Malala Yousafzai kúrò lẹ́gbẹ́ àwọn omidan, o ṣe nikkah nílùú Birmingham

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajafẹtọ ọmọniyan, to tun gba ami ẹyẹ "Noble Prize," Malala Yousafzai ti ṣe igbeyawo pẹlu ololufẹ rẹ niluu Birmingham.
Malala ati ololufẹ rẹ, Asser Malik ṣe nikkah wọn nibi ti wọn ti so awọn mejeji pọ ni ilana ẹsin Musulumi.
Ẹni ọdun mẹrinlelogun naa sọ pe ọjọ igbeyawo ọhun jẹ ọjọ manigbagbe ninu igbe aye oun.
Lọdun 2017 ni Malala wa si orilẹede Naijiria lati ba awọn adari sọrọ fun jija fun ẹtọ ọmọbinrin.
- Charles Soludo ti jáwé olúborí gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra
- Àrùn jẹjẹrẹ ló mú ìyàwó mi lọ, àmọ́ gbogbo wa la ó dágbére lọ́jọ́ kan- Pásítọ̀ Odukoya
- Mi ò lè sùn, mó ń ronú, mi ò lè ṣe ǹkan torí Lanre - Princess
- Wo ohun tí ọkọ àti ìyàwó, Lateef Adedimeji àti Bimpe fi síta fúnra wọn to fihàn pé ọjọ́ ti súnmọ́
- Ìjọba àpapọ̀ kéde ètò “Operation Feed Yourself” láti pèsè ọ̀pọ̀ oúnjẹ yanturu
- Àpapọ ilé aṣòfin Nàìjíríà buwọ́lù fífi èsì ìdìbò hàn lórí ayélujára
- Ọ̀kadà tó n lo iná ẹ̀lẹ́tíríìkì wọ̀lú! Ó le ṣe iṣẹ́ wákàtí mẹ́wàá láì dáwọ́ dúró
- 'Ọba Yorùbá kìí ṣe aláṣẹ ìkejì Orìṣà mọ́ látòní lọ! Krìstẹ́nì, Mùsùlùmí àti Àbáláyé yóò máa ṣe ayẹyẹ pọ látòní'
- Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ètò ìsìnkú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ 26 tó jóná mọ́ yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn
Malala, to jẹ ajafẹtọ awọn obinrin ni Pakistan ṣalọ ilẹ Geẹsi fun atipo lẹyin ti ikọ Taliban yinbọn lu ni ori lọdun 2012.
Lasiko to n kede iroyin igbeyawo naa loju opo Twitter rẹ, o ni "Emi ati Asser ti di lọkọ-laya nibi ayẹyẹ nikkah kekere kan pẹlu awọn mọlẹbi wa."

Oríṣun àwòrán, MALIN FEZEHAI
Ọmọ ọdun marudinlogun ni Malal wa nigba ti Taliban doju ija kọ ọ ni Pakistan nitori pe n sọrọ soke fun ẹtọ awọn obinrin.
Lọdun naa lọhun ni Taliban kọlu ọkọ bọọsi ile ẹkọ rẹ ti wọn si ṣina ibọn bolẹ, oun atawọn ọrẹ rẹ meji lo farapa ninu ikọlu ọhun.
Lẹyin to gbadun tan ni oun atawọn ẹbi rẹ lọ ṣatipo niluu Birmingham, nibi to pe ni ile rẹ keji.

Oríṣun àwòrán, MALIN FEZEHAI
Niga to maa fi di ọmọ ọdun mẹtadinlogun, o di ẹni to kere julọ lagbaye ti yoo gba ami ẹyẹ "Noble Prize."
Lati ibẹ lọ, Malala lọ si fasiti Oxford, o si di ọkan lara awọn ajafẹtọ ọmọniyan to lamilaaka julọ lagbaye.















