Ikoyi Collapsed Building: Mọ̀ sì nípa Femi Osibona tó ni ilé alájà 21 tó wó ní Ikoyi

Femi Osibona

Oríṣun àwòrán, Femi Osibona

Oriṣiiriṣii iroyin lo ti lu ori ayelujara pa lori Ọgbẹni Femi Osibona, akọleta to ni ile alaja mọkanlelogun to da wo ni Ikoyi niluu Eko lọsan an ọjọ Aje.

Ọjọ Kinni osu Kọkanla ọdun 2021 ni isẹlẹ ile to da wo naa waye lopopona Gerrard, Ikoyi-Lagos Island nilu Eko

Ẹni to kọ ile yii naa si n se ipade lọwọ pẹlu awọn eeyan kan ni, nigba ti ile naa da wo lulẹ, ti ọpọ eeyan si ha si abẹ rẹ, to fi mọ awn alejo ati awọn lebira to n kọ ile naa.

Femi Osibona gan an fun ra rẹ si wa labẹ awoku ilé to wo naa, ti ẹnikan ko sí mọ boya o si wa laaye tabi o tí jẹ Ọlọrun nipe.

Awọn mii tiẹ sọ pe awọn ọlọpaa ti gbe ọkunrin naa lẹyin ijamba ile to n kọ to wó lu awọn eeyan mọlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Ikoyi Collapsed Building: Bí ilé alájà mọ̀kànlélógún ṣe dà wó lulẹ̀ ní Ikoyi, l‘Eko rèé

Ta ni Femi Osibona tó ní ile to dawo ni Ikoyi niluu Eko?

Femi Osibona jẹ ẹni aadọta ọdun to wa lati ilu Ikenne to si kawe gboye fasiti loke okun.

Ọgbẹni Femi Osibona ni ọga agba ileeṣẹ akọleta Fourscore Homes Limited to n kọ ile alaja mọkanlelogun to wó ni opopona Gerrard ni Ikoyi niluu Eko.

Osibona jẹ ọmọ ẹgbẹ awọn akọleta, NHBRC(National Home Builders Registration Council) ni orilẹ-ede South Africa.

Bakan naa lo jẹ ọmọ ẹgbẹ Zurich Building Guarantee nilẹ Yuroopu.

Ilu Eko ni Osibona ti lọ sí ilé ẹkọ akọbẹrẹ.

Bakan naa ni o lọ sí ilé ẹkọ girama Mayflower Secondary School niluu Ikenne nipinlẹ Ogun, ki o to lọ sí oke okun lati tẹsiwaju ẹkọ rẹ.

Osibona kawe gboye ninu ẹkọ iṣowo ati eto inawo ni fasiti Croydon ni UK.

Ọdun 1997 ni Osibona bẹrẹ owo akọleta ati ilẹ rira ni Hackney niluu London.

Lẹyin naa ni ileeṣẹ ọhun ni ẹka lorilẹede South Africa ati Naijiria, ti wọn si bẹrẹ sí ní kọ ile nla nla kaakiri agbaye.

Lọdun 2009 ti Ajagunfẹyinti Brig-Gen Buba Marwa jẹ aṣoju ijọba Naijiria ni South Africa, ileeṣẹ Osibona, Fourscore Homes kọ ile awodamiẹnu mẹfa ti wọn n pe ni Fourscore Mansions ni Waterkloof ni Pretoria.

Osibona ni akọleta ọmọ ilẹ Afirika akọkọ to kọ ile alaja meje lorilẹ ede UK.

Ile naa ni wọn pe ni Fourscore Mansion to wa ni 113, Albion Drive London Fields, E8, 4LZ, East London.

Ile alaja mọkanlelogun ko to da wo lulẹ

Oríṣun àwòrán, Facebook

Ọrọ ti Femi Osibona sọ nipa ileeṣẹ rẹ ree:

"Ileeṣẹ wa ti fihan araye ni UK, Amẹrika, South Africa ati Naijiria pe agba ọjẹ ni wa ninu ile kikọ.

Ileeṣẹ Fourscore ni agbara lati fakọyọ nibikibi ti a ba ti n kọle.

Ki n to bẹrẹ owo akọleta, oju mi ri to.

Mo ta bata loṣu kẹsan an ọdun 1991 lẹyin ti mo kawe gboye HND tan ni UK.

Bakan naa ni mo ta aṣọ kootu, ki n to fi owo yii silẹ lọdun 1998.

Ọdun 1997 gan an ni mo bẹrẹ owo akọleta ati ilẹ rira.

Mo ti kọ ile to le ni aadọta niluu London ati Manchester.

Lati ibẹ ni mo ti lọ si South Africa nibi ti mo tun ti kọ àwọn ilegbe kan.

Lẹyin ti mo ti kọ ọpọlọpọ ile niluu oyinbo, ni mo pinnu lati wa ṣe bakan naa nilẹ ni Naijiria.

