Oyo Security: Olugbon àti Olu Igboora jábọ̀ ìpàdé wọn pẹlú Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Facebook
Akojọpọ ipade tawọn lọbalọba ipinlẹ Oyo se pẹlu gomina Seyi Makinde ti n foju han, to si daju pe ọna abayọ ti n jẹyọ lori eto aabo to mẹyẹ lawọn agbegbe kan nipinlẹ naa.
Koda, BBC Yoruba ti ri gbamu pe ijọba ipinlẹ Oyo ti fi nọmba kan sita fun ẹnikẹni to ba wa ninu ewu lati pe ni ipe pajawiri.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lori eyi, Olu ti ilu Igbo Ora, Oba Jimoh Olajide Titiloye ni ijọba Gomina Makinde ṣe agbekalẹ nọmba ipe pajawiri lori eto abo tii se 615.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kò sí ìyèméjì mọ́, Oduduwa Nation ni Yorùbá ń fẹ́ - Gani Adams
- Ìwà àjẹbánu àti títẹ̀ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú pọ̀jù nínú ìjọba Buhari - US
- Wo èèwọ̀ tó so mọ́ ọdún Ẹ̀yọ̀, tí obìnrin kìí ti di Sùkú tàbí wé gèlè
- Muyiwa Ademola kéde ìdí tó ṣe fi iṣẹ́ tíátà sílẹ̀
- Kí ló dé tí Jaiye Kuti ṣe ń fi omijé ṣe oúnjẹ lọ́pọ̀ ìgbà?
- Agbébọn kọlu Charles Soludo, ọlọ́pàá mẹ́ta dèrò ọ̀run
- Tẹlifísàn pásítọ̀ Oyakhilome wọ gàù nílẹ̀ UK torí òfegè ìròyìn
- Afúrasí darandaran tó pa ènìyàn 15, jó ọ̀pọ̀ dúkìá ni Ebonyi ti bọ́ sí àhámọ́ ọlọ́pàá
- Àbọ̀ ìpàdé Seyi Makinde àtàwọn oríadé l‘Oyo rèé, lórí ààbò tó mẹ́hẹ
Oba Titiloye sọ pe ẹnikẹni lo ni anfaani lati pe nọmba yii, ti wọn ba ti kẹfin ohunkohun to mu ifura dani.
Oba Igbo Ora ni igbimọ "Task Force" ti ijọba ipinlẹ Oyo ṣẹṣẹ da silẹ lati maa ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ọlọpaa yoo so eso rere.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Seyi Makinde
Oba Titiloye ni kii ṣe ẹkan naa ni eto abo to mẹhẹ nipinlẹ Oyo yoo lojutu pada nitori ọjọ kan kọ ni gbogbo rẹ bẹrẹ.
Olu Igbo Ora fikun ọrọ rẹ pe, gbogbo awọn lọbalọba igberiko naa n ṣapa wọn lati ri pe wọn mọ nipa awọn alejo to n wọ ilu.
Bakan naa, igbakeji alaga igbimọ awọn lọbalọba ipinlẹ Oyo, Olugbon ti Orile Igbon, Ọba Francis Olusola Alao sọ fun BBC Yoruba pe omi tuntun ti ru lọrọ eto abo ipinlẹ Oyo.
Olugbọn ni tawọn ọlọpaa ba tiẹ n fi awọn afurasi ti wọn ba mu lọ fún wọn silẹ tẹlẹ, o ni ko si ohun to jọ bẹẹ mọ bayii lẹyin ipade Ọjọru pẹlu Makinde ati Kọmiṣọnna ọlọpaa ipinlẹ Oyo.
"Ijọba ipinlẹ Oyo ti gbe igbimọ ẹṣọ alaabo amuṣẹya Task Force kan dide ti yoo maa ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ọlọpaa lati rii pe eto abo to mọyan lori wa," Olugbon lo sọ bẹẹ.

Abọ ìpàdé Seyi Makinde àtàwọn oríadé l'Oyo rèé, lórí ààbò tó mẹ́hẹ

Oríṣun àwòrán, Twitter/Seyi Makinde
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti seleri lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn lọbalọba ni ipinlẹ Oyo lati fi opin si iṣekupani ati ijinigbe awọn araalu ni Naijiria.
Gomina Makinde sọ ọrọ yii lasiko to n ṣepade pẹlu awọn lọbalọba ni ilu Ibadan.
O ni ijọba oun yoo tẹsiwaju lati ma a ṣiṣẹ pẹlu awọn oriade ni gbogbo ẹka ki alaafia le jọba ni ipinlẹ naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wo èèwọ̀ tó so mọ́ ọdún Ẹ̀yọ̀, tí obìnrin kìí ti di Sùkú tàbí wé gèlè
- Wo àbọ̀ ìwádìí Amẹ́ríkà lórí ìkọlù ológun tó wáyé ní Lekki
- Àwọn tí àkóso ìjọba bọ́ lọ́wọ́ wọn ló ń ti Igboho lẹ́yìn lórí ìdásílẹ̀ Oodua Nation - YWG
- Kí ló dé tí Jaiye Kuti ṣe ń fi omijé ṣe oúnjẹ lọ́pọ̀ ìgbà?
- "Nǹkan tó lé pa màálù 30 lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo lé pa ènìyàn, ẹ̀yin àrá Ondo, ewu ńbẹ"
- Àwọn agbébọn pa ọ̀pọ̀ ọlọ́pàá, ṣọ́jà, wọ́n tún jó ọ̀pọ̀ ọkọ̀ ní Akwa Ibom
Makinde ni ijọba oun ti gbe ẹka alajumọse eto aabo dide, Joint Security Task Force, lati gbogun ti eto aabo to dẹnukọlẹ ni ipinlẹ naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Bakan naa lo ni awọn oṣiṣẹ ijọba, gomina ati awọn olori ẹka eto aabo nipinlẹ Oyo to fi mọ ikọ Operation Burst ati ikọ Amọtẹkun. n sisẹ kara lati wa ojutu si eto aabo to mẹhẹ.
O fikun wi pe, ijọba oun yoo fun awọn eniyan laaye lati darapọ mọ ikọ alaabo ilu alajumọse bo ṣe wu wọn, voluntary policing approach, eyi ti yoo ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo miran ni ipinlẹ Oyo.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Seyi Makinde
''Idi ti a fi ṣepade loni ni wi pe, o pọndandan ki eto aabo wa ni ookan aya ijọba, ki awọn araalu ba le ni isinmi''
''Bi eto ilera, ẹkọ ati eto ọr aje ṣe ṣe pataki ni ipinlẹ naa ni eto aabo to muna doko naa ṣe pataki''

Oríṣun àwòrán, Twitter/Seyi Makinde
''Nitori ohun gbogbo ti ijọba ba ṣe yoo jasi pabo, ti ko ba si eto aabo fun awọn araalu, ti iṣekupani si n waye nibẹ ni ojoojumọ''
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ni awọn araalu n gbadun nitori ko si ọwọn gogo ounjẹ, ile gbigbe, ọkọ wiwọ to fi mọ burẹdi, iṣu, eso ati ẹfọ ti iye rẹ ko mu ẹfọri ba awọn eniyan.

















