Ikoyi collapsed building: Ta ló ń so Igbákejì ààrẹ, Yemi Osinbajo pọ̀ mọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ ilé alájà púpọ̀ tó dà wó ní Eko?

Oríṣun àwòrán, Professor yemi osinbajo/ facebook/bbc
Lati igba ti iṣẹlẹ ile alaja pupọ kan to da wo lagbegbe Ikoyi nilu Eko ti waye lọjọ Aje, ọjọ kini oṣu Kọkanla ọdun 2021, oniruuru awuyewuye lo ti waye.
Bi awuyewuye ti ṣe waye lori ohun to fa iṣẹlẹ naa, ni awuyewuye waye lori iye awọn to ti ku, awọn ti wọn ti ri gbe jade laaye, ati bẹẹbẹẹ lọ.
Amọṣa lọwọ yii, awuyewuye to n waye ni lori ẹni gan to ni ile naa.
- Kókó méjìlá nípa ìgbé ayé Femi Osibona
- "Amẹ́ríkà ni Wale Bob-Oseni ń lọ, ìpè fóònù tó gbà, ló gbe lọ síbi ilé tó dà wó"
- Ǹ jẹ́ o mọ̀ pé Femi Osibona ta bàtà àti aṣọ kóòtù rí, kó tó di akọ́létà?
- "Pásítọ̀ onímọ̀ ẹ̀rọ kan àti lébìrà 18 tó kó wá láti Ibafo sì wà lábẹ́ ilé Ikoyi "
- Ó di dandan kí a wa iṣu dé ìṣàlẹ̀ kòkò l'órí ọ̀rọ̀ ilé tí ó wó ní Ikoyi-Tinubu
- Èèyàn ogún ló ti sọ ẹ̀mí nù nínú ilé alájà 21 tó wó ni Ikoyi - NEMA
- A gbọ́ ohùn bí àwọn ènìyàn tó há sí abẹ́ ìlé alájà 21 ṣe ń kérọrà fún ìrànwọ́ – NEMA
- Èèyàn tó há sí abẹ́ ilé tó wó kò sí ẹni tó lè sọ ṣùgbọ́n òkú mẹ́rin là ri-Ọlópàá
Bi o tilẹ jẹ pe iroyin lati ọdọ ijọba ti fidi rẹ mulẹ pe ọgbẹni Oṣibọna, ti oun pẹlu wa lara awọn ti wọn ti ku labẹ awoku ile naa lo ni ile alaja mọkanlelogun naa.
Sugbọn awọn iroyin kan latọdọ awọn ileeṣẹ iroyin abẹle kan bii "Sahara Reporters" n mu orukọ miran jade. Orukọ ta ni?
Ninu atẹjade kan to gbe jade ninu iwe iroyin rẹ ọjọ kẹrin oṣu Kọkanla ọdun 2021, Sahara Reporters ni "wọn ti rii pe igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria, Yẹmi Oṣinbajo ni ajọṣepọ pẹlu ile alaja mọkanlelogun to da wo nipinlẹ Eko"
Iwe iroyin naa tun kọọ pe, awọn alami awọn sọ fun awọn pe Igbakeji Aarẹ Yẹmi Osinbajo lo ra ilẹ naa lọwọ oloye Michael Ade-Ojo, to jẹ oludasilẹ ileeṣẹ Elizade Motors, lẹyin to de ipo igbakeji aarẹ.
Ki ni Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajo sọ lori ọrọ yii?

Oríṣun àwòrán, Professor yemi osinbajo/ facebook
Ileesẹ aarẹ Naijiria ti fi atẹjade sita lori rẹ pe ko si ohun to kan igbakeji aarẹ pẹlu dukia ilẹ ati ile to dawo naa.
Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajo, Laolu Akande fi sita sọ pe gbogbo dukia ti igbakeji aarẹ ni lo ti kede fun ijọba gẹgẹ bi ofin orilẹede Naijiria ti ṣe laa kalẹ.
"O ti wa setigbọ igbakeji aarẹ pe iroyin irọ kan ti ileeṣẹ iroyin Sahara Reporters gbe jade lọjọ kẹrin oṣu kọkanla ọdun 2021 n kaakiri nipa ile alaja pupọ to da wo laipẹ yii pe:
- Igbakeji aarẹ lo ni ilẹ ti wọn kọ ile alaja to da wo ni Ikoyi le
- Pe Oloye Michael Ade Ojo, alaga ileeṣẹ Elizade Motors lo ta ilẹ naa fun
- Pe igbakeji aarẹ gbiyanju lawọn asiko kan lati di awọn iṣẹ awọn ajọ to n mojuto ọrọ ile gbigbe nipinlẹ Eko lọwọ.
Atẹjade naa ni ko si nnkankan ti igbakeji aarẹ ba gomina ipinlẹ Eko tabi oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ naa kankan sọrọ nipa yiyọ iwe ti wọn le fi ti ile naa pa ki o to dawo.
Ati pe ko si igba kankan to gbe igbesẹ lati di iṣẹ awọn ajọ to n mojuto ọrọ ile gbigbe nipinlẹ Eko lọwọ.
Igbakeji aarẹ ṣalaye ninu atẹjade naa pe, o fihan daadaa pe iṣẹ iroyin onisọnu lawọn ileeṣẹ agberoyin jade 'Sahara Reporters' ṣe, ti o si ti fi ṣọwọ si awọn agbẹjọro rẹ fun igbesẹ gbogbo to ba tọ.
Ki ni Oloye Micheal Ade-Ojo, alaga ileeṣẹ Elizade sọ?

