Olugbon Twins: Ọba Alao àti Olorì rẹ̀ bí ìbejì lẹ́yìn tí nǹkan oṣù ti dúró lẹ́ni ọdún 53

Àkọlé fídíò, Olugbon Twins: Ọba Alao àti Olorì rẹ̀ bí ìbejì lẹ́yìn tí nǹkan oṣù ti dúró lẹ́ni ọdún 53

Aramonda ni isẹ Oluwa, awamaridi si ni pẹlu nitori oun lo le se ohunkohun ti ẹda kan ko le se.

Ọna ara yii naa ni Ọba oke fi ta Olugbon tile Igbon, Ọba Francis Alao ati Olori rẹ, Ayaba Olusola Adedoyin Alao lọrẹ ibeji lanti lanti.

Olori, tii se ẹni ọdun mẹtalelaadọta lo ni oun ti ni arun jẹjẹrẹ tẹlẹ amọ ti Ọlọrun wo oun san, ti oun ko si lero pe o seese ki oun tun loyun pada lẹyin ti nnkan osu ti duro.

Olori naa, ti oun ati Olugbon ti se igbeyawo lati ọdun mejidinlogun amọ ti ikọọkan wọn ti ni ọmọ tẹlẹ ni igbeyawo ti wọn ti se saaju, lo ti n woju Ọlọrun fun ọmọ.

Lasiko ti wsn n ba BBC Yoruba sọrọ, Olugbọn ati Olori rẹ ni kii se ọna atọwọda ni awọn ibeji naa gba wa sile aye nitori o ya awọn naa lẹnu pe Olori loyun pẹlu ọjọ ori rẹ ati ipo ti ilera rẹ wa.

Wọn wa salaye bi irinajo naa se lọ, titi ti wọn fi bi awọn ọmọ naa ati oore ọfẹ Ọlọrun lori aye wọn.