Princess Comedian: Kí ló mú Princess Comedian máa wa ẹkún mu láàrọ̀ kùtù?

Oríṣun àwòrán, princesscomedian
Ohun to le mu ki agbalagba dede sun ẹkun arokan jade kọjaa keeyan ni o n ṣe ere ni.
Gbajugbaja adẹrin poṣonu, Princess Damilola, ti ọpọ mọ si Princess Comedian lo dede bẹrẹ si n wa ẹkun mu nitori eto kan to n mura lati ṣe laipẹ yii.
Ninu fidio kan to fi lede loju opo Instagram rẹ lo ti n sun ẹkun pẹlu ipaya lori bii eto kan yoo ṣe lọ.
Gẹgẹ bii ohun ti Princess sọ, awọn ọrẹ rẹ to n wo bii alatilẹyin ja a kulẹ lasiko to n mura fun eto adẹrinposonu naa.
- Ẹ yéé gbé ìròyìn òfegè kiri nípa olóògbé Femi Osibona, ó ṣèlérí N25M fún ìjọ mi àmọ́... - Genesis
- Wo ohun tí ọkọ àti ìyàwó, Lateef Adedimeji àti Bimpe fi síta fúnra wọn to fihàn pé ọjọ́ ti súnmọ́
- Ta ló gún obìnrin yìí pa lẹ́yìn ọdún mẹ́ta tí wọ́n gún ọmọ rẹ̀ pa nílé kan náà l'Ondo?
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ olórí pátápátá fún àwọn ajínigbé kan l'Ekiti
- Ayé òò! Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ́ẹ̀rẹ̀ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n jóná mọ́ yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọn fi igi àti koríko kọ́
- Ajínigbé ń bèèrè N10m, "Codiene", igbó àtí oúnjẹ fún ìtúsílẹ̀ èèyàn mẹ́ta tí wọ́n gbé l'Ogun
- Ṣé lóòtọ́ ni Lateef Adedimeji àti Bimpe Oyebade fẹ́ ṣègbéyàwó lọ́tẹ̀ yìí lóòtọ́? Lateef bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀
- 'Ọba Yorùbá kìí ṣe aláṣẹ ìkejì Orìṣà mọ́ látòní lọ! Krìstẹ́nì, Mùsùlùmí àti Àbáláyé yóò máa ṣe ayẹyẹ pọ látòní'
Princess ni "Mi o le sun, idi rẹe ti mo ṣe n gbe fidio yii sita fun awọn eeyan kan."
"Ọjọ marun un si asiko yii ni eto apanilẹrin ti mo fẹ ṣe yoo waye ṣugbọn awọn ti mo lero pe yoo ba mi polongo eto naa ko ri temi ro."
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
"Gbogbo awọn ti mo n reti ki wọn kede eto naa loju opo wọn ko ṣe ohunkohun nipa rẹ."
Lara awọn eeyan ti Princess darukọ ni adari eto Gbenga Adeyinka, Iledare Olajunwonlo, ti ọpọ eeyan mọ si Jaywon, Julius Agu, Alibaba, eti bẹẹ bẹẹ.
Pẹlu ibanujẹ ọkan ni Princess fi darukọ awọn eeyan ọhun to si sọ pe "Awọn bii Tee A ati Gbenga Adeyinka to maa n ki mi laya pe ki n tẹsiwaju ninu iṣẹ apanilẹrin ko tilẹ sọrọ kankan lori eto naa loju opo wọn."
O fi kun pe awọn eeyan gan ti yoo kopa ninu eto naa ko tilẹ fi ipolowo rẹ sita soju opo wọn.
Princess ni eto naa yoo waye, yala wọn sọrọ nipa rẹ ni o tabi wọn kọ.
Lẹyin naa lo bu ṣekun, to si sọ pe oun n saaro ọrẹ oun to di oloogbe laarin ọdun yii, iyẹn olorin takasufe, Sound Sultan.
Bi ẹ ko ba gbagbe, Princess yii lo pe Olanrewaju Omidina, Baba Ijesha lẹjọ lori ẹsun pe o fi ipa ba ọmọ oun lopọ.
Ẹjọ naa ṣi n lọ lọwọ nile ẹjọ to giga to wa ni Ikeja, niluu Eko.

















