Abdulrazaq Abdulrahman: Ó nira fún mi láti fi òfin de ẹ̀ran dídà bí àwọn gómìnà yókù

Awọn Fulani to n da ẹran jẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gomina ìpínlẹ̀ Kwara tí ké gbàjarè pé àwọn Fulani darandaran tí ń ju ará ìlú lọ, wọ́n sì ti ń pọ̀ ju àwọn ọmọ onilu lọ.

Gómìnà Abdulrahman Abdulrazaq lo sọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó ń bá ìwé ìròyìn Vanguard sọrọ lori bí àwọn Fulani ṣe ń yà wọ Kwara.

O ni ó nira fún òun láti fi òfin de dída ẹran bíi àwọn gómìnà ìhà Gúúsù tó kù.

Gómìnà náà sọ pé fífi òfin de dídá ẹran jẹ ní ita gbangba le e mú kí ètò ààbò túbọ̀ mẹ́hẹ sì ni ìpínlẹ̀ Kwara.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Etò ààbò jẹ́ ìpènija gidi pàápàá julọ ní ìhà ìwọ ọrùn Àríwá àti bí àwọn gómìnà gúúsù náà ṣe ni kí àwọn Fulani má dá ẹran jẹ mọ́.

Ní kété tí wọ́n sọ èyí, tí wọ́n sì dá ọjọ tí yoo bẹ̀rẹ̀, bẹẹ ni àwọn Fulani bẹ̀rẹ̀ si ni ya wọ Kwara."

Bí ẹ bá lọ ìhà Gúúsù Kwara tàbí àríwá nisinyi pàápàá jù lọ ní àwọn ìgbèríko, ẹ ó rí bí wọn ṣe pọ̀ tó, wọ́n ti pọ̀ ju àwọn ará ìlú lọ."

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho Aide: Omiyale ni DSS rọ̀jọ̀ ibọn sí Igboho, wọ́n wá pa ni àmọ́ ó bọ́

Abdulrazaq ni fifi òfin de àwọn darandaran kò bá òfin mú nítorí náà òun kò lè ṣe nǹkan tí kò bá òfin mú.

"Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti bá àwọn asoju ìlú sọ̀rọ̀ láti máa gba àwọn ènìyàn mọ́ra pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé gbogbo rògbòdìyàn lórí ààbò yìí yóò dópin laipẹ.

Ọ̀rọ̀ yìí jẹyọ bí àwọn gómìnà gúúsù bí Babajide Sanwoolu tí ìpínlẹ̀ Eko, Rotimi Akeredolu tí Ondo, Nyesom Wike tí Rivers ṣe buwọ́lu ìwé òfin láti dènà kiko ẹran jẹ ni itagbangba ni ìpínlẹ̀ wọn.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn gómìnà àríwá náà tí péjú ni ẹmẹẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ọdún yìí ni Èkó, Asaba àti Enugu láti ṣe pàdé, pẹnupọ̀ lórí fífi òfin de ikẹranjẹ̀ ni gbangba.

Bákan náà ni adajọ́ àgbà ní Nàìjíríà, Abubakar Malami sọ pé ìgbésẹ̀ àwọn gómìnà gúúsù yìí kò tọ ìlànà òfin."

Àkọlé fídíò, Ikoyi Collapsed Building: Bí ilé alájà mọ̀kànlélógún ṣe dà wó lulẹ̀ ní Ikoyi, l‘Eko rèé

Gómìnà ọ̀hún ṣàlàyé pé òun ṣe ìbúra fún àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Kwara lásìkò tí òun gba òye gómìnà nítorí náà oun sì ṣetán láti ṣe iṣẹ́ tí oun gbà.

Gómìnà náà fi idi rẹ múlẹ̀ pé ní ọ̀pọ̀ ìgbà òun nifẹ si gbígbọ́ ju sísọ lọ, ó ní òun kii sọ̀rọ̀ nítorí anfani tó pọ̀ lo wá nínú gbígbọ́, èyí sì jẹ ọ̀nà kan láti lè dari ara ìlú daradara.

"A kó pariwo nkan ti a ń ṣe, nítorí rẹ lọ ṣe dá bí ẹni pé a kó ṣe ohunkóhun, awon ìjọba tó kọjá mọ àwọn ìròyìn sọ daada ṣùgbọ́n ipa iṣẹ́ tí àwa ń ṣe, ara àwọn ará ìlú lọ wà."