Ileeṣẹ Fourscore mi lo kọ ile 360 Tower ni Ikoyi ati awọn ile miran niluu Eko.

Ashimolowo sọrọ nipa Femi Osibona

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Ọrọ ti Pasitọ Matthew Ashimolowo sọ nipa Femi Osibona ree:

Alufaa ati oludasilẹ ijọ Ki ijọ Kingsway International Christian Centre(KICC) niluu London naa sọrọ lori ibaṣepọ to ni pẹlu Femi Osibona.

Ninu fidio kan to n ja rain lori ayelujara ni Ashimolowo ti sọ pe lọdun 2001 ni oun kọkọ mọ Femi Osibona.

"Osibona lo fun mi ni aṣọ kootu ti mo wọ lọ síbi eto ti ijọba Redeem pe mi sí l'Abuja, lẹyin ti wọn ti ṣe aṣiṣe ni papakọ ofurufu, ti wọn si gbe ẹru mi lọ sí Jamaica.

Osibona ti n gbọ iwaasu mi tipẹ tẹlẹ bo tilẹ jẹ pe ijọ Celestia lo n lọ.

O tí gbọ iwaasu mi lori igbala ọkan, itusilẹ ati okoowo.

Lẹyin ti Osibọna gbọ iwaasu mi, o lu aluyọ, o sí kọ ile nla marundinlaadoje ni Centurion lẹgbẹ Johannesburg ni South Africa.

Lẹyin naa lo pe mi, o si sọ pe oun fẹ wa sí ọdọ mi ni Ghana nibi ti mo ti n waasu.

Nigba to de, ni mo bi mi leere pe nibo ni ki oun tun ti lọ kọ ile bayii ṣugbọn mo sọ fún un pe ki o lọ beere lọwọ awọn oludamọran rẹ lori ọrọ owo.

Amọ, o ni imọran mi dara ju ti wọn lọ.

Léyìn naa ni mo gb'ọwọ le e lori, ti mo si gbàdúrà fun ùn. Mo ni ko lọ si Naijiria.

Femi Fourscore ni wọn maa n pe e:

Gbara ti Femi de sí ìlú Èkó ni o ra ilẹ ni Ikoyi, ti o si kọ ile ogoji eleyii to ta ọkọọkan ni miliọnu kan dọla.

Nibayii, Ashimolowo ni Femi tun ti fidio kan ranṣẹ sí oun nibi ti o ti n kọ ile awodamiẹnu ni Ikoyi.

Aṣọ ati tai lasan ni ọkunrin yii n ta l'Abuja tẹlẹ o.

Ṣugbọn lonii, o tí ni oríṣìíríṣìí dukia ile," Ashimolowo lo sọ bẹẹ.

Awọn eeyan to n gbadura lori ile to da wo

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Ibasepọ Femi Osibona pẹlu Dele Momodu ati Oluwo ti Iwo:

Yatọ si pe Femi Osibona sun mọ awọn eeyan Ọlọrun, to si jẹ ẹni ẹmi to maa n gbadura loore koore, bakan naa lo tun sun mọ awọn eeyan nla nla nilẹ Naijiria ati lẹyin odi.

Koda, fidio kan gan n ja lori ayelujara nibi ti awọn ojisẹ Ọlọrun kan atawọn olorin ẹmi ti lọ ba Femi Osibona gbadura nibi ile to n kọ lọwọ naa.

Bakan naa ni oniruuru fidio ati aworan wa lori ayelujara to n sọ nipa bi Osibona ati Oloye Dele Momodu pẹlu Oluwo ti sunmọra si.

Bakan naa ni Dele Momodu ti fi fidio kan soju opo Instagram rẹ eyi to n se afihan iyawo rẹ ati Femi Osibona plu awn oyinbo kan ti wọn wa lori ile to da wo naa ni ọsẹ kan sẹyin.

Femi Osibona, iyawo Dele Momodu ati awọn oyinbo kan

Oríṣun àwòrán, delemomoduovation/Instagram

Nigba ti BBC yoruba kan si Oluwo tilu Iwo lati mọ ipo to wa lori isẹlẹ naa nitori bo se sun mọ Femi Osibona si, Oluwo ni ọkan oun rẹwẹsi nipa isẹlẹ naa, to si ba oun ninu jẹ gidi.

Aworan kan to wa loju opo Facebook Oluwo, eyi to fi sibẹ ni ọjọ Kẹsan osu Kwa ọdun 2021, eyiun ọsẹ mẹta ki isẹlẹ ile didawo naa to waye, lo n safiihan Femi Osibona to n mu Oluwo rin yika ile to da wp naa.

Femi Osibona ati Oluwo lori ile to da wo naa ni ọsẹ mẹta saaju ki ile to wo

Oríṣun àwòrán, Telu Initiatives - greater Iwo Empire Facebook