Ìkúnlẹ̀ Abiyamọ oo! Ìyá ju ọmọ rẹ̀ méjì sí Kànga

Obìnrin kan tí wọ́n n pé orúkọ rẹ̀ ni Omowumi, tí àwọn mííràn sì n pèé ni ìyá Darasimi ni àwọn tó jọ n gbé agbègbè ni o ni ààrùn ọpọlọ.
Ìyá Darasimi ju àwọn ọmọ rẹ obinrin méjèèjì sínú kanga nílùú Osogbo tii se olúùlú ìpińlẹ̀ Osun
Akọ̀ròyìn BBC Yoruba jábọ pé, àwọn alábágbé rẹ̀ ni adugbo Ibuaje sọ pé, ọ̀rọ̀ tó ní ìtumọ̀ kan kò jáde lẹ́nu obìnrinnaa, ẹni tó ju àwọn ọmọ rẹ̀ sínú kanga tó kú fún omi
- Sanwo-Olu ṣèlérí ìrànwọ́ owó fún ètò ìsìnkú tó dára f'àwọn tí ilé alájà 21 wó pa ní Ikoyi
- "Ó dùn mí pé èmi ló bí Abubakar Shekau tó dá ayé lóró"
- Ọ́dọ́kùnrin 18 láti òkè ọya pẹ̀lú ohun ìjà olóró dojú ìjà kọ Àmọ̀tẹ́kùn l'Ondo
- Gómínà díbọn lọ ilé ìwòsàn, òṣìṣẹ ìlera tó gba rìbá N10,000 wọ gàù
- Ìdìbò gómìnà Anambra gbérasọ, ìíú dá wáí-wáí, aráàlú ń sá kíjo kíjo
- Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nílé ẹjọ́ lónìí lórí ìgbẹ́jọ́ Baba Ijesha
- Kí ló so Yemi Osinbajo pọ̀ mọ́ ilé alájà púpọ̀ tó dà wó ní Eko?
- Kókó méjìlá nípa ìgbé ayé Femi Osibona
- "Amẹ́ríkà ni Wale Bob-Oseni ń lọ, ìpè fóònù tó gbà, ló gbe lọ síbi ilé tó dà wó"
- Alùlùgbayì ọmọ Nàìjíríà tó fI Ìlù kojú ìdẹ́yẹsí ní Amẹ́ríkà rèé
Òkú àwọn ọmọ náà, Darasimi Babalola tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ àti Desire Babalola tó jẹ́ ọmọ ọdún márùn, ni àwọn ara adúgbò tí yọ síta lẹyìn tí wọ́n san owó fún àwọn to n gbẹ kanga.
Àwọn ará adúgbò yìí bákan náà ló dá ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá Nàìrà jọ láti sánwo fún ẹni tí o yọ wọ́n, èyí wáye lẹ́yìn tí gbogbo ìgbìyànjú àwọn pánapana pin, nítórí wọn kò rí ṣe paapaa bi omi se kún inú kanga náà.
Nínú ọ̀rọ̀ aládúgbò kan tí kò fẹ́ kí a dá orúkọ oun ṣàlàyé pé, alẹ́ ọjọ́ Aje ni Omowumi yọ kẹlẹkẹlẹ lọ ju àwọn ọmọ náà sínú kànga.
sùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà tú sí gbàngba nígbà tí àwọn alábágbé rẹ̀ ri bi o ṣe ń dòòyì ka ibi kànga pé òun ń wá àwọn ọmọ òun tí oun kó síbẹ̀.

Èyí ló mú kí àwọn ará ilé bẹ̀rẹ̀ sí ni pọn omi kanga náà jáde, sùgbọ́n ó se ni láànu pé, òjò ńlá kan bẹ̀rẹ̀, tí olúkúlùkù sì gba ilé wọn lọ láti pada wá ni ọjọ́ keji, nitori ko si ẹni to le yọ àwọn ọmọ náà.
"Lẹ́yìn ti gbogbo ìgbìyànjú wa kò ni aṣeyọri kankan ni a ke pe àwọn panápaná láti wa ràn wá lọ́wọ́.
"Àwọn panápaná náà kó sínú omi sùgbọ́n wọ́n ko ri àwọn ọmọ náà yọ, lẹ́yìn èyí ni wọ́n jẹ́jẹ̀ pé àwọn ń pada bọ.
" Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta ni àwọn ará adúgbò wá àwọn Hausa tó ń ṣe iṣẹ́ kanga, ti wọn si jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn yóò kó àwọn ọmọ méjì náà jáde, ti wọ́n bá le san ẹgbẹrun mẹ́wàá náírà."
"Gbogbo wa dá owó náà jọ, tí a si ko fún wọn"
"Oman ni Ìyá Darasimi ti ṣẹ̀ṣẹ̀ dé, nǹkan tí o si má ń tẹnumọ́ ní gbogbo ìgbà ni pé, aye ti nira jù"
Agbẹnusọ ọlọpàá ìpínlẹ̀ Osun Yemisi Popoola fidí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ , bákan náà ni ó ni ọlọpàá tí fi obìnrin ọ̀hún sí àtìmọ́lé.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà ni àwọn yóò ṣe àyẹ̀wò fún bọya lóòtọ́ ni o ni ààrùn ọpọlọ.
Ẹ̀wẹ̀, Popoola ni òun kò mọ̀ nípa àwọn Hausa tó yọ okú àwọn ọmọ, sùgbọ́n òun mọ pé àwọn panápaná ló ṣe iṣẹ́ náà.


