Oríṣun àwòrán, ovation international
Amọṣa, Oloye Michael Ade-Ojo pẹlu ti sọrọ sita lori rẹ pe, irọ lasan niroyin naa ati pe oun ati Igbakeji aarẹ Oṣinbajo ko fi igba kankan ni idunadura lori ilẹ ti wọn kọ ile to da wo naa si.
O ṣalaye ninu atẹjade kan to funrarẹ buwọlu lati bomi pa ina awuyewuye ti iroyin iwe iroyin naa da silẹ pe, ilẹ to wa ni adojukọ ilẹ ti wọn kọ ile to da wo naa si ni toun, oun ko si ṣetan lati taa fun ẹnikẹni bi o ti wulẹ o mọ.
"O ti wa seti igbọ mi pe atẹjade kan latọdọ Sahara Reporters n sọ pe emi ni mo ni ilẹ ti wọn kọ ile alaja pupọ to da wo ni Ikoyi nilu Eko.

Oríṣun àwòrán, Oloye Michael Ojo
"Iroyin naa tun sọ pe mo ta ilẹ naa fun igbakeji Aarẹ, Yẹmi Oṣinbajo, ni kete to wọle si ipo.
"Irọ funfun balau ti awọn iroyin mejeeji yii. Mo wa n sọ ko ye tẹru tọmọ pe mi o fi igba kankan ni ilẹ yii.
"Ko le ye gbogbo eeyan, Mo ni dukia kan si ẹgbẹ ile ti a n sọrọ rẹ yii, ti mi o si tii ta, ti mi o dẹ nii lọkan ati ta fun ẹnikẹni."
Awọn ọrẹ ati alabaṣiṣẹpọ Igbakeji Aarẹ naa ti da si ọrọ naa pẹlu

Oríṣun àwòrán, Professor yemi osinbajo/ facebook
Ẹwẹ, Ọgbẹni Richard Akinọla gbe atẹjade kan sita lorukọ awọn ọrẹ ati alabaṣiṣẹpọ Ọjọgbọn Yẹmi Osinbajo ninu eyi to ti yannana rẹ pe bii igba ti eeyan n parọ mọ aja lati lee sọ lorukọ buruku niroyin naa, eyi to pe ni kobakungbe.
"Awọn iroyin kan sọ pe Ọgbẹni Fẹmi Osibọna jẹ agbodegba fawọn eekan kan ni ijọba, awọn miran tilẹ so o pọ mọ igbakeji aarẹ, nigba ti awọn kan fi ọgbọọgbọn n darukọ gomina ipinlẹ Eko.
"Fun anfani awọn ti wọn le fẹ gbọ ti iroyin aṣinilọna yii, awa gẹgẹ bii ọrẹ ati alabaṣiṣẹpọ igbakeji aarẹ n fẹ fọ orukọ rẹ mọ tonitoni pe ko mọ sii, bẹẹ ni ko nipin ajọni kankan ninu ileeṣẹ ẹni to kọ ile alaja naa tabi ọrọ aje rẹ.
Ju gbogbo rẹ lọ, lasiko ti a fi n ko iroyin yii jọ, ko din ni eeyan mẹrindinlogoji ti awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi ati ọlọpaa ti kede pe wọn ti jade laye lẹyin ti wọn ri oku wọn gbe jade labẹ awoku ile alaja mọkanlelogun naa.
Ninu wọn ni Ọgbẹni Fẹmi Oṣibọna to ni ile naa wa.
Bẹẹni iṣe idoola ẹmi ṣi n tẹsiwaju, ti ijọba ipinlẹ Eko pẹlu si ti gbe igbimọ oluwadi dide lori rẹ.


















