Ikoyi house collapse: Ẹni kọ̀ọ̀kan tó fẹ́ rà nínú ilé alájà 21 tó wó l'Eko ti ṣàdéhùn láti san N206m sí N1.24bn kó tó wó

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Awọn Yoruba maa n gbadura kan pe ki Edua ma jẹ ki ohun ti a ko ro ba ohun ti a n ro jẹ.
Bayii gan an lọrọ ṣe ri pẹlu awọn eeyan to fẹ ra ninu ile alaja mọkalelogun to da wo lagbegbe Ikoyi niluu Eko lọjọ kinni oṣu kọkanla.
Ninu ifọrọwerọ ti awọn eeyan kan lara wọn ṣe pẹlu iwe iroyin Punch, wọn fidi rẹ mulẹ pe awọn ti buwọlu iwe adehun lati san owo toto N206.5m($500,000 ) si N1.24bn($3m) ẹni kọọkan.
- Bí mo ṣe ká a sára tí mo gbé òkú ọmọ sínú ọkọ̀ lọ ṣe iṣẹ́ apanilẹ́rìín láì fihàn - Woli Agba Ayo Ajewole
- Ṣé lóòtọ́ ni Lateef Adedimeji àti Bimpe Oyebade fẹ́ ṣègbéyàwó lọ́tẹ̀ yìí lóòtọ́? Lateef bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀
- 'Wọ́n gba irun abẹ́ wa, irun abíyá wa, a lọ búra, ilé "Nylon" la tún ń gbé ni Mali fi ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó'
- Ta ló ni ilé alájá 21 tó wó pa àwọn èèyàn ní Ikoyi gan? Ìjọba Eko ti fèsì
- ''Mo ti gbàdúrà fún àànú láti r'ọ́run wọ̀ lẹ́yìn tí mo wà lábẹ́ ilé tó wó ní Ikoyi fún ọjọ́ kan''
- Sanwo-Olu ṣèlérí ìrànwọ́ owó fún ètò ìsìnkú tó dára f'àwọn tí ilé alájà 21 wó pa ní Ikoyi
- "Amẹ́ríkà ni Wale Bob-Oseni ń lọ, ìpè fóònù tó gbà, ló gbe lọ síbi ilé tó dà wó"
- Wo ọ̀rọ̀ tí gómìnà ìpínlẹ́ Ogun sọ lẹ́yìn tó ṣàbẹ̀wò sí bàbá Femi Osibona tó kọ́ ilé tó dà wó l'Eko
- Ajínigbé ń bèèrè N10m, codiene, igbó àtí oúnjẹ fún ìtúsílẹ̀ èèyàn mẹ́ta tí wọ́n gbé l'Ogun
Awọn iwe adehun ti wọn fi han akọroyin Punch ṣe afihan rẹ rẹ pe wọn lanfanni lati san owo yoku laarin ọdun mẹrin lẹyin ti wọn ba ti sanwo akọkọ tan.
Wọn ni ileeṣẹ akọleta Fourscore Heights Limited sẹ agbekalẹ ati sanwo to ku lọna to rọrun fawọn.
Wọn eeyan le maa san owo toku loṣooṣu, lẹẹmẹrin lọdun, lẹẹmeji lọdun tabi lẹẹkan lọdun, eleyii to ba wu yin ni.
Bakan naa ni wọn ṣalaye pe aja ile ti o ba fẹ ra ba ṣe ga si ni owo rẹ yoo ṣe pọ to.
Ẹnikan lara awọn to fẹ ra ile nibẹ sọ pe oun san N266m fun ile oni yara mẹta ti oun fẹ ra ninu awọn ile to wa lati aja kẹjọ lọ silẹ.
Amọ, o sọ pe akọleta to ni ileeṣẹ Fourscore Heights Limited din oun lowo nitori ọrẹ ni awọn jọ jẹ.
O ni awọn jọ ṣe kekere ni lati ileewe Mayflower niluu Ikene nipinlẹ Ogun, bakan naa lo ni awọn jọ wa ni ilu London ni.
O ṣalaye pe oun gbọ pe awọn to fẹ ra ile lati aja kejila lọ soke lọ san owo to le ni N492m.
O fikun ọrọ rẹ pe awọn to fẹ ra ile lati aja kẹtadinlogun lọ soke san owo to le ni N1.24bn($3m).
Dọla ni wọn sọ pe ileeṣẹ Fourscore Heights Limited sọ fawọn pe ki awọn fi sanwo.
Ileeṣẹ naa o ti fesi si gbogbo ọrọ tawọn eeyan n sọ nipa wọn titi di akoko yii.
Eeyan mejilelogoji ni ijọba ipinlẹ Eko sọ pe wọn ku nibi iṣẹlẹ naa nigba ti ori ko eeyan mẹẹdogun yọ nibi iṣẹlẹ ọhun.












