tun jẹ ki ọkan lara abala ere naa ṣafihan iru ẹsun ti Baba Ijesha n jẹjọ le lori lọwọlọwọ. Eyi ni awọn akẹgbẹ rẹ mii tun gbana jẹ le lori ti wọn si n da si ọrọ naa.

Nibayii, ko da bii pe ẹjọ naa ti wọn tun tu sun siwaju di ọjọ kejilelogun oṣu kini ọdun 2022 yoo tete pari tori ọrọ ṣi wa nilẹ lori ẹ.

Fọnran fidio ibalopọ Tiwa Savage lu sita, ọgbọ́n tó fi ká a kúrò nílẹ̀ rèé

Tiwa Savage

Oríṣun àwòrán, Tiwa Savage

Gbajugbaja Olorin takasufe to si jẹ ọmọ Yoruba, Tiwatope Savage ya awọn eeyan lẹnu ninu oṣu kẹwa ọdun yii nigba to sọrọ nipa awọn kan to fẹ ba a lorukọ jẹ ti wọn ni fidio ibalopọ rẹ kan lọwọ.

Ọrọ naa dabi ere ṣugbọn nigba ti fọnran fidio naa yoo fi lu sita, awọn eeyan mọ pe lootọ ni.

Gbajugbaja akọrin takasufe Tiwa Savage ni eeyan kan n dunkoko mọ pe oun yoo lu fidio ibalopọ rẹ sita ti ko ba fun oun lowo.

Tiwa ni ko ṣe oun to ba wu afi bi ẹni naa si ṣe fi fidio ibalopọ Tiwa ati ọrẹkunrin rẹ sita.

Ọrọ yi da awuyewuye silẹ ti awọn kan si ni o da bi ko ṣe san owo fun ẹni naa.

Awọn to n ba Tiwa da owo pọ kan taa mọ si sponsors yọwọ kuro ninu ibaṣepọ pẹlu akọrin yi nitori fọnran fidio naa.

Ẹwẹ, fun Tiwa, asiko yii tun jẹ eyi to lo lati fi die goke sii ni ti ifẹ rẹ tun pọ sii lọkan awọn eeyan. O gbe orin kan jade ti gbogbo eeyan si bẹrẹ si ni kọ ọ lẹnu kaakiri agbaye eyi ti akọle rẹ n jẹ "Sombody son".

Pẹlu eyi, o la asiko laalaa tirẹ kọja o si ti ka kuro nilẹ bayii.

Emmanuella to f Kwam1: Awuyewuye pe o ti fẹ awọn Ọba nla nla kan ri

Iroyin sọ pe ninu oṣu Kọkanla ni Wasiu ati Emmanuella yoo ṣe igbeyawo wọn

Oríṣun àwòrán, Wasiu ayinde/instagram

Àkọlé àwòrán, Iroyin sọ pe ninu oṣu Kọkanla ni Wasiu ati Emmanuella yoo ṣe igbeyawo wọn

Ni bii oṣu diẹ sẹyin ni iroyin igbeyawo gbajumọ olorin Kwam1 gba ori ayelujara kan gẹgẹ bo ṣe fẹ arẹwa apọnbeporẹ kan, to n jẹ Emmanuella Ropo.

Lati bi oṣu melo kan ni iroyin ti n lọ kaakiri lori ayelujara pe K1 tun ti fẹ iyawo miran.

Ọdun 2018 ni ariwo igbeyawo rẹ kan jade sinu iroyin, lasiko to fẹ gbajumọ oniṣowo aṣọ nilu Eko, Fathia Opeyemi ti awọn eeyan tun mọ si Titi Marshal bayii.

Ọmọ mẹta lo wa laarin wọn. Wọn si ti bi awọn ọmọ yii ko to o di pe wọn ṣe igbeyawo wọn.

Ni bayii, agogo igbeyawo ti dun laarin olorin naa ati ọmọ ẹlẹ kan, Emmanuella Ropo.

Igbeyawo Kwam1 waye niluu Abeokuta pẹlu apọnbeporẹ arẹwa obinrin, Aderopo Emmanuella ti gbogbo ilu si mi titi.

Ropo jẹ ẹni to ti le ni Ogoji ọdun lọjọ ori nigba ti Wasiu Ayinde jẹ ẹni ọdun mẹrinlelọgọta to si ti ni ọmọ to le ni ogoji latọdọ ọpọlọpọ obinrin.

Amọ lasiko igbeyawo wọn lawọn iroyin tun lu jade pe Emmanuella yii ti kọkọ fẹ Ooni ti Ile Ife ri koda wọn tun so ọrọ fifẹ eeyan kiri rẹ mọ Ọba Olugbon ti Igbo ni ipinlẹ Ondo.

