Ikoyi house collapse: Sanwo-Olu ṣèlérí ìrànwọ́ owó fún ètò ìsìnkú àwọn tó kú

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu
Gomina ipinlẹ Eko, Sanwo-Olu ti ṣeleri pe ijọba yoo ṣe iranwọ owo fun eto isinku awọn ti ile alaja mọkanlelogun wo pa lagbegbe Ikoyi niluu Eko lọjọ Aje ọjọ kinni oṣu kọkanla ọdun 2021 yii.
Sanwo-Olu sọrọ yii nigba to tun ṣe abẹwo si ibi ti ile naa ti dawo lọjọ Abamẹta niluu Eko.
Gomina ipinlẹ Eko fun awọn to ba fẹ ni iranwọ owo naa wa fun nitori awọn ẹbi mii le maa nifẹ si iru owo bẹẹ.
- Kí ló so Yemi Osinbajo pọ̀ mọ́ ilé alájà púpọ̀ tó dà wó ní Eko?
- Kókó méjìlá nípa ìgbé ayé Femi Osibona
- "Amẹ́ríkà ni Wale Bob-Oseni ń lọ, ìpè fóònù tó gbà, ló gbe lọ síbi ilé tó dà wó"
- Ǹ jẹ́ o mọ̀ pé Femi Osibona ta bàtà àti aṣọ kóòtù rí, kó tó di akọ́létà?
- "Pásítọ̀ onímọ̀ ẹ̀rọ kan àti lébìrà 18 tó kó wá láti Ibafo sì wà lábẹ́ ilé Ikoyi "
- Ó di dandan kí a wa iṣu dé ìṣàlẹ̀ kòkò l'órí ọ̀rọ̀ ilé tí ó wó ní Ikoyi-Tinubu
- Alùlùgbayì ọmọ Nàìjíríà tó fI Ìlù kojú ìdẹ́yẹsí ní Amẹ́ríkà rèé
Bakan naa ni Sanwo-Olu ṣalaye pe ijọba ipinlẹ Eko tun ti ṣe iranwọ owo fawọn to moribọ nibi iṣẹlẹ naa.
O ni owo ti ijọba fun wọn yoo ran wọn lọwọ pẹlu jijẹ mimu lẹyin ti wọn ba gbadun tan.
Ẹwẹ, gomina ipinlẹ Eko ti sọ pe ijọba ti ri eeyan mẹfa mii ti wọn yọ laaye nibi ile naa.
Sanwo-Olu ni awọn eeyan mẹfa naa wa lara awọn tawọn ẹlẹyinju aanu kan tete yọ gbara ti iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ.
Gomina ni orukọ awọn eeyan naa ni Glory Samsom, Ndajor Ahmed, Yunusa Abubaka, Ajiboye Habib, Jeremiah Samson, ati ọkunrin kan to n jẹ Emem.
O ni ile iwosan ileeṣẹ ọlọpaa Police Hospital ni Falomo ni wọn gbe awọn eeyan naa lọ fun itọju nibi ti awọn kan ti lọ sile lara wọn lẹyin ti wọn gbadun tan.
Gomina ni o ti di eeyan mẹẹdogun to moribọ bayii nibi iṣẹlẹ naa pẹlu mẹsan an tawọn oṣiṣẹ adoola ẹmi yọ laaye tẹlẹ.
Sanwo-Olu to ṣabẹwo si ibi ti ile ọhun ti dawo pẹlu Aṣiwaju Bola Tinubu sọ pe o ti di oku eeyan mejilelogoji ti wọn ti yọ labẹ ogiri alapa to wo bayii.
Gomina ipinlẹ Eko ni awọn ẹbi awọn eeyan to ku ti bẹrẹ si ni maa wo awọn eeyan wọn ninu oku to wa ni mọṣuari.
Sanwo-Olu ni ijọba n ṣe ayẹwo oku awọn ti wọn ko le damọ daadaa ki awọn ẹbi wọn le mọ oku to jẹ ti wọn.
Gomina ni iṣẹ si n lọ nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye lati yọ awọn to ba si tun wa labẹ ogiri alapa.















