Woman kiiled three years after daughter: Bàbá ọmọ obìnrin tí wọ́n gún l'Akure sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀

Yemisi Ajayi

Oríṣun àwòrán, naijanews

Awọn mọlẹbi obinri ti wọn gun pa niluu Akure lẹyin ọdun mẹta ti wọn ti kọkọ gun ọmọ rẹ naa pa ti ṣalaye bi iku rẹ ṣe ri lara awọn wọn.

Lara awọn mọlẹbi oloogbe ọhun ti BBC ba sọrọ ni ọkọ to n fẹ tẹlẹ, iyẹn Oloye Ajila.

Ajila ṣalaye fun BBC pe iroyin iku obinrin naa ba oun lojiji, o si jẹ kayeefi fun oun pẹlu.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, o ni "Mo kigbe AH! Ki ni obinrin yii ṣe ti wọn fi ṣe irufẹ ikọlu bayii si?"

Okunrin naa ṣalaye fun BBC pe bo tilẹ jẹ pe o ti le ni ọdun mẹrin ti awọn mejeji ti pinya gẹgẹ bii lọkọ-laya, ọmọ kan ṣoṣo ti obinrin ọhun bi fun oun ni awọn kan ṣeku lọdun mẹta sẹyin.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ija wa laarin wọn gẹgẹ bii lọkọ-laya, awọ si ti pinyan, eredi ree ti awọn mejeji ko ṣe tii ri ara wọn soju lati ọpọ ọdun sẹyin.

O ni "O bi ọmọ kan ṣoṣo fun mi, ọmọ naa si ni awọn kan pa ni nnkan bii ọdun mẹta ṣeyin, koda ile mi ni wọn sin ọmọ naa si, amọ a ko tii foju kan ara wa titi ti iṣẹlẹ yii fi waye."

Àkọlé fídíò, 'Ẹ yé tan ara yín, èmi mo ni aṣọ 100 yard tó jábọ́ lát'ọ̀run táwọn ará Ondo ń ya mọ́ ara wọn lọ́wọ́'

Ara ile obinrin naa miran ti BBC tun kan si lori iṣẹlẹ ọhun, Muyide Kayode sọ pe irufẹ ọna ti wọn fi pa ọmọ obinrin naa lọdun mẹta sẹyin ni wọn fi tun fi iya rẹ pa bayii.

Kayode ni eeyan daadaa ni obinrin naa jẹ ko to jade laye.

Ki ni ọlọpaa sọ?

BBC Yoruba tun kan si Funmilayo Odunlami, to jẹ agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Odunlami ni iwadii ti bẹrẹ, awọn yoo si fi atẹjade sita laipẹ.

O ni "A ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ṣugbọn iwadii n lọ lọwọ."

"Ṣe ẹ mọ pe o loju ọrọ ti a le sọ sita nipa irufẹ iṣẹlẹ bayii ki ohun ti a ba sọ ma ba di iwadii wa lọwọ."

"Ṣugbọn a ti gbọ, a si ti bẹrẹ iwadi lori iṣẹlẹ naa."

Ki lot ti ṣẹlẹ ṣeyin?

Ta ló gún obìnrin yìí pa lẹ́yìn ọdún mẹ́ta tí wọ́n gún ọmọ rẹ̀ pa nílé kan náà l'Ondo?

Mother of one stabbed to death three years after her only daughter was murdered

Oríṣun àwòrán, Daily Post

Wọn ti ṣekupa obinrin kan, Yemisi Ajayi, niluu Akure, lẹyin ọdun mẹta ti awọn eeyan kan gun ọmọ rẹ obinrin pa.

Wọn gun obinrin naa pa nile rẹ to wa ni Abusoro, lagbegbe Ijọka Road, niluu Akure.

Gẹgẹ bii ohun ti awọn oṣojumikoro sọ, igba marun un ni wọn gun obinrin naa ni ikun lori ibusun rẹ.

Àkọlé fídíò, Bí mo ṣe káa sára tí mo gbé òkú ọmọ sínú ọkọ̀ lọ ṣe iṣẹ́ apanilẹ́rìín láì fihàn - Woli Agba Ayo Ajewole

Ṣaaju lọdun 2018 ni awọn kan ti kọkọ gun ọmọ rẹ obinrin to jẹ ẹni ogun ọdun, Oluwaseun Ajila "Fiona" pa nile yii kan naa.

Titi di akoko yii, ko si ṣeni to le sọ awọn to wa nidii iṣẹlẹ iku ọmọ obinrin ọhun ki wọn to tun gun oun naa pa.

Ọkan lara awọn oṣojumikoro ọhun, ti ko fẹ ki a fi orukọ oun lede sọ pe ọkan lara awọn olugbe ile obinrin naa lo ke gbajare sita ki wọn to ri oku rẹ ninu agbara ẹjẹ.

O ni "Ọmọde naa ṣalaye fun awọn eeyan pe oun n wa iya oun lẹyin ti oun ji tan, ki le wọn jọ gbadura papọ, amọ ko ri iya rẹ ọhun."

Àkọlé fídíò, Wòólì Alfred kú lọ́dún 1964, ó tún padà wà sí ìlú Agelu f'ọ́jọ́ mẹ́rìnlá!

"Ko pẹ si akoko yii to ri oku iya rẹ naa ninu iyara, ti awọn awọn to ṣiṣẹ ibi naa si ti da aṣọ bo oku rẹ nibi yo wa."

Oṣojumikoro naa tẹsiwaju pe "Nigba ti mo de ibẹ lonii, ni ṣe ni mo bu sẹkun ki n to ke si awọn eeyan to wa layika."

Ẹlomiran to ba awọn akọroyin sọrọ ni iṣẹlẹ naa ba oun ninu jẹ gidi gan nitori ọdun mẹta sẹyin ni awọn kọlọrọsi kan ti kọkọ pa ọmọ rẹ obinrin ninu ile yii kan naa.

Nigba ti BBC Yoruba kan si alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami, o fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.

Odunlami fi kun un pe iwadii ti bẹrẹ lati mọ ohun to ṣokunfa ipaniyan naa.