Bobrisky ati amugbalẹgbẹ rẹ funra wọn loyun?

Bobrisky

Oríṣun àwòrán, @bobrisky

Àkọlé àwòrán, Mó fẹ́ dí obinrin to dára júlọ lágbàyé-Bobrisky

Ni nkan bii oṣu melo syin ni amugbalẹgbẹ gbajugbaja amura bi obinrin amọ to jẹ ẹda ọkunrin Idrees Okuneye (Bobrisky) kigbe sita pe oun ti loyun fun un eyi to sigba gbogbo ori ayelujara kan.

Oye Kyme to jẹ amugbalẹgbẹ rẹ tẹlẹ yii ti awọn oloyinbo n pe ni P.A tun pada sori ayelujara lati s pe ko ri bẹẹ mọ, oun ko loyun fun Bobrisky.

Ṣaaju eleyi si ni Oye fi fọto ara rẹ sita to fi ikun rẹ han to si jọ pe o loyun gẹgẹ bo ṣe sọ ọ to n ni ki awọn ololufẹ oun ro ẹni ti oun loyun fun.

Bobrisky fariga gidi gan lori ọrọ yii to si bọ sori ayelujara.

Nigba to ya ni Oye bọ soju opo instagram rẹ to si tọrọ aforijin lọwọ awọn ololufẹ rẹ pe oun ko ni mu wọn lẹgan mọ.

Awọn ọrọ mii to tun lọ mọ Bobrisky lẹsẹ ni asiko ti iroyin kan lu jade pe oun ati gbajumọ olowo Mompha n fẹ ara wọn gẹgẹ bi ọkunrin si ọkunrin eyi ti Mompha naa si ṣe fidio jade to ti n fi ibinu rẹ han gidi gan si iroyin yii.

Ṣe lootọ ni Odunlade Adekola n ba awọn obinrin to n kọ niṣẹ lopọ?

Odunlade ati Eniola Ajao

Oríṣun àwòrán, Odunlade Adekola

Odunlade vs ẹgbẹ ẹlẹsin Islam THURIST

Ohun to ṣaaju iroyin yii pe o n ba awọn kan lopọ gangan tohun naa jẹ wahala ki wahala mii to tun suyọ fun gbajugbaja oṣere, Odunlade Adekola ni pe o ṣe fiimu kan jade to tabuku ẹsin Islam.

Ọrọ naa di ranto ti ẹgbẹ kan to n ja fun ẹtọ ẹsin Islam ni ko yẹ ki Odunlade jẹ ki obinrin kan wọ ibori Hijab lati fi ko ipa buruku ninu fiimu rẹ amọ igba to ya ni wọn mọ pe kii ṣe Odunlade gan lo gbe fiimu ọhun jade. Ọrọ naa si pada sẹrẹ.

Ẹwẹ, omii wu jade to si mu Odunlade ni dandan lati wa ṣe fidio kan jade pe irọ nla ni o, oun ki n yẹ iṣẹ awọn ọmọ abẹ oun wo.

Awọn eeyan gbe iroyin kiri pe ọpọlọpọ awọn obirin ti Odunlade kọ niṣẹ koda ti awọn naa ti di gbajugbaja ni o maa n ba lopọ. Wn fa orukọ Eniola Ajao titi titi, ko sọrọ.

Amọ Odunlade ṣe fidio kan jade lati bu ẹnu at lu iroyin naa.

Adedimeji Lateef ati Adebimpe loyun tabi bẹẹ kọ ko to gbeyawo?

Lateef ati Adebimpe

Oríṣun àwòrán, LAteef Adedimeji

Yala eyi jẹ ootọ tabi ko jẹ bẹẹ́, Lateef ati Adebimpe ti di alarede bayii ti wọn si ti so yigi.

Ọpọlọpọ iroyin lo jade nipa ibaṣep laarin awọn mejeji yii lori boya wọn n fẹ ara wọn tabi wọn ko fẹ ara wọn ti awn naa si tan gbogbo ololufẹ wọn daadaa fun o le ni ọdun kan.

Eleyi pada di mọliki lara awọn ololufẹ wọn bo tilẹ jẹ pe awọn mii n ja lori nitori ọrọ yii.

Eyi to tun burẹkẹ ni pe iroyin jade pe, gbajugbaja oṣerebinrin, Adebimpe Oyebade ti loyun, ti ọpọ eeyan si n sọ pe akẹẹgbẹ rẹ, Lateef Adedimeji ni ọkọ rẹ to loyun fun.

Ṣugbọn nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori eto kan ta se fun un, Adebimpe sọ pe iṣu Ọlọrun ti ko ṣe e fi ọwọ bo ni ọrọ oyun nini, ati ọrọ ọkọ.