Poly Ibadan Stray Bullet: Àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ Poly ṣàlàyé bí ìbọn ṣe bá akẹ́kọ̀ọ́

Oríṣun àwòrán, Screen Shot
Rogbodiyan bẹ silẹ nile ẹkọ giga gbogboniṣe Poly Ibadan l'ọjọ Iṣẹgun lẹyin ti aṣita ibọn ba akẹkọọ kan ninu ọgba ile ẹkọ naa.
Akẹkọọ naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Babatunde Taibat to n bẹ ni ipele akọkọ, ND1, ni ẹka ti wọn ti wọn ti n kọ nipa ṣiṣe amulo ẹrọ igbalode fun imọ sayẹnsi, ni a gbọ pe aṣita ibọn ba lasiko ti awọn ẹṣọ abo n lepa awọn ọdaran kan ninu ọgba ile ẹkọ naa.
Digbadigba ni wọn gbe akẹkọbinrin naa lọ si ile iwosan ẹkọṣẹ imọ iṣegun Oyinbo, UCH nilu Ibadan, nibi ti o ti n gba itọju bayii.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Mo fẹ́ dákú níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọgọ́ta ọdún mi - Salawa Abeni
- Ọ̀gá báńkì rẹ́wọ̀n he torí ó fi N219m owó oníbàárà kọ́ ilé, ra ilẹ̀
- Àwọn adarí iléẹ̀kọ́ wọ gàù fún gbígba owò lọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà àìtọ́
- Àwọn agbébọn kọlu ilé adarí Ilana Omo Oodua Ọ̀jọ̀gbọ́n Akintoye l'Ado-Ekiti
- Èèyàn ogún ló ti sọ ẹ̀mí nù nínú ilé alájà 21 tó wó ni Ikoyi - NEMA
- Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Iree Poly pọ ẹ̀jẹ̀ àti itọ́ kó tó kú lẹ́yìn tó dé láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀
- Àṣírí ti tú,kà nípa bí ìyàwó ilé ṣe lẹ̀dí àpọ̀ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó fẹ́ jí ọkọ rẹ̀ gbé
- A gbọ́ ohùn bí àwọn ènìyàn tó há sí abẹ́ ìlé alájà 21 ṣe ń kérọrà fún ìrànwọ́ – NEMA
- Wòlíì kan fún òṣèré tíátà ní miliọnu mẹ́fà náírà láti fi tọ́jú àìsàn rẹ̀
- Ẹgbẹ́ TAMPAN ló mú kí ìjọba gbógun ti orísùn ọrọ̀ ajé mi - Yomi Fabiyi figbe ta
- Fulani darandaran kò ṣe lè ní Kwara, wọ́n pọ̀ ju ọmọ onílùú lọ
Ọkan lara awọn akẹgbẹ akẹkọọ naa ti o ba akọrin wa sọrọ, Adekọla Adewale ṣalaye wi pe ni nnkan bi aago mẹrin abọ irọlẹ ni iṣẹlẹ naa waye.
O ni awọn akẹkọọ naa wa ninu gbọngan nla kan ti wọn ti gba idanilẹkọ laarin aago mẹta ọsan si mẹrin abọ irọlẹ.

Oríṣun àwòrán, Screen Shot
Bo tilẹ jẹ pe awọn alakoso ile ẹkọ giga naa ko ti i fi idi ọrọ mulẹ lori ẹni to yin ibọn naa, alaye ti wọn ṣe fun awọn oniroyin ni pe iṣẹ iwadii n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa.
Ninu atẹjade kan ti wọn fi lede, igbimọ to n ṣe akoso ile ẹkọ giga naa ṣalaye pe ẹmi akẹkọbinrin naa ko ba iṣẹlẹ ọhun lọ, bẹẹ si ni o ti n gba itọju bayii.
Bakan naa ni alamojuto feto igbaniwọle nilẹ ẹkọ giga naa, Arabinrin Modupẹ Fawale pa arọwa si awọn akẹkọọ lati mase foya nitori iṣẹ iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹu lori ohun ti o ṣokunfa ibọn ti wọn yin ninu ọgba ile ẹkọ naa.
Ninu ọrọ tiẹ, alukoro ile ẹkọ giga naa, Arakunrin Adewole Ṣoladoye fi idi ọrọ mulẹ pe lootọ ni aṣita ibọn ba akẹkọọ kan, ti wọn si ti gbe lọ si ile iwosan UCH fun itọju bayii.
O fi kun ọrọ rẹ pe, Giwa agba ile ẹkọ naa, Ọjọgbọn Kareem Adekunle lo gbe owo silẹ fun itọju akẹkọbinrin naa, ṣugbọn o ja niyan pe awọn ọkan lara awọn ẹṣọ aabo to n bẹ ninu ọgba ile ẹkọ naa lo yinbọn.
Adekunle salaye pe iṣẹ iwadii naa ṣi n lọ lọwọ lati ṣe awari ẹni to yin ibọn naa.



















